Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 16:1-24

  • Wọ́n kó nǹkan jọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù (1-4)

  • Ètò ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù (5-9)

  • Ó ṣètò bí Tímótì àti Àpólò ṣe máa bẹ àwọn ará wò (10-12)

  • Ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìkíni (13-24)

16  Ní ti àwọn ohun tí ẹ fẹ́ kó jọ fún àwọn ẹni mímọ́,+ ẹ lè tẹ̀ lé ìlànà tí mo fún àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà.  Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí kálukú yín ya ohun kan sọ́tọ̀ bí agbára rẹ̀ bá ṣe tó, kó má bàa sí pé ẹ̀ ń kó nǹkan jọ nígbà tí mo bá dé.  Àmọ́ nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, màá ní kí àwọn ọkùnrin tí ẹ fọwọ́ sí nínú àwọn lẹ́tà yín  + kó ẹ̀bùn àtọkànwá yín lọ sí Jerúsálẹ́mù.  Àmọ́, tí mo bá rí i pé ó yẹ kí èmi náà lọ síbẹ̀, wọ́n á bá mi lọ.  Ṣùgbọ́n màá wá sọ́dọ̀ yín tí mo bá ti kọjá ní Makedóníà, torí mo máa gba Makedóníà kọjá;+  ó sì ṣeé ṣe kí n dúró tàbí kí n tiẹ̀ lo ìgbà òtútù pẹ̀lú yín, kí ẹ lè sìn mí dé ọ̀nà ibi tí mo bá ń lọ.  Torí mi ò kàn fẹ́ rí yín fẹ́rẹ́ tí mo bá ń kọjá, nítorí mo ní in lọ́kàn láti lo ìgbà díẹ̀ lọ́dọ̀ yín,+ tí Jèhófà* bá yọ̀ǹda.  Àmọ́ màá wà ní Éfésù+ títí di ìgbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì,  nítorí ilẹ̀kùn ńlá ti ṣí sílẹ̀ fún mi láti ṣe iṣẹ́ púpọ̀,+ àmọ́ ọ̀pọ̀ alátakò ló wà. 10  Tóò, tí Tímótì+ bá dé, ẹ rí i pé kò sí ohun kankan tó ń bà á lẹ́rù láàárín yín, nítorí iṣẹ́ Jèhófà* ló ń ṣe,+ bí èmi náà ti ń ṣe. 11  Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fojú kéré rẹ̀. Ẹ yọ̀ǹda rẹ̀ kó máa lọ ní àlàáfíà, kó lè wá sọ́dọ̀ mi, torí mò ń dúró dè é pẹ̀lú àwọn ará. 12  Ní ti Àpólò+ arákùnrin wa, mo pàrọwà fún un gidigidi láti tẹ̀ lé àwọn ará wá sọ́dọ̀ yín. Àmọ́ kò tíì fẹ́ wá báyìí, ó máa wá nígbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀ fún un. 13  Ẹ wà lójúfò,+ ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,+ ẹ ṣe bí ọkùnrin,*+ ẹ di alágbára.+ 14  Ẹ máa fi ìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tí ẹ bá ń ṣe.+ 15  Ní báyìí, mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ará: Ẹ mọ̀ pé agbo ilé Sítéfánásì ni àkọ́so Ákáyà àti pé wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́. 16  Kí ẹ̀yin náà máa tẹrí ba fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ àti fún gbogbo àwọn tó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kára.+ 17  Inú mi dùn pé Sítéfánásì+ àti Fọ́túnátù pẹ̀lú Ákáíkọ́sì wà níbí, nítorí wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ bá máa ṣe ká ní ẹ wà níbí. 18  Wọ́n ti mú ìtura bá ẹ̀mí mi àti tiyín. Nítorí náà, ẹ máa ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí. 19  Àwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà kí yín. Ákúílà àti Pírísíkà pẹ̀lú ìjọ tó wà ní ilé wọn+ kí yín tayọ̀tayọ̀ nínú Olúwa. 20  Gbogbo àwọn ará kí yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. 21  Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ. 22  Tí ẹnikẹ́ni kò bá nífẹ̀ẹ́ Olúwa, kí ó di ẹni ègún. Ìwọ Olúwa wa, máa bọ̀! 23  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa wà pẹ̀lú yín. 24  Kí ìfẹ́ mi wà pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jésù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ẹ jẹ́ onígboyà.”