Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń bójú Tó Àwọn Mẹ̀kúnnù

Jèhófà Ń bójú Tó Àwọn Mẹ̀kúnnù

Jèhófà Ń bójú Tó Àwọn Mẹ̀kúnnù

ṢÉ Ó dìgbà tá a bá di èèyàn àrà ọ̀tọ̀ tàbí tá a di ẹni tó ta yọ láwọn ọ̀nà kan kí Ọlọ́run tó bìkítà nípa wa? Àwọn kan fa ọ̀rọ̀ tí Abraham Lincoln, ààrẹ kẹrìndínlógún ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ nígbà kan yọ, wọ́n ló sọ pé: “Àwọn gbáàtúù èèyàn ni Ọlọ́run fẹ́ràn jù. Ìdí nìyẹn tó fi dá wọn lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.” Ọ̀pọ̀ ló ronú pé kò sí ohun gidi kan tó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù wá. Àwọn èèyàn lè ka àwọn mẹ̀kúnnù sí àwọn “òtòṣì, aláìtẹ́gbẹ́.” Bákan náà, gbólóhùn náà “gbáàtúù” lè túmọ̀ sí àwọn tí ò rọ́wọ́ mú láwùjọ tàbí tí wọn ò lẹ́nu ọ̀rọ̀ bíi tàwọn tó ti rí já jẹ, àwọn akúṣẹ̀ẹ́ tàbí àwọn tí ò rówó lògbà. Irú àwọn èèyàn wo lo máa ń fẹ́ bá kẹ́gbẹ́? Ṣé àwọn tó máa ń ṣakọ ni àbí àwọn oníjàgídíjàgan àbí àwọn agbéraga? Ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn oníwà ọ̀rẹ́, onírẹ̀lẹ̀, amẹ̀tọ́mọ̀wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn dénú lo máa fẹ́ bá kẹ́gbẹ́?

Bí ìpániláyà àti ìfiniṣẹ̀sín ṣe ń gbilẹ̀ láyé lónìí ti mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ẹnì kan tó máa ń ka ìwé ìròyìn yìí kọ̀wé pé: “Ìdílé ti mo ti wá ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n kì í kà mí kún, wọ́n máa ń múnú bí mi wọ́n á sì máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé láti kùtùkùtù ìgbésí ayé mi ni mo ti ka ara mi sí ẹni tí ò já mọ́ ohunkóhun. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn yìí ṣì máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú bá ṣẹlẹ̀ sí mi.” Àmọ́ o, ìdí púpọ̀ wà tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù ṣeré.

Bí Ọlọ́run Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Mẹ̀kúnnù

Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, àwámáridìí sì ni títóbi rẹ̀.” (Sáàmù 145:3) Àmọ́, èyí kò ní kí Jèhófà máà bójú tó wa lọ́nà onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú. (1 Pétérù 5:7) Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.

Àwọn nǹkan tó ń fa àwọn èèyàn mọ́ra nínú ayé, irú bíi kéèyàn lẹ́wà, kó wà nípò ọlá, kó rí ti owó ṣe, kọ́ ni Ọlọ́run kà sí pàtàkì. Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn òtòṣì, ọmọ òrukàn, opó àtàwọn àjèjì lọ́pọ̀lọpọ̀. Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì táwọn èèyàn ti hàn léèmọ̀ ní Íjíbítì, pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe àtìpó níkà tàbí kí o ni ín lára . . . Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́. Bí o bá ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà.” (Ẹ́kísódù 22:21-24) Kò tán síbẹ̀ o, wòlíì Aísáyà sọ pé ó dá òun lójú pé Ọlọ́run ń bójú tó àwọn ẹni rírẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ìwọ ti di ibi odi agbára fún ẹni rírẹlẹ̀, ibi odi agbára fún òtòṣì nínú wàhálà tí ó dé bá a, ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, ibòji kúrò lọ́wọ́ ooru, nígbà tí ẹ̀fúùfù òjijì àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ dà bí ìjì òjò lára ògiri.”—Aísáyà 25:4.

Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ ‘àwòrán Ọlọ́run gẹ́lẹ́,’ ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní fífi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sáwọn gbáàtúù èèyàn. (Hébérù 1:3) Nígbà tí Jésù rí àwọn èrò tá a ‘bó láwọ, tá a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,’ “àánú wọn ṣe é.”—Mátíù 9:36.

Tún kíyè sí irú àwọn èèyàn tí Jésù yàn láti jẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀—àwọn ọkùnrin tá a pè ní àwọn èèyàn “tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ni wọ́n. (Ìṣe 4:13) Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ké sí onírúurú èèyàn láti wá gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “aláìgbàgbọ́ tàbí gbáàtúù ènìyàn èyíkéyìí” lè wá dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni kó sì di onígbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 14:24, 25) Dípò kí Ọlọ́run yan àwọn táráyé ń wárí fún, àwọn gbáàtúù èèyàn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ló yàn fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin rí pípè tí òun pè yín, ẹ̀yin ará, pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n nípa ti ara ni a pè, kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tí a bí ní ilé ọlá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run yan àwọn ohun òmùgọ̀ ayé, kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn; Ọlọ́run sì yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ohun tí ó lágbára; Ọlọ́run sì yan àwọn ohun tí kò gbayì nínú ayé àti àwọn ohun tí a fojú tẹ́ńbẹ́lú, àwọn ohun tí kò sí, kí ó lè sọ àwọn ohun tí ó wà di asán, kí ẹlẹ́ran ara kankan má bàa ṣògo níwájú Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 1:26-29.

