Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ó Pọn Dandan Kéèyàn Máa Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan Pàtó?

Ṣé Ó Pọn Dandan Kéèyàn Máa Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan Pàtó?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa pé jọ láti jọ́sìn òun. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.”​—Hébérù 10:24, 25.

 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa jẹ́ àwùjọ kan tá a ṣètò fún ìjọsìn nígbà tó sọ fún wọn pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ọ̀nà pàtàkì kan tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi gbà ń fi ìfẹ́ yìí hàn ni pé kí wọ́n máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Wọ́n á máa pà dé pọ̀ déédéé gẹ́gẹ́ bí ìjọ láti jọ́sìn pa pọ̀. (1 Kọ́ríńtì 16:19) Gbogbo àwọn ìjọ yìí á para pọ̀ di ẹgbẹ́ ará kárí ayé.​—1 Pétérù 2:17.

Ohun míì tún wà tó ṣe pàtàkì ju kéèyàn kàn máa ṣe ẹ̀sìn kan lọ

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì fi hàn pé ó yẹ kí àwa èèyàn máa jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀, àmọ́ kò kọ́ wa pé bí ẹnì kan bá sáà ti ń ṣe ẹ̀sìn kan ó ti ń ṣe ohun tó ń mú inú Ọlọ́run dùn nìyẹn. Tá a bá fẹ́ kí inú Ọlọ́run dùn sí wa, ẹ̀sìn tí à ń ṣe gbọ́dọ̀ hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.”​—Jákọ́bù 1:27.