Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣọ́ra Fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù!

Ṣọ́ra Fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù!

Ṣọ́ra Fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù!

“Padà . . . kúrò nínú ìdẹkùn Èṣù.”​—2 TÍM. 2:26.

BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

Bó o bá sábà máa ń ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn míì, àyẹ̀wò wo ló yẹ kó o ṣe nípa ara rẹ?

Kí lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Pílátù àti Pétérù nípa ìdí tí kò fi yẹ kó o kó sínú ìdẹkùn ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?

Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa nímọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ?

1, 2. Àwọn ìdẹkùn Èṣù wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 ÈṢÙ ń dọdẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Kì í ṣe pé ó ń wá bó ṣe máa pa wọ́n bí àwọn ọdẹ aperin ṣe máa ń pa ẹran ńlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Èṣù ń fẹ́ gan-an ni pé kó gbá ẹni tó bá ń dọdẹ mú láàyè, kó sì ṣe onítọ̀hún bó bá ṣe fẹ́.—Ka 2 Tímótì 2:24-26.

2 Bí ọdẹ kan bá fẹ́ mú ẹran láàyè, ó ní ohun tó máa ń lò. Ó lè fi ohun kan tan ẹran náà wá sí gbangba níbi táá ti kó sínú okùn tó dẹ. Tàbí kó dẹ páńpẹ́ kan síbi tó fara sin, kí páńpẹ́ náà lè ré lójijì nígbà tí ẹran ti wọ́n dẹ ẹ́ fún bá kó sínú rẹ̀. Irú àwọn ìdẹkùn bẹ́ẹ̀ ni Èṣù máa ń lò láti fi mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láàyè. Bí a kò bá fẹ́ kó mú wa, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò ká sì máa fiyè sí àwọn àmì tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ìdẹkùn tàbí páńpẹ́ Sátánì wà nítòsí. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní kó sínú mẹ́ta lára àwọn páńpẹ́ tí Èṣù ń lò, tó ti fi mú àwọn èèyàn kan. Àwọn ni (1) sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù, (2) ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti (3) ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa jíròrò àwọn páńpẹ́, tàbí ìdẹkùn méjì míì tí Sátánì ń lò.

DẸ́KUN SÍSỌ̀RỌ̀ GBÀÙGBÀÙ

3, 4. Bí a kò bá kó ahọ́n wa níjàánu, kí ló lè yọrí sí? Sọ àpẹẹrẹ kan.

3 Bí ọdẹ kan bá fẹ́ kí àwọn ẹranko sá jáde kúrò níbi tí wọ́n fara pa mọ́ sí, ó lè sọ iná sí apá ibì kan nínú igbó, bí àwọn ẹranko náà bá sì ti ń sá jáde, á bẹ̀rẹ̀ sí í mú wọn. Bákan náà, Èṣù máa fẹ́ láti dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ. Bí iná náà bá sì ti ràn, ó lè mú kí àwọn ará máa fi ìjọ tó jẹ́ ibi ààbò sílẹ̀ kí wọ́n sì máa lọ síbi tí ọwọ́ rẹ̀ ti lè tẹ̀ wọ́n. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó fẹ́ láìmọ̀, ká sì wá tipa bẹ́ẹ̀ kó sínú akóló rẹ̀.

4 Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù fi ahọ́n wé iná. (Ka Jákọ́bù 3:6-8.) Bí a kò bá kó ahọ́n wa níjàánu, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Ẹ ronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ná: Wọ́n ṣèfilọ̀ ní ìpàdé ìjọ pé arábìnrin kan ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwọn akéde méjì ń sọ̀rọ̀ nípa ìfilọ̀ náà. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé inú òun dùn pé ó di aṣáájú-ọ̀nà, àdúrà òun sì ni pé kí Jèhófà jẹ́ kó kẹ́sẹ járí. Èkejì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríwísí aṣáájú-ọ̀nà náà, ó ní ńṣe ló máa ń fẹ́ láti fira rẹ̀ sípò ńlá nínú ìjọ. Èwo lo máa fẹ́ láti mú lọ́rẹ̀ẹ́ nínú àwọn akéde méjèèjì? Kò ṣòro láti mọ èyí tó ṣeé ṣe kó fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ láàárín àwọn méjèèjì.

