Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ère

Ère

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn máa ń lo ère nínú ìjọsìn wọn. Ṣé Bíbélì fọwọ́ sí irú àṣà bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba irú ìjọsìn yìí?

Ǹjẹ́ àwọn Júù olóòótọ́ tó gbáyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì lo ère nínú ìjọsìn wọn?

“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n.”​—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ lédè ­Hébérù tàwọn èèyàn ń pè ní ­Májẹ̀mú Láéláé, dẹ́bi fún lílo ère nínú ìjọsìn

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia sọ pé, àwọn Júù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ère àti àwòrán tí “wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún tí wọ́n sì máa ń júbà” nínú ìjọsìn wọn.” a Ohun tí ìwé náà fà yọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ni àwọn àwòrán èso, òdòdó àti àwọn ẹranko tí wọ́n gbẹ́ sára tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù.​—1 Àwọn Ọba 6:​18; 7:​36.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn Júù yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ìwé yìí sọ. Àwọn Júù olóòótọ́ kì í júbà àwọn àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára tẹ́ńpìlì. Kódà, kò sí ibi kankan nínú Bíbélì tí ọmọ Ísírẹ́lì tó ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run ti lo ère nínú ìjọsìn rẹ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlí ì Aísáyà sọ pé: “Èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”​—Aísáyà 42:8.

Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lo ère nínú ìjọsìn wọn?

‘Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà? . . . Ẹ jáwọ́ nínú ­fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’​—2 Kọ́ríńtì 6:​16, 17.

Ìwé náà, “History of the Christian Church” sọ pé: “Àwọn Kristẹni ìjímìjí ì bá ti yarí kanlẹ̀ tí wọ́n bá kàn tiẹ̀ dámọ̀ràn gbígbé ère sínú ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì máa ka títẹríba tàbí gbígbàdúrà níwájú àwọn ère náà sí ìbọ̀rìṣà”

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Kì í ṣe tuntun pé àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ lo ère nínú ìjọsìn wọn, torí náà kì í ṣe ìsinsìnyí ló yẹ ká ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá ṣàríwísí wọn. Wọ́n fi àwọn oríṣiríṣi ère dárà sára àwọn ibojì abẹ́lẹ̀ tí wọ́n sin àwọn Kristẹni yìí sí . . . . Kódà, wọ́n tún fi àwòrán àwọn akọni inú àwọn ìtàn àròsọ dárà sí àwọn ilé ìjọsìn mímọ́ àti àwọn ibi ìsìnkú.” b

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta ni wọ́n ṣe èyí tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ nínú àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ sínú àwọn ibojì abẹ́lẹ̀ yìí. Èyí sì jẹ́ igba [200] ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú. Torí náà, ọ̀nà ìjọsìn tí ìwé New Catholic Encyclopedia pè ní ọ̀nà ìjọsìn “àwọn Kristẹni ayé àtijọ́” kì í ṣe ọ̀nà ìjọsìn tí àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi gangan ń tẹ̀ lé ní àtètèkọ́ṣe,  tó sì wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì táwọn èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Àwọn ère tí wọ́n bá nínú ibojì yìí fi hàn pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta, àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ti mú àṣà àwọn abọ̀rìṣà, ìyẹn lílo ère, wọnú ìjọsìn. Ó jọ pé kí wọ́n lè fa ojú àwọn abọ̀rìṣà yẹn mọ́ra ni wọ́n ṣe dọ́gbọ́n ki àṣà náà bọnú ìjọsìn. c

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.”​—1 Kọ́ríńtì 10:14.

Ṣé ó yẹ́ ká máa lo ère nínú ìjọsìn wa?

“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn ­òrìṣà.”​—1 Jòhánù 5:​21.

Bíbélì dẹ́bi fún lílo ère nínú ìjọsìn. Torí èyí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í júbà àwọn ère, bákan náà, a kì í gbé àwọn ère ìsìn sínú ilé wa tàbí sínú àwọn ilé ìjọsìn wa

AOHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ìwé náà, New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé téèyàn bá ń jọ́sìn ère ẹnì kan, ẹni náà gan-an léèyàn ń jọ́sìn, fún ìdí yìí, téèyàn bá fẹ́ jọ́sìn ẹnì kan, kò sí ohun tó burú nínú jíjọ́sìn ère ẹni náà torí pé òun ni ère yẹn dúró fún.”

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa lo ère nígbà tó kọ́ wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà. Síwájú sí i, Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gírí ìkì kò tiẹ̀ sọ ohun tó jẹ mọ́ lílo ère láti jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”​—Mátíù 4:10.

a Ìwé New Catholic Encyclopedia túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà júbà sí “ohun tó jẹ́ apá kan ìjọsìn.”

b Ère lè tọ́ka sí àwòrán, ṣìgìdì tàbí àmì èyíkéyìí tí wọ́n bá ń lò nínú ìjọsìn.

c Àṣà lílo ère wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn ilẹ̀ ayé àtijọ́ títí kan ilẹ̀ Íjíbítì, Gíríìsì àti Íńdíà.