Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Ìgbàlà?

Kí Ni Ìgbàlà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Àwọn tó kọ Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “gbà là” àti “ìgbàlà” nígbà míì tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tí wọ́n gbà nínú ewu tàbí tí wọ́n gbà sílẹ̀ kó má bàa pa run. (Ẹ́kísódù 14:13, 14; Ìṣe 27:20) Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbàlà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ làwọn ọ̀rọ̀ yìí máa ń tọ́ka sí. (Mátíù 1:21) Torí pé ẹ̀ṣẹ̀ ló ń fa ikú, àwọn tá a bá gbà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nírètí pé àwọn máa wà láàyè títí láé.​—Jòhánù 3:16, 17. a

Báwo lo ṣe lè rí ìgbàlà?

 Kó o tó lè rígbàlà, o gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù, o sì gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ohun tó sọ kó o lè fi hàn pé o nígbàgbọ́ lóòótọ́.​—Ìṣe 4:10, 12; Róòmù 10:9, 10; Hébérù 5:9.

 Bíbélì sọ pé o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn iṣẹ́, tàbí lédè míì, kó o máa ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, kó o lè fi hàn pé ìgbàgbọ́ tó o ní kì í ṣe òkú. (Jákọ́bù 2:24, 26) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ló máa mú kó o rí ìgbàlà o. “Ẹ̀bùn Ọlọ́run” ni, “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” tàbí “oore-ọ̀fẹ́” rẹ̀ ló máa mú kó o rí ìgbàlà​—Éfésù 2:8, 9; Bíbélì Mímọ́.

Ṣé ìgbàlà lè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan kó sómi, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mumi yó, ẹnì kan wá gbà á sílẹ̀. Onítọ̀hún tún lè pa dà bẹ́ sómi o! Bẹ́ẹ̀ ló rí pẹ̀lú ẹni tí Ọlọ́run ti gbà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ wá jó rẹ̀yìn, ìgbàlà lè bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ àwọn Kristẹni tó ti ní ìgbàlà pé kí wọ́n “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.” (Júúdà 3) Ó tún kìlọ̀ fún àwọn tó ti rígbàlà pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”​—Fílípì 2:12.

Ṣé Ọlọ́run ni Olùgbàlà àbí Jésù?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ni orísun ìgbàlà, ìdí nìyẹn tó fi sábà máa ń pè é ní “Olùgbàlà.” (1 Sámúẹ́lì 10:19; Aísáyà 43:11; Títù 2:10; Júúdà 25) Yàtọ̀ síyẹn, onírúurú èèyàn ni Ọlọ́rùn lò láti gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì sílẹ̀, “olùgbàlà” sì ni Bíbélì pe àwọn náà. (Nehemáyà 9:27; Àwọn Onídàájọ́ 3:9, 15; 2 Àwọn Ọba 13:5) b Bákan náà, Bíbélì pe Jésù ní “Olùgbàlà” torí pé ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ni Ọlọ́run fi gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.​—Ìṣe 5:31; Títù 1:4. c

Ṣe gbogbo èèyàn ló máa rí ìgbàlà

 Rárá o, àwọn kan ò ní rígbàlà. (2 Tẹsalóníkà 1:9) Nígbà tí ẹnì kan bi Jésù pé, “Díẹ̀ ha ni àwọn tí a ó gbà là?” èsì tó fún un ni pé: “Ẹ tiraka tokuntokun láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé, nítorí, mo sọ fún yín, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò wá ọ̀nà láti wọlé ṣùgbọ́n wọn kì yóò lè ṣe bẹ́ẹ̀.”​—Lúùkù 13:23, 24.

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa ìgbàlà aráyé

 Èrò tí kò tọ́: Kọ́ríńtì Kìíní orí 15 ẹsẹ 22 fi kọ́ni pé gbogbo èèyàn ló máa rígbàlà torí ó sọ pé “a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.”

 Òótọ́: Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú àtàwọn tó tẹ̀ lé e fi hàn pé ọ̀rọ̀ àjíǹde ni ibí yìí dá lé. (1 Kọ́ríńtì 15:12, 13, 20, 21, 35) Torí náà, ohun tí gbólóhùn náà, “a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi” túmọ̀ sí ni pé ipasẹ̀ Jésù ni gbogbo àwọn tó bá máa jíǹde á fi rí ìbùkún yìí gbà.​—Jòhánù 11:25.

 Èrò tí kò tọ́: Títù 2:11 fi kọ́ni pé gbogbo èèyàn ló máa rígbàlà torí ó sọ pé Ọlọ́run máa gba “gbogbo ènìyàn” là.​—Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

 Òótọ́: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “gbogbo” nínú ẹsẹ yìí tún lè túmọ̀ sí “oríṣiríṣi tàbí onírúurú.” d Torí náà, ohun tí ìwé Títù 2:11 ń sọ ni pé Ọlọ́run máa gba onírúurú èèyàn là, títí kan àwọn èèyàn “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.”​—Ìṣípayá 7:9, 10.

 Èrò tí kò tọ́: Pétérù Kejì orí 3 ẹsẹ 9 fi kọ́ni pé gbogbo èèyàn ló máa rígbàlà torí ó sọ pé Ọlọ́run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.”

 Òótọ́: Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn rígbàlà, àmọ́ kì í fipá mú wọn láti ṣe ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè rígbàlà. Ní “ọjọ́ ìdájọ́” rẹ̀, “ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” máa wáyé.​—2 Pétérù 3:7.

a Bíbélì máa ń sọ pé ‘a ti gba ẹnì kan là’ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà tó máa rí ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú pátápátá ò tíì dé.​—Éfésù 2:5; Róòmù 13:11.

b Nínú àwọn ẹsẹ yìí, àwọn Bíbélì kan lo àwọn ọ̀rọ̀ míì dípò “olùgbàlà,” bíi “olùdáǹdè,” “akọgun,” “aṣáájú,” òmíràn tiẹ̀ lo “ẹnì kan.” Àmọ́, nínú èdè tí wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ kan náà tí wọ́n lò fún àwọn èèyàn yìí ni wọ́n lò láwọn ibòmíì tí Bíbélì ti pé Jèhófà Ọlọ́run ní Olùgbàlà.​—Sáàmù 7:10.

c Inú orúkọ Hébérù náà, Yehoh·shuʹaʽ, ni orúkọ náà, Jésù ti wá. Ohun tó túmọ̀ sí ni “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”

d Wo ìwé náà, Vine’s Complete Expository Dictionary of Old and New Testament Words. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà ni wọ́n lò nínú Mátíù 5:11, tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jésù sọ pé àwọn èèyàn máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú “lóríṣìíríṣìí” sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.​—Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.