5. Ká bàa lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù, àyẹ̀wò wo ló yẹ ká ṣe nípa ara wa?

5 Báwo la ṣe lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù? Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Torí náà, ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká ṣe àyẹ̀wò ohun tó wà nínú ọkàn wa. Bí èrò búburú tó máa ń mú kéèyàn sọ̀rọ̀ ẹlòmíì láìdáa bá wá sí wa lọ́kàn, ǹjẹ́ a máa ń fàyè gbà á? Bí àpẹẹrẹ, bí a bá gbọ́ pé arákùnrin kan ń sapá láti kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, ṣé a tètè máa ń gbà pé èrò rere ló ní lọ́kàn, àbí ńṣe la máa ń fura sí i pé ire ti ara rẹ̀ nìkan ló ń wá? Bí a bá sábà máa ń ronú pé ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú káwọn míì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, ó máa dára ká rántí pé Èṣù jiyàn nípa ìdí tí Jóòbù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olùṣòtítọ́ fi ń sìn Ín. (Jóòbù 1:9-11) Torí náà, dípò tí a ó fi máa fura sí arákùnrin wa, ó máa dára ká ronú nípa ohun tó fà á tá a fi ń ní èrò tí kò tọ́ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ ìdí rere kan tiẹ̀ wà tó fi yẹ ká máa ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Àbí ẹ̀mí ìkórìíra tó gbilẹ̀ gan-an nínú ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ti gbin ohun tí kò dára sí wa lọ́kàn?—2 Tím. 3:1-4.

6, 7. (a) Kí ni díẹ̀ lára ohun tó lè mú ká máa fẹ́ ṣàríwísí àwọn ẹlòmíì? (b) Kí ló yẹ ká ṣe bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ tó dùn wá?

6 Ronú nípa àwọn ìdí míì tó lè mú ká máa ṣàríwísí àwọn ẹlòmíì. Ọ̀kan lára ohun tó lè mú ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ kí àwọn èèyàn túbọ̀ máa kíyè sí àwọn àṣeyọrí wa. Lédè mìíràn, a lè fẹ́ láti máa fi hàn pé a sàn ju gbogbo èèyàn tó kù lọ. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe là ń gbìyànjú láti wá àwáwí torí ohun kan tó yẹ ká ti ṣe ṣùgbọ́n tí a kùnà láti ṣe. Yálà ìgbéraga ló sún wa ṣe ohun tá a ṣe ni o tàbí ìlara tàbí àìdára-ẹni-lójú, ó máa ṣèpalára tó pọ̀ gan-an.

7 A sì lè rò pé kò sí ohun tó burú nínú ṣíṣe àríwísí ẹnì kan. Bóyá òun náà ti sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa wa rí. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, gbígbẹ̀san ohun tó ṣe sí wa kọ́ ló máa yanjú ọ̀ràn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe nìyẹn máa mú kí ọ̀ràn náà burú sí i. Èṣù ló sì máa ń fẹ́ kéèyàn gbẹ̀san, Ọlọ́run kò fẹ́ bẹ́ẹ̀. (2 Tím. 2:26) Torí náà, ó dára ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn rẹ̀, “kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pét. 2:21-23) Ó dá Jésù lójú pé Jèhófà máa bójú tó àwọn ọ̀ràn lọ́nà tí Ó fẹ́ àti nígbà tí ó bá tọ́ lójú Rẹ̀. Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run. Tá a bá ń sọ àwọn ohun tó máa gbé àwọn mìíràn ró, a óò mú kí “ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà” máa wà nínú ìjọ wa.—Ka Éfésù 4: 1-3.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ SÁTÁNÌ FI ÌBẸ̀RÙ ÀTI Ẹ̀MÍ ṢOHUN-TẸ́GBẸ́-Ń-ṢE DẸKÙN MÚ Ẹ

8, 9. Kí nìdí tí Pílátù fi dá Jésù lẹ́bi?

