Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Ní Inú Dídùn Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà”

“Máa Ní Inú Dídùn Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà”

“Máa Ní Inú Dídùn Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà”

“Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”—SÁÀMÙ 37:4.

1, 2. Ta ni orísun ayọ̀ tòótọ́, báwo sì ni Dáfídì Ọba ṣe mọ́kàn wa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀?

 “ALÁYỌ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, . . . aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, . . . aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” Gbólóhùn wọ̀nyí, pa pọ̀ mọ́ gbólóhùn mẹ́fà mìíràn tó ṣàpèjúwe àwọn tó jẹ́ aláyọ̀, ni ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù rẹ̀ olókìkí Lórí Òkè, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ Mátíù òǹkọ̀wé Ìwé Ìhìn Rere. (Mátíù 5:3-11) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lókè yìí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a lè jẹ́ aláyọ̀.

2 Sáàmù kan tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ mọ́kàn wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tààrà, pé òun ni Orísun ayọ̀ tòótọ́. Dáfídì sọ pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.” (Sáàmù 37:4) Àmọ́, báwo ni mímọ Jèhófà àtàwọn onírúurú ànímọ́ rẹ̀ ṣe lè mú wa ní “inú dídùn kíkọyọyọ”? Báwo ni àgbéyẹ̀wò ohun tó ti ṣe àti èyí tí yóò ṣe kí ète rẹ̀ lè kẹ́sẹ járí, ṣe lè mú ọ máa retí àtirí “àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá” gbà? Bí a bá fara balẹ̀ gbé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ inú Sáàmù kẹtàdínlógójì, ẹsẹ kìíní sí ìkọkànlá yẹ̀ wò, a ó rí ìdáhùn ìbéèrè wọ̀nyí.

“Má Ṣe Ìlara”

3, 4. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sáàmù 37:1, ìmọ̀ràn wo ni Dáfídì fúnni, kí sì nìdí tó fi bá a mu láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn náà lóde òní?

3 “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé yìí, ìwà ibi sì gbòde kan. À ń fojú ara wa rí i pé ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:1, 13) Téèyàn ò bá ṣọ́ra, àṣeyọrí àti aásìkí tó dà bíi pé àwọn èèyàn burúkú ń ní á máa bani nínú jẹ́ ṣáá ni! Gbogbo ìyẹn sì lè kó ìpínyà ọkàn bá wa, tá ò sì ní lè máa fi ojú tẹ̀mí wo àwọn nǹkan bó ṣe yẹ mọ́. Wo bí ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Sáàmù kẹtàdínlógójì ṣe kìlọ̀ fún wa nípa ewu yìí, pé: “Má ṣe gbaná jẹ nítorí àwọn aṣebi. Má ṣe ìlara àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo.”

4 Ojoojúmọ́ letí wa ń kún fún ìròyìn tá à ń gbọ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n àtèyí tó ń wá látinú ìwé ìròyìn, tó ń sọ nípa ìwà ìrẹ́jẹ àti àìsí ìdájọ́ òdodo. Àwọn oníṣòwò ń lu jìbìtì wọ́n sì ń mú un jẹ. Àwọn ọ̀daràn ń fojú àwọn ẹni ẹlẹ́ni gbolẹ̀ bó ṣe wù wọ́n. Àwọn apààyàn ń ṣe é gbé, a kì í rí wọn mú tàbí tá a bá rí wọn mú ká má fìyà jẹ wọ́n. Gbogbo irú ìwà àìsí ìdájọ́ òdodo báwọ̀nyí lè máa múnú bíni, kó sì máa bani lọ́kàn jẹ́. Bó ṣe dà bíi pé nǹkan ń ṣẹnuure fáwọn aṣebi tiẹ̀ lè múni bẹ̀rẹ̀ sí bínú wọn. Ṣùgbọ́n ṣé ìkanra wa yóò mú àwọn nǹkan sàn sí i? Ṣé ìbínú nítorí bó ṣe dà bíi pé àwọn aṣebi ń rọ́wọ́ mú yóò wá yí àtúbọ̀tán wọn padà? Rárá o! Kò sídìí fún wa láti yọ ara wa lẹ́nu, pé à ń “gbaná jẹ.” Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

5. Kí nìdí tí Bíbélì fi fi àwọn aṣebi wé koríko?

5 Onísáàmù náà dáhùn pé: “Nítorí pé bí koríko ni wọn yóò rọ pẹ̀lú ìyára kánkán, àti bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ koríko tútù ni wọn yóò rẹ̀ dànù.” (Sáàmù 37:2) Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ koríko tútù lè dùn ún wò, ṣùgbọ́n ewé rẹ̀ kì í pẹ́ rọ tí yóò sì kú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn àwọn aṣebi rí. Aásìkí wọn kì í wà títí ayé. Bí wọ́n bá kú, gbogbo ohun tí wọ́n fèrú kó jọ kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́. Bópẹ́ bóyá, kálukú á jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Níkẹyìn, gbogbo aṣebi àti gbogbo àwọn aláìṣòdodo á gba “owó ọ̀yà” wọn, ìyẹn ni pé ẹ̀san á ké lórí wọ́n. Áà, wọ́n mà kúkú pòfo o!—Sáàmù 37:35, 36; 49:16, 17.

6. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú Sáàmù 37:1, 2?

6 Ǹjẹ́ ó wá yẹ ká máa bọkàn jẹ́ nítorí ọlà àwọn aṣebi tí kì í wà pẹ́ títí? Ẹ̀kọ́ tí Sáàmù kẹtàdínlógójì, ẹsẹ kìíní àti ìkejì ń kọ́ wa ni pé: Má ṣe jẹ́ kí àṣeyọrí wọn mú ọ yà kúrò nínú ipa ọ̀nà ìjọsìn Jèhófà tó o ti yàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o gbájú mọ́ èrè àti góńgó tẹ̀mí tó ò ń lépa.—Òwe 23:17.

“Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere”

7. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

7 Onísáàmù náà rọ̀ wá pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere.” (Sáàmù 37:3a) Tí a bá ń ṣàníyàn jù tàbí tí iyèméjì bá ń dà wá láàmú, ńṣe ni ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Òun ló máa ń dáàbò boni nípa tẹ̀mí ní gbogbo ọ̀nà. Mósè kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ yóò rí ibùwọ̀ fún ara rẹ̀ lábẹ́ òjìji Olódùmarè.” (Sáàmù 91:1) Bí ìwà ta-ni-yóò-mú-mi tó ń pọ̀ sí i láyé òde òní bá ń kó ìdààmú bá wa, ńṣe ni ká gbára lé Jèhófà pátápátá. Tí a bá fẹsẹ̀ rọ́, tí ọ̀rẹ́ wa kan sì ràn wá lọ́wọ́, ṣebí inú wa máa ń dùn. Bákan náà, tí a bá ń gbìyànjú láti rìn nínú ìṣòtítọ́, a nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.—Aísáyà 50:10.

8. Báwo ni kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ kí aásìkí àwọn aṣebi má bàa bà wá lọ́kàn jẹ́ jù?

8 Ohun tá a lè ṣe kí aásìkí àwọn aṣebi má bàa bà wá lọ́kàn jẹ́ ni pé ká tara bọ iṣẹ́ wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn rí, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n dẹni tó ní ìmọ̀ pípéye nípa ète Jèhófà. Bí ìwà ibi ṣe ń pọ̀ sí i yìí, ńṣe ló yẹ kí ọwọ́ wa túbọ̀ máa dí lẹ́nu iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” “Rere” tó ga jù lọ tá a lè ṣe ni pé ká máa sọ ìhìn rere ológo ti Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ìwàásù tá à ń ṣe fáwọn èèyàn jẹ́ “ẹbọ ìyìn.”—Hébérù 13:15, 16; Gálátíà 6:10.

9. Ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Dáfídì sọ, èyí tó sọ pé, “máa gbé ilẹ̀ ayé.”

9 Dáfídì ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Máa gbé ilẹ̀ ayé, kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.” (Sáàmù 37:3b) Nígbà ayé Dáfídì, Ilẹ̀ Ìlérí tó jẹ́ àgbègbè tí Ọlọ́run fi fún Ísírẹ́lì ni “ilẹ̀ ayé” tíbí yìí ń sọ. Àlà ilẹ̀ yìí dé Dánì níhà àríwá, ó sì dé Bíá-Ṣébà níhà gúúsù nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. (1 Àwọn Ọba 4:25) Lóde òní, ibi yòówù ká máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, à ń retí àkókò tí gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè nínú ayé tuntun òdodo. Àmọ́ ní báyìí, à ń gbé nínú ààbò tẹ̀mí.—Aísáyà 65:13, 14.

