Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọlọ́run

Ta Ni Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Wà?

Bíbélì fún wa ní ẹ̀rí márùn-ún tó jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà.

Ṣé Ẹni Gidi Ni Ọlọ́run?

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lo agbára rẹ̀ láti dá ohun gbogbo, àmọ́ ṣe ó tiẹ̀ bìkítà nípa wa?

Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?

Ṣé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà? Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé ibì kan pàtó ló ń gbé, síbẹ̀ ó mọ̀ ẹ́ dáadáa?

Ǹjẹ́ Ibì Kan Wà Tí Ọlọ́run Ń Gbé?

Kí ni Bíbélì sọ nípa ibi tí Ọlọ́run ń gbé? Ṣé ibi kan náà ní Jésù ń gbé?

Ṣé Ẹnì Kan Wà Tó Rí Ọlọ́run Rí?

Ṣé Bíbélì ta ko ara rẹ̀ ni nígbà tó sọ níbì kan pé ‘kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run rí,’ tó sì tún sọ níbòmíì pé Mósè “rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì”?

Ṣé Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Wà Nínú Bíbélì?

Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Ṣé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn?

Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?

Ìwé Mímọ́ àti ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni sọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ẹ̀kọ́ yìí.

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Pèrò Dà?

Ṣé Bíbélì ta ko ara rẹ̀ nígbà tó ní Ọlọ́run sọ pé “èmi kò yí padà” àti nígbà tó sọ pé “èmi yóò pèrò dà”?

Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

Ó ní ìdí pàtàkì tí Bíbélì fi pe ẹ̀mí mímọ́ ní “ìka” Ọlọ́run.

God’s Name

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Orúkọ?

Orúkọ Ọlọ́run wà nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì. Ṣé o yẹ kí o máa lò ó?

Ṣé Jésù Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Jésù kò pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run Olódùmarè. Kí nìdí?

Ta Ni Jèhófà?

Ṣé Ọlọ́run àwọn èèyàn kan ni bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

Orúkọ Mélòó Ni Ọlọ́run Ní?

Àwọn èèyàn lè máa rò pé oríṣiríṣi orúkọ ni Ọlọ́run ń jẹ́, bí ‘Allah’, ‘Ááfà àti Ómégà’, ‘El Shaddai,’ àti ‘Jèhófá-jirè.’ Ṣé ó ṣe pàtàkì ká mọ orúkọ tó yẹ ká máa pe Ọlọ́run?

Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́

Kí Ni Ọlọ́run Fẹ́ Kí N Fi Ayé Mi Ṣe?

Ǹjẹ́ o nílò kí Ọlọ́run fi àmì àrà ọ̀tọ̀ kan hàn ọ́ tàbí kí Ọlọ́run bá ọ sọ̀rọ̀ kó o tó mọ bí wàá ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ka ohun tí Bíbélì sọ.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Òmìnira Láti Yan Ohun Tó Wuni? Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Darí Gbogbo Nǹkan?

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé àwọn. Ǹjẹ́ ohun tá a bá yan láti ṣe ló máa ń pinnu bóyá a ó ṣàṣeyọrí?

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ọlọ́run?

Ohun méje tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

Ṣé Ọlọ́run Ló Fa Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Ìpọ́njú lè bá ẹnikẹ́ni, títí kan àwọn tí Ọlọ́run ṣojú rere sí pàápàá. Kí nìdí?