Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Jésù

Ta Ni Jésù?

Ṣé Èèyàn Rere Nìkan Ni Jésù?

Ohun tó mú kí Jésù ará Násárétì jẹ́ ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn tó ti gbé láyé rí.

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run Olódùmarè?

Kí ni Jésù sọ nípa ipò tí òun wà àti ipò tí Ọlọ́run wà?

Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?

Bí Ọlọ́run kò bá bí Jésù bí ìgbà téèyàn bímọ, báwo ni Jésù ṣe jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run?

Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?

Ṣe a ṣì ń retí rẹ̀ àbí ó ti dé?

Kí Là Ń Pè Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Ọ̀rọ̀ náà ní ju ìtumọ̀ kan lọ nínú Bíbélì.

Ta Ni Máíkẹ́lì, Olú-Áńgẹ́lì?

Ó tún ní orúkọ míì tó ṣeé ṣe kó jẹ́ òun lo mọ̀ dáadáa.

Ìgbà Tí Jésù Wà Láyé

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?

Kà nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì ní December 25.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Màríà Wúńdíá?

Àwọn kan sọ pé wúńdíá tó bí Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣé Bíbélì jẹ́rìí sí i pé bẹ́ẹ̀ ló rí?

Àwọn Wo Ni “Amòye Mẹ́ta Náà”? Ṣé “Ìràwọ̀” Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ni Wọ́n Tẹ̀ Lé?

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbajúmọ̀ tí wọ́n máa ń sọ nígbà Kérésìmesì ni kò sí nínú Bíbélì.

Ǹjẹ́ Àwọn Ọ̀mọ̀wé Gbà Pé Jésù Wà?

Kọ́ nípa bóyá wọ́n gbà pé Jésù wà lóòótọ́.

Ǹjẹ́ Àkọsílẹ̀ Bíbélì Nípa Ìgbésí Ayé Jésù Péye?

Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tó jóòótọ́ nípa àkọsílẹ̀ tó wà nínu ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ tó pẹ́ jù lọ.

Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?

Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan kan nípa ìrísí Jésù.

Se Jesu Segbeyawo? Se Jesu Ni Awon Aburo?

Bó tile jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ní pàtó pé Jésù ṣègbéyàwó tàbí kò ṣe. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ó ṣègbéyàwó tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀?

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ìtàn Jésù?

Báwo ló ṣe pẹ́ tó lẹ́yìn tí Jésù kú kí wọ́n tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere?

Ikú àti Àjíǹde Jésù

Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Báwo ni ikú rẹ̀ ṣe ṣe wá láǹfààní gan-an?

Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?

Àmì tí àwọn èèyàn fi ń dá àwọn Kristẹni mọ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ka àgbélébùú sí. Ṣe ó yẹ ká máa lò ó nínú ìjọsìn?

Ṣé Aṣọ Ìsìnkú Turin Ni Wọ́n Fi Sin Òkú Jésù?

Kókó pàtàkì mẹ́ta nípa Aṣọ Ìsìnkú náà jẹ́ ká mọ ìdáhùn.

Lẹ́yìn Tí Jésù Jíǹde, Ṣé Ara Èèyàn Ló Ṣì Ní àbí Ó Ti Di Ẹ̀dá Ẹ̀mí?

Bíbélì sọ pé a sọ Jésù di “ààyè nínú ẹ̀mí,” báwo wá ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe rí i tí wọ́n sì fọwọ́ kàn án nígbà tó jíǹde?

Bí Jésù Ṣé Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?

Kí nìdí tá a fi nílò Jésù láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa? Ṣé ta bá ṣáà nígbàgbọ́ nínú Jésù, a máa rí ìgbàlà?

Ṣé Èèyàn Máa Rí Ìgbàlà Tó Bá Ṣáà Ti Gba Jésù Gbọ́?

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó gba Jésù gbọ́ àmọ́ tí wọn ò ní rígbàlà. Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbọ́dọ̀ Gbàdúrà Lórúkọ Jésù?

Ṣàgbéyẹ̀wò nípa bí gbígbàdúrà lórúkọ Jésù ṣe ń bọlá fún Ọlọ́run tó sì ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jésù.

Kí Ni Ìpadàbọ̀ Kristi?

Ǹjẹ́ a máa lè fojú rí i tó bá dé?