Bákan náà ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa lónìí. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Bí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá èèyàn débi tó fi rán Ọmọ kan ṣoṣo tó bí wá sáyé láti wá kú nítorí wa, kò sídìí èyíkéyìí tó fi yẹ ká ronú pé kò nífẹ̀ẹ́ wa tàbí pé a ò já mọ́ ohunkóhun. (Jòhánù 3:16) Jésù Kristi jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti hùwà sí ẹni tó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí lọ́nà kan náà tí wọ́n á gbà hùwà sí òun. Ó sọ pé: “Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.” (Mátíù 25:40) Ojú yòówù kí aráyé máa fi wò wá, tá a bá sáà ti nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a jẹ́ pé a ti dẹni iyì ẹni ẹ̀yẹ lójú Ọlọ́run nìyẹn.

Èrò tí Francisco, a ọmọ ilẹ̀ Brazil tí kò ní bàbá, wá ní nìyẹn lẹ́yìn tó ti ní àjọse tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé pé: “Mímọ̀ tí mo wá mọ Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ ló jẹ́ kí n borí ìmọ̀lára àìláàbò tí mo ní àti ìtìjú. Mo wá rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.” Jèhófà wá di ojúlówó Bàbá fún Francisco.

Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èwe

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èwe gidi gan-an lápapọ̀ àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Òótọ́ ni pé kò yẹ ká máa ronú pé a ju bá a ṣe tó lọ, yálà a jẹ́ àgbà tàbí ọmọdé. Síbẹ̀, a lè ní àwọn ẹ̀bùn kan àtàwọn ànímọ́ kan tí Ọlọ́run lè lò lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà mọ irú àtúnṣe àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a nílò ká bàa lè lo àwọn ẹ̀bùn àti ànímọ́ tá a ní débi tó yẹ ká lò ó dé. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí àkọsílẹ̀ inú 1 Sámúẹ́lì orí 16. Lójú wòlíì Sámúẹ́lì, ó dà bíi pé àwọn ọkùnrin mìíràn wà níbẹ̀ tí ipò ọba Ísírẹ́lì tọ́ sí tí wọ́n sì tóótun ju Dáfídì lọ, àmọ́ Jèhófà ṣàlàyé ìdí tí Òun fi yan Dáfídì àbígbẹ̀yìn Jésè láti jẹ́ ọba lọ́la ní Ísírẹ́lì. Ó sọ pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́ [ìyẹn ẹ̀gbọ́n Dáfídì]. Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.

Ǹjẹ́ àwọn èwe lónìí lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn dénúdénú? Gbé ọ̀ràn obìnrin ará Brazil tó ń jẹ́ Ana yẹ̀ wò. Ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìrẹ́nijẹ tó ń rí ǹ bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an bíi tàwọn èwe mìíràn. Ni bàbá rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí mú òun àtàwọn arábìnrin rẹ̀ méjì lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Nígbà tó ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ sáwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ana bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni mìíràn bẹ́ẹ̀ ló tún ń gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó wá dẹni tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé pé: “Gígùn tí mo máa ń gun kẹ̀kẹ́ mi lọ síbi òkè kan tó wà nítòsí ilé mi láti lọ wo bí oòrùn ṣe ń wọ̀ máa ń gbádùn mọ́ mi. Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún inú rere àti ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀, mo sì máa ń sọ fún un pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Mímọ̀ tí mo wá mọ Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ ti mú káyé mi tòrò minimini ó sì ti fún mi ní ìbàlẹ̀ ọkàn.” Ǹjẹ́ ìwọ náà ń wáyè láti ṣàṣàrò lórí àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

Òótọ́ ni pé ọ̀nà tá a gbà tọ́ wa dàgbà lè mú kó ṣòro fún wa láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀ràn Lidia ṣe àpẹẹrẹ. Nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a fún bàbá rẹ̀, ńṣe ló ní kó kóra ẹ̀ sọ́hùn-ún, ó pe ọ̀rọ̀ náà ní “Òkú ọ̀rọ̀.” Lidia mọ̀ pé ńṣe ni bàbá òun fẹ́ kóun gbàgbé ìṣòro náà, àmọ́ ó sọ pé: “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún mi ní gbogbo nǹkan tí ọkàn mi fẹ́, ó tiẹ̀ tún jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Jèhófà ní mú kó di ọ̀rẹ́ tí mo fẹ́ràn jù lọ. Ní báyìí, mo ní Baba tó nífẹ̀ẹ́ tí ọ̀rọ̀ sì tètè máa ń yé, tí mo lè sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún àtàwọn ọ̀rọ̀ àṣírí tó ń bà mí lẹ́rù. Mo lè fi àìmọye wákàtí bá Ẹni gíga jù lọ láyé òun ọ̀run sọ̀rọ̀, ó sì dá mi lójú pé ó ń gbọ́ tèmi.” Àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Fílípì 4:6, 7, jẹ́ kó mọ̀ nípa àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ẹsẹ yẹn kà pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

