Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Àwọn Sẹ́ẹ̀lì Ayára Ṣiṣẹ́ Tó Wà Nínú Ọpọlọ Eéṣú

Àwọn Sẹ́ẹ̀lì Ayára Ṣiṣẹ́ Tó Wà Nínú Ọpọlọ Eéṣú

WỌN eéṣú máa ń sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọ́n bá ń ṣí lọ. Wọ́n lè tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800,000] ní àyè tí ò ju yàrá kékeré kan lọ. Síbẹ̀, wọn kì í rọ́ lu ara wọn. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe fún wọn?

Rò Ó Wò Ná: Àwọn eéṣú máa ń ní ojú gbàǹgbà méjì, ní ẹ̀yìn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ojú yìí ni sẹ́ẹ̀lì ayára ṣiṣẹ́ kan wà táwọn òyìnbó ń pè ní lobula giant movement detector (LGMD). Nígbà tí eéṣú kan bá fẹ́ kọlu òmíràn, sẹ́ẹ̀lì yìí á ti fura, á sì yára gbé ìsọfúnni lọ sí ìyẹ́ àti ẹsẹ̀ eéṣú náà, èyí á mú kó tètè yà bàrá kó máa bàa kọlu àwọn tó kù. Kódà, ìlọ́po márùn-ún ni àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí fi yára ju àkókò téèyàn fi máa ṣẹ́jú lásán.

Nígbà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kíyèsí bí sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe ń ṣiṣẹ́, èyí mú kí wọ́n ṣe ètò kọ̀ǹpútà kan sínú àwọn rọ́bọ́ọ̀tì kan. Ètò yìí máa ń jẹ́ kí àwọn rọ́bọ́ọ̀tì náà tètè fura tí ohun kan bá fẹ́ kọlù wọ́n láì ṣẹ̀ṣẹ̀ lo àwọn ẹ̀rọ tó díjú irú bí radar àti infrared tó máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ nínú afẹ́fẹ́. Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ tí ń lo irú ọgbọ́n yìí láti dín ìjàǹbá ọkọ̀ kù ní ti pé, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ kan sínú ọkọ̀ tó máa tètè ta ẹni tó ń wakọ̀ lólobó tí ó bá fẹ́ kọlu ọkọ̀ míì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Shigang Yue ní yunifásítì ìlú Lincoln, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ lára àwọn kòkòrò tíntínní bí eéṣú.”

Kí Lèrò Rẹ? Ṣé àwọn sẹ́ẹ̀lì ayára ṣiṣẹ́ tó wà nínú ọpọlọ eéṣú kàn ṣàdédé wà bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?