Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìgbàgbọ́ àti Ìjọsìn

Ẹ̀sìn

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run? Ṣé Mo Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run Bí Mi Ò Bá Ṣe Ẹ̀sìn Kankan?

Wàá rí ohun mẹ́ta tó o lè ṣe láti ní ẹ̀mí Ọlọ́run, wàá sì mọ èrò mẹ́rin tó wọ́pọ̀ tí kò tọ́ nípa rẹ̀.

Ṣé Ọ̀kan Náà Ni Gbogbo Ìsìn? Ǹjẹ́ Gbogbo Rẹ̀ Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́ Gbà?

Àwọn nǹkan méjì tí Bíbélì mẹ́nu bà jẹ́ ká mọ ohun tí ìdáhùn jẹ́.

Ṣé Ó Pọn Dandan Kéèyàn Máa Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan Pàtó?

Ṣé ó ṣeé ṣe kí èèyàn máa sin Ọlọ́run láì lọ sí ilé ìjọsìn?

Kí Nìdí Tí Onírúurú Ẹ̀sìn Kristẹni Fi Wà?

Ṣé ohun tí Jésù tó dá ìsìn Kristẹni tòótọ́ sílẹ̀ fẹ́ nìyí?

Báwo Lo Ṣe Lè Dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀?

Bíbélì sọ ohun mẹ́sàn-án tá a lè fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀.

Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?

Ṣe a ṣì ń retí rẹ̀ àbí ó ti dé?

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Mímọ́?

Ṣé èèyàn aláìpé bíi tiwa lè jẹ́ mímọ́?

Àdúrà

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbọ́ Mi Tí Mo Bá Gbàdúrà?

Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn ìṣòro wa?

Ṣé Ọlọ́run Á Gbọ́ Àdúrà Mi?

Bóyá Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà tó o bá gbà tàbí kò ní gbọ́ kù sí ọwọ́ rẹ.

Ṣé Àdúrà Olúwa Ni Àdúrà Tó Dáa Jù Láti Gbà?

Ṣé Àdúrà Olúwa nìkan ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?

Kí Ni Mo Lè Gbàdúrà Fún?

Mọ bí dídáhùn àdúrà nípa ọ̀rọ̀ ara ẹni ò ṣe lè ṣòro fún Ọlọ́run.

Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbọ́dọ̀ Gbàdúrà Lórúkọ Jésù?

Ṣàgbéyẹ̀wò nípa bí gbígbàdúrà lórúkọ Jésù ṣe ń bọlá fún Ọlọ́run tó sì ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jésù.

Ṣó Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà sí Àwọn Ẹni Mímọ́?

Ka ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tó yẹ ká gbàdúrà sí.

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Fi Í Gbọ́ Àwọn Àdúrà Kan?

Kà nípa irú àwọn àdúrà tí Ọlọ́run kì í gbọ́ àti irú àwọn ẹni tí Ọlọ́run kì í gbọ́ tiwọn.

Ìgbàlà

Ṣé Èèyàn Máa Rí Ìgbàlà Tó Bá Ṣáà Ti Gba Jésù Gbọ́?

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó gba Jésù gbọ́ àmọ́ tí wọn ò ní rígbàlà. Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Kí Ni Ìgbàlà?

Báwo la ṣe lè rí ìgbàlà? Ìgbàlà lọ́wọ́ kí ni?

Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?

Kí nìdí tá a fi nílò Jésù láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa? Ṣé ta bá ṣáà nígbàgbọ́ nínú Jésù, a máa rí ìgbàlà?

Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Báwo ni ikú rẹ̀ ṣe ṣe wá láǹfààní gan-an?

Kí Ni Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí?

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣèrìbọmi ló wà nínú Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí àti bó ti ṣe pàtàkì tó.

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Di Àtúnbí?

Ṣé ó di dandan kó o di àtúnbí kó o tó di Kristẹni?

Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ìdáríjì

Ki Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sì jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ wọn bí ìgbà tí ọmọ kan bá jogún àwọn àbùkù kan lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀.

Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?

Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ máa ń burú ju ara wọn lọ?

Kí Ni Ìdáríjì?

Bíbélì sọ ohun márùn-ún tó lè ràn ẹ lọ́wọ́ láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ọ́.

Ṣé Ọlọ́run Máa Dárí Jì Mí?

Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe lè rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà.

Ṣé Bíbélì Lè Mára Tu Àwọn Tó Ń Dá Ara Wọn Lẹ́bi?

Tó o bá ń dá ara ẹ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, o lè ṣe ara ẹ léṣe, àmọ́ àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ṣé “Ẹ̀ṣẹ̀ Méje Tó La Ikú Lọ” Wà Lóòótọ́?

Ibo ni wọ́n ti rí i? Ìyàtọ̀ wo ló sì wà láàárín ẹ̀ṣẹ̀ tí ń fa ikú wá báni àtèyí tí kì í fa ikú wá báni?

Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Kò Ní Ìdáríjì?

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá o ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì?

Kí Ni Ìtumọ̀ “Ojú fún Ojú”?

Ṣé òfin “ojú fún ojú” fún àwọn èèyàn láṣẹ láti gbẹ̀san ara wọn?

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?

Tó bá jẹ́ pé Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa sìgá mímu, báwo la ṣe lè dáhùn ìbéèrè yìí?

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?

Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa tẹ́tẹ́ títa, báwo la ṣe wá lè mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó?

Àṣà Èsìn

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìdá Mẹ́wàá

Ìyàtọ̀ tó wà nínú ohun tí Bíbélì sọ gan-an àti ohun táwọn èèyàn sọ lè yà ọ́ lẹ́nu.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jọ́sìn Àwọn Ère?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo àwọn ère nínú ìjọsìn wa?

Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Pa Sábáàtì Mọ́?

Tí kò bá yẹ́ bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Bíbélì fi pe Sábáàtì ní májẹ̀mú títí láé?

Kí Ni Bíbélì Kọ́ni Nípa Fífi Èdè Fọ̀?

Ṣé ẹ̀bùn ẹ̀mí la fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ààwẹ̀?

Kí ló fà á táwọn kan nínú Bíbélì fi gbààwẹ̀? Ṣé Bíbélì sọ pé káwọn Kristẹnì máa gbààwẹ̀?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fífúnni?

Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa fúnni?

Kí Ni Òfin Mẹ́wàá Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Àwọn wo ni Ọlọ́run fún ní òfin yìí? Ṣé ó di dandan káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé e?