Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìsẹ̀lẹ̀ ní Ọjọ́ Olúwa

Àwọn Ìsẹ̀lẹ̀ ní Ọjọ́ Olúwa

Orí 18

Àwọn Ìsẹ̀lẹ̀ ní Ọjọ́ Olúwa

1, 2. (a) Báwo ni yíyè ìsẹ̀lẹ̀ bíburú jáì kan bọ́ ṣe máa ń rí? (b) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ohun tó rí nígbà tí Jésù ṣí èdìdì kẹfà?

 ǸJẸ́ o ti yè bọ́ nínú ìsẹ̀lẹ̀ bíburú jáì kan rí? Ìrírí burúkú gbáà ni. Mìmì ńlá kan lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kí ilẹ̀ máa mì jìgìjìgì tòun ti ariwo ìrọ́kẹ̀kẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ibi tó o ti ń sá kìjokìjo káàkiri láti wá abẹ́ tábìlì kan forí pa mọ́ sí ni wàá ti rí i pé ńṣe ni ìmìjìgìjìgì tó dà pọ̀ mọ́ ariwo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ náà tún wá ń burú sí i. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ pé ṣàdédé ni wàá gbúròó ariwo ìrọ́kẹ̀kẹ̀, tó máa le débi pé igbá á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣubú làwo, táwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé á máa dà lura, táwọn ilé á sì máa dà wó. Àdánù kékeré kọ́ nirú ẹ̀ máa ń fà, kódà, ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ tí kì í kúrò lára bọ̀rọ̀, tó ń ṣọṣẹ́ tiẹ̀ náà, a tún máa dá kún àgbákò náà.

2 Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, kíyè sí bí Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ohun tó rí nígbà tí Jésù ṣí èdìdì kẹfà: “Mo sì rí nígbà tí ó ṣí èdìdì kẹfà, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá sì sẹ̀.” (Ìṣípayá 6:12a) Ó ní láti jẹ́ pé ìgbà kan náà tí Jésù ṣí àwọn èdìdì yòókù ló ṣí èdìdì kẹfà yìí náà. Ìgbà wo gẹ́lẹ́, ní ọjọ́ Olúwa, ni ìsẹ̀lẹ̀ yìí sẹ̀, irú ìsẹ̀lẹ̀ wo sì ni?—Ìṣípayá 1:10.

3. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jésù sọ pé yóò wáyé nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀? (b) Báwo làwọn ìsẹ̀lẹ̀ gidi ṣe tan mọ́ ìsẹ̀lẹ̀ ńlá ìṣàpẹẹrẹ tí Ìṣípayá 6:12 sọ̀rọ̀ rẹ̀?

3 Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ìsẹ̀lẹ̀ gidi àti ìsẹ̀lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láwọn ibi mélòó kan. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì tí Jésù sọ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ nínú agbára Ìjọba, ó wí pé “ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ apá kan “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” Láti ọdún 1914 wá táwọn èèyàn tó wà láyé ti ń gbèrú rẹ́kẹrẹ̀kẹ ní ọ̀kẹ́ àìmọye ilẹ̀ mímì gidi ti dá kún àwọn ìdààmú àkókò wa lọ́pọ̀lọpọ̀. (Mátíù 24:3, 7, 8) Àmọ́ ṣá o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsẹ̀lẹ̀ náà mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, àjálù tó ṣeé fi ojúyòójú rí ni wọ́n. Àwọn ló ṣáájú ìsẹ̀lẹ̀ ńlá ìṣàpẹẹrẹ tí Ìṣípayá 6:12 sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìyẹn gan-an sì ni ìsẹ̀lẹ̀ tó ju ìsẹ̀lẹ̀ lọ tó máa jẹ́ paríparì òpin gbogbo ìgbọ̀nrìrì tó ti kọ́kọ́ mi ètò Sátánì táwọn èèyàn ń darí lórí ilẹ̀ ayé jìgìjìgì dé ìpìlẹ̀ rẹ̀. a

Ìmìtìtì Láwùjọ Ẹ̀dá Èèyàn

4. (a) Látìgbà wo làwọn èèyàn Jèhófà ti ń fojú sọ́nà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alájàálù yóò bẹ̀rẹ̀ ní 1914? (b) Òpin àkókò wo ni 1914 yóò sàmì sí?

