Lẹ́tà Jémíìsì 3:1-18

  • Bí a ṣe lè kápá ahọ́n (1-12)

    • Kí ọ̀pọ̀ má ṣe di olùkọ́ (1)

  • Ọgbọ́n tó wá láti òkè (13-18)

3  Ẹ̀yin arákùnrin mi, kí púpọ̀ nínú yín má ṣe di olùkọ́, torí ẹ mọ̀ pé a máa gba ìdájọ́ tó wúwo* jù.+  Nítorí gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀* lọ́pọ̀ ìgbà.+ Tí ẹnì kan kì í bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, á jẹ́ pé ẹni pípé ni, ó sì lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu.  Tí a bá fi ìjánu sí ẹnu àwọn ẹṣin kí wọ́n lè ṣègbọràn sí wa, gbogbo ara wọn là ń darí pẹ̀lú.  Ẹ tún wo àwọn ọkọ̀ òkun: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tóbi gan-an, tí atẹ́gùn tó le gan-an sì máa ń gbé wọn kiri, ìtọ́kọ̀ tó kéré gan-an la fi ń darí wọn síbi tí ẹni tó ń darí ọkọ̀ bá fẹ́ kó lọ.  Bẹ́ẹ̀ náà ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara tó kéré, síbẹ̀ ó máa ń fọ́nnu gan-an. Ẹ wo bí iná tí kò tó nǹkan ṣe lè jó igbó kìjikìji run!  Bákan náà, ahọ́n jẹ́ iná.+ Ahọ́n dúró fún ayé àìṣòdodo lára àwọn ẹ̀yà ara wa, torí ó máa ń sọ gbogbo ara di aláìmọ́,+ ó sì máa ń dáná sí gbogbo ìgbésí ayé* ẹ̀dá, iná Gẹ̀hẹ́nà* á sì sun òun náà.  Torí àwọn èèyàn máa ń kápá gbogbo ẹran inú igbó àti ẹyẹ àti ẹran tó ń fàyà fà* àti ẹ̀dá inú òkun, wọ́n sì ti kápá wọn.  Àmọ́ kò sí èèyàn tó lè kápá ahọ́n. Aláìgbọràn ni, ó sì ń ṣeni léṣe, ó kún fún májèlé tó ń pani.+  Òun la fi ń yin Jèhófà,* Baba wa, síbẹ̀ òun la tún fi ń gégùn-ún fún àwọn èèyàn tí a dá ní “àwòrán Ọlọ́run.”+ 10  Ẹnu kan náà tí èèyàn fi ń súre ló tún fi ń gégùn-ún. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kó máa rí bẹ́ẹ̀.+ 11  Omi tó ṣeé mu* àti omi tó korò kì í jáde láti orísun kan náà, àbí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀? 12  Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ò lè mú èso ólífì jáde tàbí kí àjàrà mú èso ọ̀pọ̀tọ́ jáde, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?+ Bẹ́ẹ̀ ni omi iyọ̀ ò lè mú omi tó ṣeé mu jáde. 13  Ọlọ́gbọ́n àti olóye wo ló wà láàárín yín? Kó fi ìwà rere rẹ̀ hàn nínú bó ṣe ń fi ìwà tútù ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé ó gbọ́n. 14  Àmọ́ tí ẹ bá ń jowú gidigidi,+ tó sì ń wù yín láti máa fa ọ̀rọ̀,*+ ẹ má ṣe máa fọ́nnu,+ ẹ má sì máa parọ́ mọ́ òtítọ́. 15  Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tó wá láti òkè; ti ayé ni,+ ti ẹranko àti ti ẹ̀mí èṣù. 16  Torí ibikíbi tí wọ́n bá ti ń jowú tí wọ́n sì ń fa ọ̀rọ̀,* ìdàrúdàpọ̀ àti gbogbo nǹkan burúkú máa ń wà níbẹ̀.+ 17  Àmọ́, ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́,+ lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà,+ ó ń fòye báni lò,+ ó ṣe tán láti ṣègbọràn, ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere,+ kì í ṣe ojúsàájú,+ kì í sì í ṣe àgàbàgebè.+ 18  Bákan náà, ibi tí àlàáfíà bá wà+ la máa ń gbin èso òdodo sí fún àwọn tó ń wá àlàáfíà.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “le.”
Tàbí “ṣàṣìṣe.”
Ní Grk., “àgbá kẹ̀kẹ́ ìbí (orísun).”
Tàbí “rákò.”
Ní Grk., “Omi dídùn.”
Tàbí kó jẹ́, “tí ẹ sì ń wá ipò ọlá.”
Tàbí kó jẹ́, “tí wọ́n sì ń wá ipò ọlá.”
Tàbí kó jẹ́, “ibi tí àlàáfíà bá wà, ni àwọn tó ń wá àlàáfíà máa ń gbin èso òdodo sí.”