Ó Ń Pèsè Àwọn Ohun Tó O Nílò

Jèhófà ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ló sì ń bójú tó ìjọ rẹ̀ kárí ayé. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run nípa ṣíṣètò láti bá a sọ̀rọ̀. Ká má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ láé. Dáfídì ò fìgbà kan fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Ó sọ pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi. Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sáàmù 25:4, 5.

Èrò pé kéèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run lè ṣàjèjì sí ọ. Ìṣòro èyíkéyìí tó wù kó o ní, jẹ́ kó wà lọ́kàn rẹ nígbà gbogbo pé Ẹni Gíga Jù Lọ náà lè ràn ọ́ lọ́wọ́, lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (1 Jòhánù 5:14, 15) Nítorí náà, kọ́ bí wàá ṣe jẹ́ kí àdúrà rẹ ṣe pàtó, kó bá ipò tó o wà mu àtàwọn nǹkan tó o nílò.

Àdúrà tí Sólómọ́nì Ọba gbà nígbà tó ń ṣí tẹ́ńpìlì fi hàn bó ti ṣe pàtàkì tó láti mọ àwọn ohun tá a nílò, ó gbàdúrà pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìyàn mú ní ilẹ̀ náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn jà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjógbẹ ṣẹlẹ̀ àti èbíbu, eéṣú àti aáyán; bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọ̀tá wọn sàga tì wọ́n ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè wọn—irú ìyọnu àjàkálẹ̀ èyíkéyìí àti irú àrùn èyíkéyìí—àdúrà yòówù, ìbéèrè fún ojú rere yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé olúkúlùkù wọn mọ ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀ . . . Nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run . . . kí o sì dárí jì, kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (2 Kíróníkà 6:28-30) Ká sòótọ́, ìwọ fúnra rẹ lo mọ ‘ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ àti ìrora rẹ.’ Nígbà náà, wàá rí i pé ó ṣe pàtàkì púpọ̀ kó o mọ àwọn ohun tó o dìídì nílò àtàwọn ohun tọ́kàn rẹ ń fẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, “[Jèhófà] yóò . . . fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”—Sáàmù 37:4.

Mú Àjọṣe Àárín Ìwọ àti Jèhófà Lókun Sí I

Ó wu Jèhófà pé káwọn gbáàtúù èèyàn gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un dá wa lójú pé: “‘Èmi yóò sì jẹ́ baba yín, ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’ ni Jèhófà Olódùmarè wí.” (2 Kọ́ríńtì 6:18) Ní ti gidi, Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ń fẹ́ ká ṣàṣeyọrí ká sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ ò rí bó ti ń mórí ẹni wú tó láti mọ̀ pé Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ wa nínú ìdílé, níbi iṣẹ́ àti nínú ìjọ Kristẹni!

Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo wa là ń dojú kọ àwọn àkókò tó le koko. Àìsàn, ìṣòro ìdílé, kí owó tó ń wọlé máà tó nǹkan tàbí nǹkan mìíràn lè fa ìrora fún wa. A lè máà mọ ọ̀nà tá a lè gbà kojú ìṣòro tàbí àdánwò tá a bá ní. Ẹni burúkú tó ń fẹ̀sùn kanni náà Sátánì Èṣù, tó ń gbógun tẹ̀mí ti àwọn èèyàn Ọlọ́run, ló ń fa àwọn ìṣòro tó túbọ̀ ń ròkè sí i yìí yálà ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà. Àmọ́ ẹnì kan wà tí ọ̀rọ̀ wa yé tó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Jésù Kristi lẹni náà, tó wà ní ipò gíga lókè ọ̀run. A kà pé: “Àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 4:15, 16.

Ẹ ò rí i pé ó ń fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an láti mọ̀ pé kò dìgbà tá a bá di ẹni tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta tàbí tá a lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ká tó lè rí ojú rere Ọlọ́run! Àní nígbà tí wàhálà bá bá ọ, ṣe bíi ti onísáàmù nì tó gbàdúrà pé: “Ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń gba tèmi rò. Ìwọ ni ìrànwọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.” (Sáàmù 31:9-14; 40:17) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀, ìyẹn àwọn gbáàtúù èèyàn. Ní ti tòótọ́, ‘a lè kó gbogbo àníyàn wa lọ bá a, nítorí ó bìkítà fún wa.’—1 Pétérù 5:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló jẹ́ àwọn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn Kristẹni ń sapá láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kò dìgbà tá a bá di ẹni tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta ká tó lè rí ojú rere Ọlọ́run