4 Láti nǹkan bí ọdún 1875, àwọn èèyàn Jèhófà ti ń fojú sọ́nà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alájàálù yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 àti pé wọn yóò sàmì sí òpin Àwọn Àkókò Kèfèrí. Èyí ni sáà “ìgbà méje” (ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rin [2,520] ọdún) tó bẹ̀rẹ̀ látìgbà ìbìṣubú ìjọba ìlà ìdílé Dáfídì ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni títí dé ìgbà tá a gbé Jésù gorí ìtẹ́ ní Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run lọ́dún 1914 Sànmánì Kristẹni.—Dáníẹ́lì 4:24, 25; Lúùkù 21:24, Bibeli Mimọ. b

5. (a) Ìkéde wo ni C. T. Russell ṣe ní October 2, ọdún 1914? (b) Àwọn rúkèrúdò wo ló ti ń wáyé lágbo ìṣèlú látọdún 1914?

5 Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé nígbà tí C. T. Russell ń darí ìjọsìn òwúrọ̀ pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, New York, ní òwúrọ̀ October 2, ọdún 1914, ó sọ lọ́nà tó wọni lọ́kàn pé: “Àwọn Àkókò Kèfèrí ti dópin; àwọn ọba wọn ti lo ọjọ́ wọn kọjá.” Ní tòótọ́, rúkèrúdò kárí ayé tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 délé dóko tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́balọ́ba tó ti wà tipẹ́ ló di àfẹ́kù. Àtúntò táwọn Bolshevik ṣe lọ́dún 1917 bi ipò olú ọba apàṣẹwàá ṣubú, ìyẹn ló sì tanná ran ìfagagbága tó wà pẹ́ láàárín ètò ìjọba Marx àti ti ìjọba oníṣòwò bòńbàtà. Àwọn rúkèrúdò tó ń mú àyípadà dé bá ètò ìṣèlú ṣì ń bá a lọ láti máa yọ àwùjọ ẹ̀dá èèyàn lẹ́nu níbi gbogbo kárí ayé. Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọba kì í ṣàkóso ju ọdún kan tàbí méjì lọ. Àpẹẹrẹ irú àìfẹsẹ̀múlẹ̀ ètò ìṣèlú yìí la lè rí nínú ọ̀ràn ti orílẹ̀-èdè Ítálì, tó ní ìjọba tuntun mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] láàárín ọdún méjìlélógójì [42] péré lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Àmọ́ ṣá o, kékeré ni irú rúkèrúdò tó délé dóko yìí jẹ́ lójú pabanbarì mìmì tó ń bọ̀ wá mi ètò ìjọba èèyàn. Kí wá ló máa yọrí si? Ìjọba Ọlọ́run á gba gbogbo agbára ìṣàkóso orí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 9:6, 7.

6. (a) Báwo ni H. G. Wells ṣe ṣàpèjúwe sànmánì tuntun tó sì tún ṣe pàtàkì náà? (b) Kí ni ọ̀mọ̀ràn kan àti òṣèlú kan kọ nípa sànmánì tó bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914?