10. Tí a bá “fi ìṣòtítọ́ báni lò,” kí ló máa ń yọrí sí?

10 Tí a bá “fi ìṣòtítọ́ báni lò,” kí ló máa yọrí sí? Òwe tí Ọlọ́run mí sí rán wa létí pé: “Ènìyàn tí ó ń ṣe àwọn ìṣe ìṣòtítọ́ yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún.” (Òwe 28:20) Ó dájú pé tá a bá ń fi ìṣòtítọ́ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere níbikíbi tá a bá ń gbé, tá a sì ń wàásù fún gbogbo ẹni tá a bá rí, a ó gba èrè rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Frank àti aya rẹ̀ Rose, lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ìlú kan níhà àríwá ilẹ̀ Scotland ní ogójì ọdún sẹ́yìn. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan tó fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ti padà sẹ́yìn. Tọkọtaya yìí ò jẹ́ kí èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ní báyìí ìjọ kan ń bẹ ní ìlú náà, ó sì ń bí sí i. Láìsí àní-àní, Jèhófà bù kún ìṣòtítọ́ tọkọtaya yìí. Frank fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ìbùkún wa tó ga jù lọ ni pé a ṣì wà nínú òtítọ́ àti pé a ṣì wúlò fún Jèhófà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, tí a bá “fi ìṣòtítọ́ báni lò,” a máa ń rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà, a sì máa ń gbádùn wọn.

“Máa Ní Inú Dídùn Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà”

11, 12. (a) Báwo la ṣe lè “ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà”? (b) Kí lo lè pinnu pé o fẹ́ máa ṣe nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ, kí ló sì lè jẹ́ àbáyọrí rẹ̀?

11 Láti lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ má sì yẹ̀, a ní láti “máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà.” (Sáàmù 37:4a) Báwo la ṣe lè ní inú dídùn kíkọyọyọ? Bó ti wù kí ìṣòro wa le koko tó, dípò tá a ó fi kó ìṣòro náà lé ọkàn, ohun tí Jèhófà sọ ni ká máa ronú lé lórí. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká rí i pé à ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé. (Sáàmù 1:1, 2) Ǹjẹ́ ò ń gbádùn Bíbélì kíkà rẹ? Wàá gbádùn rẹ̀ tó bá jẹ́ pé ẹ̀mí pé o fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà sí i lo fi ń kà á. O ò ṣe máa dúró díẹ̀ tó o bá ti kà á dé ìwọ̀n kan, kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Kí ni ibi tí mo kà yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?’ Á dára kí o ní ìwé pélébé kan lọ́dọ̀ tó o bá ń ka Bíbélì. Nígbàkigbà tó o bá dúró láti ronú lórí ìtumọ̀ ohun tó o kà, kọ gbólóhùn tó bá rán ọ létí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Ọlọ́run ní sínú ìwé náà. Dáfídì kọrin nínú sáàmù mìíràn pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.” (Sáàmù 19:14) Ríronú tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà yìí, máa ń “dùn mọ́” Jèhófà nínú, ìyẹn sì ń mú inú àwa náà dùn pẹ̀lú.

12 Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò tá à ń ṣe yóò ṣe máa mú wa láyọ̀? A lè pinnu pé a fẹ́ mọ Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ jinlẹ̀ débi tá a bá lè mọ̀ ọ́n dé. A óò rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tá a lè ṣàṣàrò jinlẹ̀ lé lórí nínú àwọn ìwé bíi Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí àti Sún Mọ́ Jèhófà. a Dáfídì sì mú un dá olódodo lójú pé, Jèhófà yóò “fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.” (Sáàmù 37:4b) Ó ní láti jẹ́ pé irú ìgbọ́kànlé yìí ló mú kí àpọ́sítélì Jòhánù kọ ọ̀rọ̀ yìí pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa. Síwájú sí i, bí a bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè, a mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—1 Jòhánù 5:14, 15.

13. Lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, kí là ń rí nípa bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ṣe ń gbòòrò sí i ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀?

13 Gẹ́gẹ́ bí olùpàwàtítọ́mọ́, ìdáláre ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lohun tó jẹ wá lọ́kàn jù lọ. (Òwe 27:11) Ǹjẹ́ ayọ̀ kì í kún ọkàn wa tá a bá gbọ́ nípa gudugudu méje tí àwọn ará wa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lábẹ́ ìjọba oníkùmọ̀ tàbí ìjọba bóofẹ́bóokọ̀? À ń wo bí wọ́n yóò ṣe túbọ̀ ní òmìnira sí i kí òpin ètò nǹkan yìí tó dé. Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ayé pẹ̀lú ń báṣẹ́ lọ pẹrẹu lẹ́nu wíwàásù fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn mìíràn tó kàn wá gbé fúngbà díẹ̀ lápá ìwọ̀ oòrùn ayé níbi tí òmìnira ẹ̀sìn wà. Àdúrà wa ni pé bí wọ́n bá padà délé, kí wọ́n máa bá a lọ láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ mọ́lẹ̀, àní láàárín àwọn ibi tó ṣókùnkùn biribiri tó dà bíi pé ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ kò lè dé.—Mátíù 5:14-16.

