Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Lílo Ère Nínú Ìjọsìn?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Lílo Ère Nínú Ìjọsìn?

 Iléeṣẹ́ agbéròyìnjáde ti àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sọ pé, níbi ayẹyẹ kan tí wọ́n ṣe ní St. Peter’s Basilica ní March 25, 2022, ṣe ni Póòpù Francis dúró níwájú ère Màríà, “ó dijú, ó sì tẹríba bó ṣe ń gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí i.” Ó “bẹ Màríà” pé kó jẹ́ kí àlàáfíà wà. Iléeṣẹ́ agbéròyìnjáde kan tí wọ́n ń pè ní Vatican News fi kún un pé “Póòpù náà gba àdúrà sí Ọkàn Mímọ́ Màríà kó lè ya àwọn èèyàn sí mímọ́, pàápàá àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Ukraine.”

 Kí lèrò tiẹ̀? Ṣé ó yẹ ká máa gbàdúrà sí ère tàbí ká máa lo ère nínú ìjọsìn wa? Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ:

  •   “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀. O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ láti sìn wọ́n, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo.”​—Ẹ́kísódù 20:​4, 5. a

  •   “Àwọn òrìṣà wọn jẹ́ fàdákà àti wúrà, Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn. Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran; wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn; wọ́n ní imú, àmọ́ wọn ò lè gbóòórùn; wọ́n ní ọwọ́, àmọ́ wọn ò lè fọwọ́ ba nǹkan; wọ́n ní ẹsẹ̀, àmọ́ wọn ò lè rìn; wọn ò lè mú ìró kankan jáde láti ọ̀fun wọn. Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.”​—Sáàmù 115:​4-8.

  •   “Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn; Èmi kì í bá ẹnì kankan pín ògo mi, Èmi kì í sì í fi ìyìn mi fún àwọn ère gbígbẹ́.”​—Àìsáyà 42:​8, àlàyé ìsàlẹ̀.

  •   “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.”​—1 Kọ́ríńtì 10:14.

  •   “Ẹ máa yẹra fún àwọn òrìṣà.”​—1 Jòhánù 5:21.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ tó bá dọ̀rọ̀ lílo ère nínú ìjọsìn, ka àpilẹ̀kọ náà “Ojú Ìwòye Bíbélì​—Ère” tàbí kó o wo fídíò náà Ṣé Ọlọ́run Fẹ́ Ká Máa Lo Ère Nínú Ìjọsìn?

 O tún lè ka ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn kókó yìí:

Ibi Tí A Ti Mú Àwòrán: Vincenzo Pinto/AFP via Getty Images

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?