6 Àwọn òpìtàn, àwọn ọ̀mọ̀ràn, àtàwọn aṣáájú òṣèlú ti sọ pé ọdún 1914 jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun kan tó jẹ́ mánigbàgbé. Lọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] lẹ́yìn tí sànmánì yẹn bẹ̀rẹ̀, òpìtàn H. G. Wells sọ pé: “Kò sí wòlíì tí inú rẹ̀ kò ní dùn láti sọ ohun tó dùn-ún gbọ́ létí. Àmọ́, ó di dandan kó sọ ohun tó bá rí. Ó rí ayé kan tí àwọn ọmọ ogun, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn, àwọn ayánilówó èlé, àtàwọn tí ń wá owó òjijì jẹ gàba lé; ayé kan táwọn èèyàn ti ń fura tí wọ́n sì ń kórìíra ọmọnìkejì wọn, níbi táwọn èèyàn ti ń yára di ẹni àmúsìn, tí ọlọ́rọ̀ ò ti rí ti òtòṣì rò, tí onílé àti àlejò ti ń gbéjà ko ara wọn, tóníkálukú sì ń múra ogun.” Lọ́dún 1953, ọ̀mọ̀ràn Bertrand Russell kọ̀wé pé: “Látọdún 1914, gbogbo ẹni tó ń kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ayé ni ìdààmú ńláǹlà ti bá. Ohun tó sì fa èyí ni bó ṣe dà bíi pé ohun kan tí kò ṣeé yí padà ń ti ayé yìí lọ sínú ìjábá tó ju ìjábá lọ. . . . Lójú wọn, ìran èèyàn rí bí akọni kan nínú eré oníjàǹbá tí wọ́n máa ń ṣe nílẹ̀ Gíríìsì. Nínú eré náà, àwọn ọlọ́run tí inú ń bí máa ń ti akọni yẹn gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tí kò sì ní lè rí ohunkóhun ṣe láti já ara rẹ̀ gbà títí tí wọ́n á fi tì í pa.” Lọ́dún 1980, nígbà tí aṣáájú òṣèlú náà Harold Macmillan, ń ronú lórí bí ọ̀rúndún ogún ṣe bẹ̀rẹ̀ láìsí ìjà láìsí ìta, ó wí pé: “Èrò àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bí mi ni pé ohun gbogbo yóò túbọ̀ máa dára sí i. . . . Àmọ́, lówùúrọ̀ ọjọ́ kan lọ́dún 1914, ṣe ni ohun gbogbo kàn dédé dà rú láìròtẹ́lẹ̀.”

7-9. (a) Rúkèrúdò wo ló ti ń mi àwùjọ ẹ̀dá èèyàn látọdún 1914? (b) Kí ló ṣì ń bọ̀ wá jẹ́ ara àwọn rúkèrúdò nínú àwùjọ ẹ̀dá èèyàn lákòókò wíwàníhìn-ín Jésù?

7 Aráyé tún kàgbákò rúkèrúdò míì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àwọn ogun kéékèèké mìíràn àti ìpániláyà kárí ayé ṣì ń bá a lọ láti máa mi ilẹ̀ ayé. Ẹ̀rù àwọn apániláyà tàbí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń lo àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn.

8 Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan míì tó yàtọ̀ sí ogun, ti mi àwùjọ ẹ̀dá èèyàn dé ìpìlẹ̀ rẹ̀ láti ọdún 1914. Ọjà okòwò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó fọ́ ní October 29, ọdún 1929 tún tanná ran ọkàn lára rúkèrúdò tó tíì kó ìpayà báni jù lọ. Èyí mú Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé wá, èyí tó kan gbogbo orílẹ̀-èdè oníṣòwò bòńbàtà. Àárín ọdún 1932 àti ọdún 1934 ni ìlọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé náà rọjú jù lọ, àmọ́ ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ ò tíì tán títí di báyìí. Látọdún 1929 làwọn alákòóso ti ń gbìyànjú láti fi oríṣiríṣi ìwéwèé ṣàtúnṣe ètò ọrọ̀ ajé ayé, èyí tó ń ṣe ségesège. Ńṣe làwọn ìjọba ń jẹ gbèsè nítorí àtigbọ́ bùkátà. Ìṣòro tó wáyé lórí epo rọ̀bì lọ́dún 1973 àti ọjà okòwò tó fọ́ lọ́dún 1987 ti dá kún mìmì tó mì wọ́n lágbo ọ̀ràn ìnáwó. Ní báyìí ná, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń rajà láwìn. Àìmọye èèyàn ni ọgbọ́n màdàrú ní ti ọ̀ràn ìnáwó, ìwéwèé ìṣòwò jẹ-kí-n-jẹ, àrékérekè tẹ́tẹ́ lọ́tìrì àti tẹ́tẹ́ títa mìíràn ti pa ládàánù, ọ̀pọ̀ lára wọn sì làwọn ìjọba tó yẹ kí wọ́n máa dáàbò bo àwọn èèyàn ń ṣonígbọ̀wọ́ fún. Kódà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n jẹ́ ajíhìnrere lórí tẹlifíṣọ̀n ń rọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye dọ́là tó jẹ́ ìpín tiwọn lára ẹ̀ sápò!—Fi wé Jeremáyà 5:26-31.

