Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ta Ni Jèhófà?

Ta Ni Jèhófà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ tó wà nínú Bíbélì, òun sì ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. (Ìṣípayá 4:11) Àwọn wòlíì bí Ábúráhámù àti Mósè jọ́sìn rẹ̀ bíi ti Jésù. (Jẹ́nẹ́sísì 24:27; Ẹ́kísódù 15:1, 2; Jòhánù 20:17) Òun ni Ọlọ́run “gbogbo ilẹ̀ ayé,” kì í kàn ṣe Ọlọ́run àwọn èèyàn kan.​—Sáàmù 47:2.

 Orúkọ tó dá yàtọ̀ tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ń jẹ́ ni Jèhófà. (Ẹ́kísódù 3:15; Sáàmù 83:18) Orúkọ náà wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “mú kí ó dì,” ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ sì sọ pé orúkọ náà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Ìtumọ̀ orúkọ yìí bá ipò Jèhófà mu gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá àti Ẹni tó ń mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Aísáyà 55:10, 11) Bákàn náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó gbawájú jù lọ.—Ẹ́kísódù 34:5-7; Lúùkù 6:35; 1 Jòhánù 4:8.

 Orúkọ náà “Jehovah” lédè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n tú sí Jèhófà lédè Yorùbá wá látinú lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà יהוה (YHWH) tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. A kò mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ náà ní èdè Hébérù àtijọ́. Àmọ́, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń lo orúkọ náà “Jèhófà” ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, inú ìtumọ̀ Bíbélì William Tyndale ló ti kọ́kọ́ fara hàn lọ́dún 1530. a

Kí nìdí tí a kò fi mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run ní èdè Hébérù àtijọ́?

 Wọn kì í fi fáwẹ̀lì sáàárín ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àtijọ́ tí wọ́n bá kọ, kọ́ńsónáǹtì nìkan ni wọ́n ń lò. Tí ẹni tó gbọ́ èdè Hébérù bá ń kàwé, ó rọrùn fún ẹni náà láti fi àwọn fáwẹ̀lì tó yẹ sáàárín àwọn kọ́ńsónáǹtì náà. Lẹ́yìn tí wọ́n kọ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù (“Májẹ̀mú Láéláé”), àwọn Júù kan gba ẹ̀kọ́ èké náà gbọ́ pé kò dáa kéèyàn máa pe orúkọ Ọlọ́run. Tí wọ́n bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ní orúkọ Ọlọ́run nínú, ńṣe ni wọ́n máa fi àwọn ọ̀rọ̀ bí “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” dípò rẹ̀. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n gbà gbọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí tàn kiri títí táwọn èèyàn ìgbà yẹn kò fi mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run mọ́. b

 Àwọn kan rò pé “Yahweh” ló yẹ kí wọ́n pe orúkọ Ọlọ́run, àwọn míì dábàá onírúurú ọ̀nà míì. Nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, wọ́n rí apá kan lára ìwé Léfítíkù tí wọ́n dà kọ lédè Gíríìkì tó lo Iao fún orúkọ Ọlọ́run. Àwọn òǹkọ̀wé èdè Gíríìkì nígbà àtijọ́ dábàá pé a tún lè pe orúkọ náà ní Iae, I·a·beʹ àti I·a·ou·e,ʹ àmọ́ kò sí èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà yìí tá a lè fi gbogbo ẹnu sọ pé òun ni wọ́n lò nínú èdè Hébérù àtijọ́. c

Àwọn àṣìlóye wo ni àwọn kan ni nípa orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì

 Àṣìlóye: Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì tó lo orúkọ náà “Jèhófà” kàn fi kún-un ni, kò sí níbẹ̀.

 Òótọ́: Orúkọ Ọlọ́run tí lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin dúró fún fara hàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà. d Èyí tó pọ jù nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò láìnídìí, wọ́n sì ti fi orúkọ oyè bí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀.

 Àṣìlóye: Kò yẹ ká fún Ọlọ́run Olódùmarè ní orúkọ kan tó dá yàtọ̀.

 Òótọ́: Ọlọ́run fúnra rẹ̀ mí sí àwọn tó kọ Bíbélì láti lo orúkọ rẹ̀ láìmọye ìgbà, ó sì tún sọ fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa lo orúkọ òun. (Aísáyà 42:8; Jóẹ́lì 2:32; Málákì 3:16; Róòmù 10:13) Kódà Ọlọ́run bínú sí àwọn wòlíì èké tó gbìyànjú láti mú kí àwọn èèyàn gbà gbé orúkọ rẹ̀.​—Jeremáyà 23:27.

 Àṣìlóye: Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Júù, ó yẹ kí wọ́n yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì.

 Òótọ́: Òótọ́ ni pé àwọn akọ̀wé Júù kan kì í pe orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n bá ń kàwé. Àmọ́, wọn ò yọ ọ́ kúrò nínú ẹ̀dà Bíbélì wọn. Lábẹ́ ipò èyíkéyìí, Ọlọ́run kò fẹ́ ká tẹ̀ lé àṣà àwọn èèyàn tó bá ti ta ko àwọn òfin rẹ̀.​—Mátíù 15:1-3.

 Àṣìlóye: Kò yẹ kí orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì torí a ò mọ bí wọ́n ṣe ń pè é lédè Hébérù.

 Òótọ́: Ohun táwọn tó ronú lọ́nà yìí ní lọ́kàn ni pé Ọlọ́run retí pé kí àwọn èèyàn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra máa pe orúkọ òun lọ́nà kan náà. Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé àwọn olùjọsìn Ọlọ́run láyé àtijọ́ tí wọ́n sọ èdè tó yàtọ̀ síra pe àwọn orúkọ àwọn èèyàn lọ́nà tó yàtọ̀ síra.

 Jẹ́ ká fi orúkọ Jóṣúà tó jẹ́ onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe àpẹẹrẹ. Ó ṣeé ṣe kí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń sọ èdè Hébérù pe orúkọ rẹ̀ ní Yehoh·shuʹaʽ, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì pè é ní I·e·sousʹ. Nínú Bíbélì, a rí àwọn ẹsẹ kan tí wọ́n ti lo ìtúmọ̀ orúkọ Jóṣúà ní èdè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì, èyí tó fi hàn pé àwọn Kristẹni náà ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu bí wọ́n ṣe pe orúkọ àwọn èèyàn lọ́nà tó bá èdè wọn mu.​—Ìṣe 7:45; Hébérù 4:8.

 A lè lo ìlànà yìí kan náà nínú ìtúmọ̀ orúkọ Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí orúkọ Ọlọ́run fara hàn láwọn ibi tó yẹ nínú Bíbélì ju bí wọ́n ṣe ń pè é gẹ́lẹ́ lọ.

a Tyndale lo “Iehouah” fún orúkọ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ ìwé Bíbélì márùn-ún àkọ́kọ́ tó ṣe. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì ń yí pa dà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orúkọ náà lọ́nà tó bóde mu. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1612 nígbà tí Henry Ainsworth túmọ̀ ìwé Sáàmù, “Iehovah” ló lò jálẹ̀ ìwé náà. Nígbà tí wọ́n ṣàtúnṣe ìtumọ̀ náà lọ́dún 1639, “Jehovah” ni wọ́n lò. Bákan náà, àwọn atúmọ̀ èdè tó ṣe Bíbélì American Standard Version tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1901 lo “Jehovah” níbi tí orúkọ Ọlọ́run bá ti fara hàn lédè Hébérù.

b Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ń jẹ́ New Catholic Encyclopedia, Ẹ̀dà kejì, Ìdìpọ̀ kẹrìnlá, ojú ìwé 883 àti 884 sọ pé: “Nígbà táwọn Júù pa dà dé láti ìgbèkùn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ki àṣejù bọ bí wọ́n ṣe láwọn ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ náà Yahweh, wọ́n wá ń fi ọ̀rọ̀ bí ÁDÓNÁÌ tàbí ÉLÓHÍMÙ rọ́pò rẹ̀.”

c Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo apá tá a pè ní Appendix A4, “The Divine Name in the Hebrew Scriptures,” tó wà nínú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures, (èdè Gẹ̀ẹ́sì).

d Wo ìwé Theological Lexicon of the Old Testament, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 523 àti 524.