“Yí Ọ̀nà Rẹ Lọ Sọ́dọ̀ Jèhófà”

14. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé atóófaratì ni Jèhófà jẹ́?

14 Ìtura gbáà ló máa ń jẹ́ láti mọ̀ pé ìdààmú ọkàn wa àtàwọn ohun tó dà bí òkè ìṣòro lójú wa yóò kúrò pátápátá! Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Dáfídì sọ pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e.” Ó wá fi kún un pé: “Òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” (Sáàmù 37:5) Nínú àwọn ìjọ wa gbogbo, à ń rí ẹ̀rí púpọ̀ tó fi hàn pé atóófaratì ni Jèhófà jẹ́. (Sáàmù 55:22) Gbogbo àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún yálà aṣáájú ọ̀nà, alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, ló lè jẹ́rìí sí i pé Jèhófà ń tọ́jú àwọn lóòótọ́. O ò ṣe bá àwọn tó o mọ̀ lára wọn sọ̀rọ̀, kó o bi wọ́n nípa bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Ó dájú pé wàá gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí tó fi hàn pé Jèhófà ò ṣàìnawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí wọn, àní nígbà ìṣòro pàápàá. Kì í ṣàìpèsè ohun kòṣeémánìí fún wọn.—Sáàmù 37:25; Mátíù 6:25-34.

15. Báwo ni òdodo àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń ràn bí oòrùn?

15 Tí a bá gbójú lé Jèhófà, tí a sì gbẹ́kẹ̀ lé e láìmikàn, ohun tí onísáàmù náà sọ síwájú sí i lè ṣẹ sí wa lára, ó sọ pé: “Dájúdájú, òun yóò sì mú òdodo rẹ jáde wá bí ìmọ́lẹ̀ pàápàá, àti ìdájọ́ òdodo rẹ bí ọjọ́kanrí.” (Sáàmù 37:6) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà máa ń la àwọn olóòótọ́ ọkàn lójú láti mú kí wọ́n lè rí i pé ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti sí ọmọnìkejì wa ló ń sún wa wàásù fáwọn èèyàn. Bákan náà, ìwà rere wa máa ń hàn kedere fáyé rí bí ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ ń bà wá lórúkọ jẹ́. Gbogbo bí onírúurú àtakò àti inúnibíni wọ̀nyí ṣe ń dojú kọ wá, Jèhófà ò dá wa dá a. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni òdodo àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ràn bí oòrùn ọjọ́kanrí.—1 Pétérù 2:12.

“Dákẹ́ Jẹ́ẹ́ . . . Fi Ìyánhànhàn Dúró Dè É”

16, 17. Ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 37:7, ìsinsìnyí jẹ́ àkókò fún kí ni, kí sì nìdí rẹ̀?

16 Ohun tí onísáàmù náà sọ lẹ́yìn náà ni pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà kí o sì fi ìyánhànhàn dúró dè é. Má ṣe gbaná jẹ mọ́ ẹnikẹ́ni tí ń mú kí ọ̀nà rẹ̀ kẹ́sẹ járí, sí ènìyàn tí ń mú èrò-ọkàn rẹ̀ ṣẹ.” (Sáàmù 37:7) Níhìn-ín Dáfídì ń tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa mú sùúrù, ká dúró de ìgbà tí Jèhófà máa dá sí ọ̀ràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí ò tíì dé, kò yẹ ká torí ìyẹn máa ráhùn. Ṣebí a ti rí i pé àánú àti sùúrù Jèhófà ga ju bá a ṣe rò lọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ àwa náà lè fi hàn wàyí pé à ń fi sùúrù dúró bí a ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà lọ ní pẹrẹu kí òpin tó dé? (Máàkù 13:10) Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká yẹra fún fífi ìwàǹwára ṣe nǹkan, èyí tó lè ba ayọ̀ wa jẹ́, kí ó sì kó wa sínú ewu nípa tẹ̀mí. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ gbógun ti ọ̀nàkọnà tí ayé Sátánì lè gbà kó èèràn ràn wá. Ìsinsìnyí gan-an ló sì yẹ ká máa hùwà mímọ́, ká má sì ṣe ohun tó lè ba ìdúró òdodo tá a ní lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́. Ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti rí i pé a kò gba èrò ìṣekúṣe láyè rárá, ká sì yẹra fún híhu ìwàkiwà pẹ̀lú ẹ̀yà òdìkejì, àti ẹ̀yà kan náà bíi tiwa pàápàá.—Kólósè 3:5.