9 Kọ́rọ̀ tó dà báyìí, wàhálà tó bá ọrọ̀ ajé ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Mussolini àti Hitler láti fipá gba ìjọba. Lọ́gán ni Bábílónì Ńlá ti yáa wá ojú rere wọn, Ìjọba Póòpù sì wọnú àdéhùn ìmùlẹ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ítálì lọ́dún 1929 àti pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 1933. (Ìṣípayá 17:5) Dájúdájú, àwọn àkókò ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó tẹ̀ lé e jẹ́ apá kan ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù pé lára àwọn nǹkan tó máa sàmì sí wíwàníhìn-ín òun ni “làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde . . . nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Lúùkù 21:7-9, 25-31) c Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìmìtìtì tó bẹ̀rẹ̀ láti máa mi àwùjọ ẹ̀dá èèyàn látọdún 1914 ò tíì dáwọ́ dúró o, kékeré sì kọ́ ní ìpayà tí wọ́n ń dá sílẹ̀.

Mímì Tó Lọ́wọ́ Jèhófà Nínú

10. (a) Kí ló fà á tí rúkèrúdò fi pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ọ̀ràn ẹ̀dá? (b) Kí ni Jèhófà ń ṣe, kí ló sì ń fi múra sílẹ̀ fún?

10 Ohun tó fa rúkèrúdò bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn ẹ̀dá ni pé èèyàn ò kúnjú ìwọ̀n láti máa darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. (Jeremáyà 10:23) Láfikún sí ìyẹn, ejò ògbólógbòó nì, Sátánì, “tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” ń fi ojú aráyé rí màbo bó ti ń ṣe gbogbo ohun tó wà ní agbára rẹ̀ láti yí aráyé padà kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà. Ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní ti mú kí ayé lu jára tó fi wá dà bí àdúgbò kan ṣoṣo, níbi tí ìkórìíra nítorí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè àti ti ẹ̀yà ẹni ti ń mi àwùjọ ẹ̀dá èèyàn látòkèdélẹ̀, àjọ tí wọ́n sì pè ní ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò tíì lè yanjú ìṣòro náà kúrò nílẹ̀. Kò tíì sí ìgbà tí èèyàn ń jọba lórí èèyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀ tó ti ìgbà yìí. (Ìṣípayá 12:9, 12; Oníwàásù 8:9) Láìka ìyẹn sí, ó ti lé ní àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí tí mìmì tó lọ́wọ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé nínú, ti ń mì, bó ti ń múra sílẹ̀ láti yanjú àwọn ìṣòro náà títí láé fáàbàdà. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

11. (a) Ìmìjìgìjìgì wo la ṣàpèjúwe nínú Hágáì 2:6, 7? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ní ìmúṣẹ?

11 Nínú Hágáì 2:6, 7 a kà pé: “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i—láìpẹ́—èmi yóò sì mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì. Dájúdájú, èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” Látọdún 1919 wá ni Jèhófà ti mú káwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ máa pòkìkí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ láàárín gbogbo aráyé pátá. Wọ́n ti fi ìkìlọ̀ tó kárí ayé yìí ki ayé Sátánì nílọ̀. d Bí ìkìlọ̀ náà ti ń gbóná janjan sí i, àwọn èèyàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra,” ti gbára dì láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè. Kì í ṣe ìmìtìtì inú ètò Sátánì ló gbọ̀n wọ́n síta o. Àmọ́, bí wọ́n ṣe ń fòye mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí, àwọn fúnra wọn ń pinnu láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù kí wọ́n lè máa fògo kún ilé ìjọsìn Jèhófà. Báwo lèyí ṣe ń ṣẹlẹ̀? Nípasẹ̀ iṣẹ́ onítara ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni. (Mátíù 24:14) Ìjọba yìí, èyí tí Jésù àti àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ para pọ̀ jẹ́, yóò máa wà títí lọ gbére fún ògo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “ìjọba kan tí kò ṣeé mì.”—Hébérù 12:26-29.

12. Bó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ìwàásù tá a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Mátíù 24:14, kí ló yẹ kó o ṣe ṣáájú ìsẹ̀lẹ̀ ńlá ti Ìṣípayá 6:12?