8 Bí ẹran kan bá kó sínú ìdẹkùn, ẹran náà kò ní lómìnira láti rìn fàlàlà bó ṣe wù ú mọ́. Bákan náà, bí ẹnì kan bá jẹ́ kí ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe máa darí òun, a jẹ́ pé ó gbà kí àwọn míì máa darí apá kan nínú ìgbésí ayé òun nìyẹn. (Ka Òwe 29:25.) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà kí ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe darí àwọn ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú ìrírí wọn.

9 Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà ìlú Róòmù mọ̀ pé Jésù kò jẹ̀bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, torí náà kò fẹ́ láti ṣe ohun tó máa pa á lára. Kódà, Pílátù sọ pé Jésù kò ṣe “nǹkan kan . . . tí ó yẹ fún ikú.” Síbẹ̀, Pílátù dájọ́ ikú fún un. Kí nìdí? Ìdí ni pé Pílátù fẹ́ láti ṣe ohun tí àwọn èèyàn fẹ́ kó ṣe. (Lúùkù 23:15, 21-25) Àwọn Júù tó ń ṣe àtakò sí Jésù wá ọ̀nà láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn, torí náà wọ́n kígbe pé: “Bí ìwọ bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì.” (Jòh. 19:12) Ẹ̀rù lè ti máa ba Pílátù pé bí òun bá gbè sẹ́yìn Kristi, ó ṣeé ṣe kí òun pàdánù ipò òun gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa òun. Torí náà, ó gbà kí àwọn èèyàn mú un ṣe ohun tí Èṣù fẹ́.

10. Kí ló mú kí Pétérù sẹ́ Kristi?

10 Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jù lọ fún Jésù. Ó polongo ní gbangba pé Jésù ni Mèsáyà náà. (Mát. 16:16) Pétérù ń bá a nìṣó láti máa tọ Jésù lẹ́yìn nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù kò lóye ohun tó sọ tí wọ́n sì fi Í sílẹ̀. (Jòh. 6:66-69) Nígbà tí àwọn ọ̀tá sì wá láti mú Jésù, Pétérù lo idà láti dáàbò bo Ọ̀gá rẹ̀. (Jòh. 18:10, 11) Àmọ́, nígbà tó yá, Pétérù jẹ́ kí ìbẹ̀rù borí òun, ó sẹ́ Jésù Kristi nípa sísọ pé òun kò mọ̀ ọ́n rí. Ó kó sínú ìdẹkùn fún ìgbà díẹ̀, ó gbà kí ìbẹ̀rù èèyàn fa òun sẹ́yìn láti lo ìgboyà.—Mát. 26:74, 75.

11. Àwọn ipò tí ń múni ṣe ohun tí kò tọ́ wó ló ṣeé ṣe ká dojú kọ?

11 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ máa sá fún àwọn ohun tó lè mú ká ṣe ohun tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Àwọn agbanisíṣẹ́ tàbí àwọn míì lè gbìyànjú láti mú ká hùwà àìṣòótọ́ tàbí kí wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa tàn wá ká lè lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe. Ní ti àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọmọléèwé, àwọn ojúgbà wọn lè gbìyànjú láti mú kí wọ́n jí ìwé wò nígbà ìdánwò, kí wọ́n wo àwòrán oníhòòhò, kí wọ́n mu sìgá, kí wọ́n lo oògùn olóró, kí wọ́n mu ọtí líle ní àmuyó, tàbí kí wọ́n ṣe ìṣekúṣe. Ńṣe ni ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe dà bí ìdẹkùn. Torí náà, báwo la ò ṣe ní í jẹ́ kí wọ́n mú wa ṣe ohun tí inú Jèhófà kò dùn sí?

12. Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù àti Pétérù?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù àti Pétérù. Òye díẹ̀ ni Pílátù ní nípa Kristi. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé Jésù kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án àti pé kì í ṣe èèyàn kan lásán. Àmọ́, agbéraga ni Pílátù kò sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Torí náà, ó rọrùn fún Èṣù láti mú kó ṣe ohun tó fẹ́. Pétérù ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, láwọn ìgbà míì, kì í ṣe bó ti mọ, ẹ̀rù máa ń bà á, ó sì máa ń ṣe ohun tó wu àwọn míì. Kí wọ́n tó mú Jésù, Pétérù fọ́nnu pé: “Àní bí a bá mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀, síbẹ̀ a kì yóò mú èmi kọsẹ̀.” (Máàkù 14:29) Ì bá ti túbọ̀ rọrùn fún àpọ́sítélì yìí láti wà ní ìmúrasílẹ̀ de àwọn ìdánwò tó ń bọ̀ wá kojú rẹ̀ ká sọ pé ó ti ṣe bíi ti onísáàmù tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Onísáàmù náà kọrin pé: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” (Sm. 118:6) Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó mú Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì méjì mìíràn lọ sí àárín gbùngbùn inú ọgbà Gẹtisémánì. Àmọ́, dípò kí Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì méjì náà wà lójúfò, ńṣe ni wọ́n sùn lọ. Jésù jí wọn, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa wá sínú ìdẹwò.” (Máàkù 14:38) Àmọ́, Pétérù tún sùn lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sì wá kó sínú ìdẹkùn ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe.

13. Báwo la ṣe lè sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́?

13 A tún lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì mìíràn kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù àti Pétérù. Ẹ̀kọ́ náà sì ni pé, ká lè sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye, ká ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká sì bẹ̀rù Jèhófà dípò àwọn èèyàn. Tá a bá gbé ìgbàgbọ́ wa ka orí ìmọ̀ pípéye, a ó máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ lọ́nà tó fi hàn pé ó dá wa lójú. Èyí máa ràn wá lọ́wọ́ láti sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́ ká sì borí ìbẹ̀rù èèyàn. Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ dá ara wa lójú ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a nílò agbára Ọlọ́run ká tó lè sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́. A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́, ká jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún un mú ká sá fún ṣíṣe ohun tó máa tàbùkù sí orúkọ rẹ̀, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ó sì tún yẹ ká ti máa wà ní ìmúrasílẹ̀ de ohun tó lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa wà ní ìmúrasílẹ̀ tá a sì jọ ń gbàdúrà, wọ́n máa mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe bí àwọn ojúgbà wọn bá fẹ́ mú kí wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́.—2 Kọ́r. 13:7. *

SÁ FÚN Ẹ̀BÌTÌ SÁTÁNÌ, ÌYẸN ÌMỌ̀LÁRA Ẹ̀BI TÓ KỌJÁ BÓ ṢE YẸ

14. Kí ni Èṣù máa fẹ́ ká ní lọ́kàn nípa àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe kọjá?

14 Ìgbà míì wà táwọn èèyàn máa ń dẹ ẹ̀bìtì láti fi mú ẹran. Ẹ̀bìtì yìí jẹ́ igi rìbìtì kan tàbí òkúta tí wọ́n so rọ̀ sára igi tẹ́ẹ́rẹ́ ní ojú ọ̀nà tí ẹran sábà máa ń gbà kọjá. Bí ẹranko kan tí kò fura bá fara kọ́ ohun tó gbé igi tẹ́ẹ́rẹ́ náà ró, ńṣe ni igi rìbìtì tàbí òkúta náà á wó lù ú mọ́lẹ̀ tá á sì tẹ̀ ẹ́ rẹ́. Ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ la lè fi wé igi rìbìtì tàbí òkúta yẹn. Tá a bá ń ronú nípa ẹ̀ṣẹ̀ kan tá a ti ṣẹ̀ kọjá, ìyẹn lè mú ká máa rí ara wa bí “ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó.” (Ka Sáàmù 38:3-5, 8.) Sátánì á fẹ́ ká máa ronú pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a ṣẹ̀ ti mú ká kọjá ẹni tí Jèhófà lè fi àánú hàn sí àti pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́.

15, 16. Báwo lo ṣe lè sá fún ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ?

15 Báwo lo ṣe lè sá fún ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ? Tó o bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tètè wá nǹkan ṣe nípa rẹ̀ kó o lè pa dà ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Tọ àwọn alàgbà lọ kó o sì ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Ják. 5:14-16) Ṣe ohun tó o bá lè ṣe láti wá ojútùú sí àṣìṣe náà. (2 Kọ́r. 7:11) Tí wọ́n bá sì bá ẹ wí, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ìbáwí jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Jèhófà fẹ́ràn rẹ. (Héb. 12:6) Pinnu pé o kò ní ṣe ohun tó mú kó o dẹ́ṣẹ̀ yẹn mọ́, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu rẹ. Lẹ́yìn tó o bá ti ronú pìwà dà tó o sì ti yí pa dà, ní ìgbàgbọ́ pé ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò ní ti gidi.—1 Jòh. 4:9, 14.

16 Ọkàn àwọn míì kì í yé dá wọn lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ti dárí rẹ̀ jì wọ́n. Bó bá jẹ́ pé bí ọ̀ràn tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn, rántí pé Jèhófà dárí ji Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi Jésù tó jẹ́ ààyò olùfẹ́ Ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀, nígbà tó nílò wọn jù lọ. Jèhófà dárí ji ọkùnrin tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ Kọ́ríńtì torí ìwà ìṣekúṣe bíburú jáì tó hù àmọ́ tó ronú pìwà dà lẹ́yìn náà. (1 Kọ́r. 5:1-5; 2 Kọ́r. 2:6-8) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa nípa àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí Ọlọ́run sì dárí jì wọ́n.—2 Kíró. 33:2, 10-13; 1 Kọ́r. 6:9-11.

17. Kí ni ìràpadà lè ṣe fún wa?

17 Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ jì ẹ́, ó sì máa gbàgbé wọn tó o bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó o sì gbà pé ó máa fi àánú hàn sí ẹ. Má ṣe ronú láé pé ẹbọ ìràpadà Jésù kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò. Tó o bá ronú bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú kó o kó sínú ọ̀kan lára àwọn ìdẹkùn Sátánì. Láìka ohun yòówù tí Èṣù lè fẹ́ kó o gbà gbọ́ sí, ẹbọ ìràpadà náà lè mú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tó bá ti dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà kúrò. (Òwe 24:16) Bó o bá ń ní ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ, ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà lé mú un kúrò, ó sì lè fún ẹ lókun kó o lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà, èrò inú àti ọkàn rẹ sin Ọlọ́run.—Mát. 22:37.

A KÒ ṢE ALÁÌMỌ ÀWỌN ÈTE-ỌKÀN SÁTÁNÌ

18. Kí la lè ṣe ká máa bàa kó sínú ìdẹkùn Èṣù?

18 Sátánì ò fẹ́ mọ èyí tá a kó sí nínú àwọn ìdẹkùn rẹ̀, tiẹ̀ ṣáà ni pé kó rí wa mú. Níwọ̀n bí a kò ti ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn Sátánì, ohun tá a lè ṣe wà kí Èṣù má bàa fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ borí wa. (2 Kọ́r. 2:10, 11) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n tá a máa fi kojú àwọn àdánwò wa, a kò ní kó sínú àwọn ìdẹkùn rẹ̀, ẹ̀bìtì rẹ̀ kò sì ní ré lù wá. Jákọ́bù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Ják. 1:5) Ó pọn dandan pé ká máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti nípa fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń mú jáde ń jẹ́ ká dá àwọn ohun tí Èṣù fi ń múni mọ̀, wọ́n sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè sá fún wọn.

19, 20. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ kórìíra ohun tó burú?

19 Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé ká kórìíra ohun tó burú. (Sm. 97:10) Ṣíṣe àṣàrò lórí wàhálà tó lè jẹ yọ tó bá jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti wù wá là ń ṣe, máa jẹ́ ká yẹra fún lílépa ìfẹ́ ọkàn wa. (Ják. 1:14, 15) Tá a bá kórìíra ohun tó burú tó sì jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára, ohun tí Sátánì fi ń tan àwọn èèyàn kó ní fà wá mọ́ra, ńṣe ló máa kó wa nírìíra.

20 Ẹ wo bó ti yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó pé Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ borí wa! Nípasẹ̀ ẹ̀mí Rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀, Jèhófà ń dá wa nídè “kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mát. 6:13) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè sá fún ohun méjì míì tí Èṣù fi ń mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láàyè.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ó dára kí àwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn jíròrò ohun tó wà nínú àpótí náà, “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” tó wà ní ojú ìwé 132 sí 133 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Ẹ lè jíròrò rẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Bí a kò bá kó ahọ́n wa níjàánu, a lè dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

O lè mú ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ kúrò