17 Dáfídì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi. Nítorí pé àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:8, 9) Dájúdájú, a lè máa fi ìdánilójú retí ìgbà tí Jèhófà yóò mú gbogbo ìwà ìbàjẹ́ àtàwọn tó ń fà á kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ìgbà ọ̀hún sì dé tán.

“Ní Ìgbà Díẹ̀ Sí I”

18, 19. Ìṣírí wo lo rí gbà nínú Sáàmù 37:10?

18 “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí.” (Sáàmù 37:10) Ìṣírí ńláǹlà lọ̀rọ̀ yìí mà jẹ́ fún wa o bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí àti ìgbà tí wàhálà òmìnira kúrò lábẹ́ Jèhófà yóò dópin! Gbogbo onírúurú ìjọba tàbí ọlá àṣẹ táráyé ti gbìdánwò rẹ̀ ló já sí pàbó. Ní báyìí, a ti wá ń sún mọ́ ìgbà tá a ó padà sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, ìyẹn Ìjọba Jèhófà tí Jésù Kristi yóò ṣe olórí rẹ̀. Ìjọba náà ni yóò máa ṣàkóso gbogbo ayé yìí, yóò sì mú gbogbo àwọn alátakò Ìjọba Ọlọ́run kúrò.—Dáníẹ́lì 2:44.

19 Nínú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, kò ní sí “ẹni burúkú” kankan bó ti wù ká wá wọn tó. Nígbà yẹn, ẹnikẹ́ni tó bá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà pẹ́nrẹ́n yóò dàwátì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá kọjú ìjà sí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ tàbí ẹni tí kò tẹrí ba fún ọlá àṣẹ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kò ní sí níbẹ̀ rárá. Gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ ni yóò fìmọ̀ ṣọ̀kan láti máa wá ọ̀nà àtimú inú Jèhófà dùn. Ààbò gbáà nìyẹn yóò sì jẹ́, ní ti pé kò ní sí kọ́kọ́rọ́, kò ní sí ọ̀pá ìdábùú ilẹ̀kùn, àní sẹ́ kò ní sí ohunkóhun tí yóò ba ìfọkàntánni àti ayọ̀ ibẹ̀ jẹ́!—Aísáyà 65:20; Míkà 4:4; 2 Pétérù 3:13.

20, 21. (a) Àwọn wo ni “ọlọ́kàn tútù” tí Sáàmù 37:11 ń sọ, ibo ni wọ́n sì ti ń rí “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà”? (b) Àwọn ìbùkún wo la óò ní, bí a bá fara wé Dáfídì Ńlá náà?

20 Nígbà náà, “ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:11a) Ṣùgbọ́n àwọn wo làwọn “ọlọ́kàn tútù” yìí? Nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ọkàn tútù,” wá látinú ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ sí “pọ́n lójú, láti rẹ̀ sílẹ̀, láti tẹ́ lógo.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn “ọlọ́kàn tútù” ni àwọn tó fi ìrẹ̀lẹ̀ dúró de Jèhófà kí ó wá rí sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táráyé hù sí wọn. “Ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11b) Nísinsìnyí pàápàá, à ń rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàáfíà nínú párádísè tẹ̀mí tó wà nínú ìjọ Kristẹni tòótọ́.

21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro, à ń ran ara wa lọ́wọ́, a sì ń tu àwọn tí ìdààmú ọkàn bá nínú. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Àwọn arákùnrin tó wà nípò olùṣọ́ àgùntàn máa ń fi ìfẹ́ bá wa bójú tó àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nípa tẹ̀mí, àti nípa tara nígbà mìíràn pàápàá. Èyí ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa fara da ìyà nítorí òdodo. (1 Tẹsalóníkà 2:7, 11; 1 Pétérù 5:2, 3) Àlàáfíà tá a ní yìí mà dára o! Bákan náà, a sì tún ń retí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè alálàáfíà tó ń bọ̀. Nígbà náà, ń jẹ́ ká máa fara wé Jésù Kristi, Dáfídì Ńlá náà, ẹni tí ìtara tó fi ń sin Jèhófà mú kó fi ìṣòtítọ́ sìn ín dópin. (1 Pétérù 2:21) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayọ̀ wa ò ní lópin, a ó sì máa yin Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹni tí a ní inú dídùn kíkọyọyọ sí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Mọ Ìdáhùn Rẹ̀?

• Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú Sáàmù 37:1, 2?

• Báwo lo ṣe lè “ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà”?

• Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn Kristẹni kì í ṣe “ìlara àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà nípa rírí i pé o mọ̀ nípa Jèhófà jinlẹ̀ débi tó o bá lè mọ̀ ọ́n dé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé”