Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 1:1-12

  • Ìkíni (1, 2)

  • Ìgbàgbọ́ àwọn ará Tẹsalóníkà ń lágbára sí i (3-5)

  • Ẹ̀san lórí àwọn aláìgbọràn (6-10)

  • Àdúrà fún ìjọ (11, 12)

1  Pọ́ọ̀lù, Sílífánù* àti Tímótì,+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa:  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Olúwa.  Ẹ̀yin ará, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín. Ó yẹ bẹ́ẹ̀, torí pé ìgbàgbọ́ yín ń lágbára sí i, ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i.+  Nítorí èyí, à ń fi yín yangàn+ láàárín ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro* tí ẹ̀ ń dojú kọ.*+  Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, tó ń mú kí a kà yín yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run tí ẹ̀ ń torí rẹ̀ jìyà.+  Èyí jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run kà á sí òdodo láti san ìpọ́njú pa dà fún àwọn tó ń pọ́n yín lójú.+  Àmọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ní ìpọ́njú máa rí ìtura gbà pẹ̀lú wa nígbà ìfihàn Jésù Olúwa+ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára+  nínú iná tó ń jó fòfò, bó ṣe ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.+  Àwọn yìí máa fara gbá ìyà ìdájọ́ ìparun ayérayé+ láti iwájú Olúwa àti látinú ògo agbára rẹ̀, 10  nígbà tó bá dé kí a lè yìn ín lógo pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́ sì lè wò ó ní ọjọ́ yẹn tìyanutìyanu, nítorí ẹ gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún yín gbọ́. 11  Torí bẹ́ẹ̀, à ń gbàdúrà fún yín nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run wa kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀,+ kó sì fi agbára rẹ̀ ṣe gbogbo ohun rere tó wù ú láṣepé pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́. 12  Kí a lè yin orúkọ Olúwa wa Jésù lógo nínú yín, kí a sì yin ẹ̀yin náà lógo nínú rẹ̀, nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa àti ti Jésù Kristi Olúwa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.
Tàbí “àwọn ìpọ́njú.”
Tàbí “fara dà.”