Jóẹ́lì 2:1-32

  • Ọjọ́ Jèhófà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (1-11)

  • Ìkésíni láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (12-17)

    • “Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya” (13)

  • Ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ (18-32)

    • “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi” (28)

    • Àwọn ohun ìyanu lójú ọ̀run àti ní ayé (30)

    • Àwọn tó ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò rí ìgbàlà (32)

2  “Ẹ fun ìwo ní Síónì!+Ẹ kéde ogun ní òkè mímọ́ mi. Kí jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,*Torí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀!+ Ó sún mọ́lé!  2  Ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ lórí àwọn òkè. Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì lágbára;+Kò tíì sí irú wọn rí,Irú wọn kò sì ní sí mọ́ láé,Jálẹ̀ àwọn ọdún láti ìran dé ìran.  3  Iná ń jẹ àwọn ohun tó wà níwájú wọn,Ọwọ́ iná sì ń run àwọn ohun tó wà lẹ́yìn wọn.+ Ilẹ̀ iwájú wọn dà bí ọgbà Édẹ́nì,+Àmọ́ aginjù tó ti di ahoro ló wà lẹ́yìn wọn,Kò sì sí ohun tó lè yè bọ́.  4  Wọ́n rí bí ẹṣin,Wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin ogun.+  5  Ìró wọn dà bíi ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó ń bẹ́ gìjà lórí àwọn òkè,+Bí ìró iná ajófòfò tó ń jó àgékù pòròpórò. Wọ́n dà bí àwọn alágbára, tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+  6  Ìdààmú máa bá àwọn èèyàn náà nítorí wọn,Ìbẹ̀rù yóò sì hàn lójú gbogbo èèyàn.  7  Wọ́n ń rọ́ gììrì bí àwọn jagunjagun,Wọ́n gun ògiri bí àwọn ọmọ ogun,Wọ́n tò tẹ̀ léra,Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì kúrò lójú ọ̀nà rẹ̀.  8  Wọn kì í ti ara wọn;Kálukú wọn ń tọ ọ̀nà tirẹ̀. Bí ohun ìjà* bá gbé àwọn kan ṣubú lára wọn,Àwọn tó ṣẹ́ kù kì í tú ká.  9  Wọ́n rọ́ wọnú ìlú, wọ́n sáré lórí ògiri. Wọ́n gun orí àwọn ilé, wọ́n sì gba àwọn ojú fèrèsé* wọlé bí olè. 10  Ilẹ̀ mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì mì jìgìjìgì. Oòrùn àti òṣùpá ti ṣókùnkùn,+Àwọn ìràwọ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́. 11  Jèhófà yóò gbé ohùn sókè níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+ torí wọ́n pọ̀ gan-an nínú ibùdó rẹ̀.+ Alágbára ni ẹni tó ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;Torí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jèhófà, ó sì ń bani lẹ́rù.+ Ta ló lè fara dà á?”+ 12  “Síbẹ̀, ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi báyìí,” ni Jèhófà wí,+“Kí ẹ gbààwẹ̀,+ kí ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún. 13  Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,Torí ó ń gba tẹni rò,* ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+Òun yóò sì pèrò dà* nípa àjálù náà. 14  Ta ló mọ̀ bóyá ó máa tún ìpinnu ṣe, kó sì pèrò dà,*+Kó sì mú kí ìbùkún ṣẹ́ kù fún yín,Kí ẹ lè fi ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà Ọlọ́run yín? 15  Ẹ fun ìwo ní Síónì! Ẹ kéde ààwẹ̀;* ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+ 16  Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ; ẹ sọ ìjọ di mímọ́.+ Ẹ kó àwọn àgbà ọkùnrin* jọ, kí ẹ sì kó àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.+ Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò nínú yàrá rẹ̀ tó wà ní inú, kí ìyàwó pẹ̀lú kúrò nínú yàrá* rẹ̀. 17  Kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sunkúnLáàárín ibi àbáwọlé* àti pẹpẹ,+ kí wọ́n sì sọ pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ ṣàánú àwọn èèyàn rẹ;Má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn fi ogún rẹ ṣẹlẹ́yà,Kó wá di pé àwọn orílẹ̀-èdè á máa jọba lórí wọn,Tí àwọn èèyàn á fi máa sọ pé, “Ibo ni Ọlọ́run wọn wà?”’+ 18  Jèhófà yóò ní ìtara nítorí ilẹ̀ rẹ̀,Yóò sì ṣàánú àwọn èèyàn rẹ̀.+ 19  Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ lóhùn pé: ‘Màá fi ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró ránṣẹ́ sí yín,Yóò sì tẹ́ yín lọ́rùn;+Mi ò ní jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè fi yín ṣẹlẹ́yà mọ́.+ 20  Màá lé àwọn ará àríwá jìnnà sí yín;Màá fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ tí kò lómi tó sì ti di ahoro,Àwọn tó wà níwájú yóò forí lé ọ̀nà òkun* ìlà oòrùn*Àwọn tó wà lẹ́yìn yóò sì forí lé ọ̀nà òkun ìwọ̀ oòrùn.* Òórùn wọn yóò gbalẹ̀ kan,Wọn yóò sì máa rùn ṣáá;+Torí pé Òun yóò ṣe àwọn ohun ńlá.’ 21  Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀. Máa yọ̀, kí inú rẹ sì dùn, torí pé Jèhófà máa ṣe àwọn ohun ńlá. 22  Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹran inú igbó,Torí àwọn ibi ìjẹko inú aginjù yóò hu ewéko tútù,+Àwọn igi yóò sì mú èso jáde;+Igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi àjàrà yóò so wọ̀ǹtìwọnti.+ 23  Ẹ̀yin ọmọ Síónì, ẹ máa yọ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run yín sì mú inú yín dùn;+Torí ó máa rọ òjò fún yín ní ìwọ̀n tó yẹ nígbà ìwọ́wé,Yóò sì rọ òjò lé yín lórí,Nígbà ìwọ́wé àti nígbà ìrúwé, bíi ti tẹ́lẹ̀.+ 24  Ọkà tó mọ́ máa kún àwọn ibi ìpakà,Wáìnì tuntun àti òróró á sì kún àwọn ibi ìfúntí yín ní àkúnwọ́sílẹ̀.+ 25  Màá sì san àwọn ohun tí ẹ ti pàdánù láwọn ọdún yẹn fún yínÀwọn ọdún tí ọ̀wọ́ eéṣú, eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́, ọ̀yánnú eéṣú àti eéṣú tó ń jẹ nǹkan run fi jẹ irè oko yín,Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán sáàárín yín.+ 26  Ó dájú pé ẹ ó jẹ àjẹyó,+Ẹ ó sì yin orúkọ Jèhófà Ọlọ́run yín,+Ẹni tó ti ṣe ohun ìyanu fún yín;Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.+ 27  Ẹ ó sì mọ̀ pé mo wà láàárín Ísírẹ́lì+Àti pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kò sí ẹlòmíì! Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé. 28  Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò tú ẹ̀mí mi + sára onírúurú èèyàn,Àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀,Àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò máa lá àlá. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò sì máa rí ìran.+ 29  Kódà, ní àwọn ọjọ́ náà,Èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi. 30  Èmi yóò fi àwọn ohun ìyanu* hàn lójú ọ̀run àti ní ayé,Ẹ̀jẹ̀ àti iná pẹ̀lú ọwọ̀n èéfín.*+ 31  Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá yóò sì di ẹ̀jẹ̀+Kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù tó dé.+ 32  Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò sì rí ìgbàlà;+Torí àwọn tó sá àsálà yóò wà ní Òkè Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù+ bí Jèhófà ṣe sọ,Àwọn tó là á já tí Jèhófà pè.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Tàbí “ayé.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Tàbí “ohun ọṣẹ́.”
^ Tàbí “wíńdò.”
^ Tàbí “ó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́.”
^ Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
^ Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”
^ Ní Héb., “Ẹ sọ ààwẹ̀ di mímọ́.”
^ Ní Héb., “yàrá ìgbéyàwó.”
^ Tàbí “àgbààgbà.”
^ Tàbí “gọ̀bì.”
^ Ní Héb., “yóò kọjú sí ọ̀nà òkun.”
^ Ìyẹn, Òkun Òkú.
^ Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.
^ Tàbí “àmì.”
^ Tàbí “èéfín tó rí bí òpó.”