Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run Olódùmarè?

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run Olódùmarè?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

 Àwọn tó ń tako Jésù fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ pé òun bá Ọlọ́run dọ́gba. (Jòhánù 5:18; 10:30-33) Àmọ́, Jésù kò fìgbà kan sọ pé òun bá Ọlọ́run Olódùmarè dọ́gba. Ó sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.”—Jòhánù 14:28.

 Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò gbà pé Jésù bá Ọlọ́run Olódùmarè dọ́gba. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí Jésù dìde, “Ó gbé [Jésù] sí ipò gíga.” Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù kò gbà gbọ́ pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè. Bó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́rùn Olódùmarè ni, Bíbélì kò ní sọ pé Ọlọ́rùn tún gbé e sí ipò gíga.—Fílípì 2:9.