12 Ṣé ìwọ náà ti di ọ̀kan lára àwọn tó ń gbọ́ ìwàásù yẹn? Àbí o wà lára ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù tó pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Jésù láwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, máa tẹ̀ síwájú láti máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì. (2 Tímótì 2:15; 3:16, 17) Jáwọ́ pátápátá kúrò nínú ẹgbẹ́ àwùjọ Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé tó ń dúró dé ìparun! Máa bọ̀ ní tààràtà, kó o wá dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ayé tuntun, kó o sì máa kópa ní kíkún nínú ìgbòkègbodò wọn ṣáájú kí “ìsẹ̀lẹ̀” àjálù ìkẹyìn tóó fọ́ gbogbo ayé Sátánì yángá. Ṣùgbọ́n kí ni ìsẹ̀lẹ̀ ńlá yẹn? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

Ìsẹ̀lẹ̀ Ńlá Náà!

13. Lọ́nà wo ni ìsẹ̀lẹ̀ ńlá náà gbà jẹ́ tuntun téèyàn ò rí rí?

13 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko yìí jẹ́ àkókò àwọn ìsẹ̀lẹ̀—ní ti gidi àti lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (2 Tímótì 3:1) Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀ yìí tó jẹ́ mímì ńlá ìkẹyìn tí Jòhánù rí nígbà tí Jésù ṣí èdìdì kẹfà. Àkókò fún àwọn ìmìtìtì délé dóko ti dópin. Ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan tó jẹ́ tuntun, téèyàn ò tíì rí rí ti wá dé nísinsìnyí. Ìsẹ̀lẹ̀ náà tóbi púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tá ò fi lè fi òṣùwọ̀n Richter (tí wọ́n fi ń mọ bí ìsẹ̀lẹ̀ ti pọ̀ tó) tàbí ohun èlò ìdíwọ̀n èyíkéyìí mìíràn tó jẹ́ tèèyàn wọn ìrugùdù àti ìmìjìgìjìgì tó bá a rìn. Èyí kọjá ìmìtìtì lásánlàsàn kan tí ń ṣẹlẹ̀ ládùúgbò, mímì kan tí ń sọ òkè dilẹ̀ ni, èyí tí yóò pa gbogbo “ilẹ̀ ayé” ìyẹn gbogbo àwùjọ ẹ̀dá èèyàn oníwà ìbàjẹ́, run pátápátá.

14. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló sọ nípa ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan àtàwọn àbájáde rẹ̀? (b) Kí ló dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì àti ti Ìṣípayá 6:12, 13 ń tọ́ka sí?

14 A rí àwọn míì lára àwọn wòlíì Jèhófà tí wọ́n ti sọ nípa irú ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ àti àjálù tó máa bá a rìn. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọdún 820 ṣááju Sànmánì Kristẹni, Jóẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ‘dídé ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikúnfún-ẹ̀rù ti Jèhófà,’ ó tún sọ pé nígbà náà “a óò yí oòrùn padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kún un: “Ogunlọ́gọ̀, ogunlọ́gọ̀ wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu. Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn dájúdájú, gbogbo àwọn ìràwọ̀ yóò sì fawọ́ mímọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn dájúdájú. Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì ké ramúramù láti Síónì, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerúsálẹ́mù. Dájúdájú, ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àti odi agbára fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Jóẹ́lì 2:31; 3:14-16) Ìmìjìgìjìgì yìí lè ní í ṣe pẹ̀lú kìkì ìmúṣẹ ìdájọ́ Jèhófà nígbà ìpọ́njú ńlá. (Mátíù 24:21) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí ìròyìn tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ẹ̀ nínú Ìṣípayá 6:12, 13 ní ìtumọ̀ kan náà.—Tún wo Jeremáyà 10:10; Sefanáyà 1:14, 15.

15. Mímì délé dóko wo ni wòlíì Hábákúkù sọ tẹ́lẹ̀?

15 Ní nǹkan bí igba [200] ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Jóẹ́lì, wòlíì Hábákúkù sọ nínú àdúrà sí Ọlọ́run rẹ̀ pé: “Jèhófà, mo ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ. Jèhófà, mo ti fòyà ìgbòkègbodò rẹ. Ní àárín àwọn ọdún, mú un wá sì ìyè! Ní àárín àwọn ọdún, kí o sọ ọ́ di mímọ̀. Nígbà ṣìbáṣìbo, kí o rántí láti fi àánú hàn.” Kí ni “ṣìbáṣìbo” yẹn yóò jẹ́? Hábákúkù ń bá a lọ láti fúnni ní àpèjúwe kan tó ṣe kedere nípa ìpọ́njú ńlá, ó sọ nípa Jèhófà pé: “Ó dúró jẹ́ẹ́, kí ó bàa lè gbọn ilẹ̀ ayé jìgìjìgì. Ó wò, ó sì wá mú kí àwọn orílẹ̀-èdè fò sókè. . . . Ìdálẹ́bi ni o fi la ilẹ̀ ayé kọjá. Tìbínútìbínú ni o fi pa àwọn orílẹ̀-èdè bí ọkà. Síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Hábákúkù 3:1, 2, 6, 12, 18) Ẹ wo mímì délé dóko tí yóò tọwọ́ Jèhófà ṣẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé nígbà tó bá pa àwọn orílẹ̀-èdè bí ẹní pa ọkà!

16. (a) Kí ni wòlíì Ísíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí Sátánì yóò gbé ìjà rẹ̀ tó kẹ́yìn ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Kí ni àbáyọrí ìsẹ̀lẹ̀ tí Ìṣípayá 6:12 sọ nípa rẹ̀?

16 Ìsíkíẹ́lì pẹ̀lú sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù (Sátánì tí a rẹ̀ nípò sílẹ̀) bá gbé ìjà rẹ̀ tó kẹ́yìn ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, Jèhófà yóò mú kí “ìmìtìtì ńláǹlà” ṣẹlẹ̀ “ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.” (Ìsíkíẹ́lì 38:18, 19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsẹ̀lẹ̀ gidi lè wà nínú ẹ̀, ó yẹ ká rántí pé Ìṣípayá la fi hàn nípa àwọn àmì. Èdè ìṣàpẹẹrẹ pọ̀ gan-an nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tá a tọ́ka sí. Fún ìdí yìí, ńṣe ló dà bíi pe ṣíṣí èdìdì kẹfà ń fi àṣekágbá gbogbo mími ètò àwọn nǹkan ilẹ̀ ayé yìí hàn—ìsẹ̀lẹ̀ ńlá náà, nínú èyí tí Jèhófà Ọlọ́run á pa gbogbo èèyàn tó bá ta ko ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ run.

Àkókò Òkùnkùn

17. Ipa wo ni ìsẹ̀lẹ̀ ńlá náà ní lórí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀?

17 Bí Jòhánù ṣe ń bá a lọ láti fi hàn wá, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbani lẹ́rù tó kan ọ̀run pàápàá bá ìsẹ̀lẹ̀ ńlá náà rìn. Ó wí pé: “Oòrùn sì di dúdú bí aṣọ àpò [ìdọ̀họ] tí a fi irun ṣe, òṣùpá sì dà bí ẹ̀jẹ̀ látòkè délẹ̀, àwọn ìràwọ̀ ọ̀run sì jábọ́ sí ilẹ̀ ayé, bí ìgbà tí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ẹ̀fúùfù líle mì bá gbọn àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ tí kò pọ́n dànù.” (Ìṣípayá 6:12b, 13) Àrà mérìíyìírí gbáà mà lèyí o! Ǹjẹ́ o lè ronú nípa bí òkùnkùn tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí á yọrí sí ṣe máa da jìnnìjìnnì boni tó nígbà tó bá ní ìmúṣẹ bí wòlíì náà ṣe sọ ọ́ gan-an? Kò ní sí ìmọ́lẹ̀ oòrùn lílọ́wọ́ọ́wọ́, tí ń tuni lára lọ́sàn-án mọ́! Kò ní sí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá gbígbádùn mọ́ni, aláwọ̀ fàdákà ní òru mọ́! Ẹgbàágbèje ìràwọ̀ ò ní ṣẹ́jú wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ní sánmà mọ́ rárá. Dípò bẹ́ẹ̀, òkùnkùn dídúdú kirikiri, tó máa ń mú kí nǹkan súni ló máa wà.—Fi wé Mátíù 24:29.

18. Lọ́nà wo ni ‘àwọn ọ̀run gbà di ṣíṣú’ fún Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni?

18 Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irú òkùnkùn tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ á wà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó kìlọ̀ pé: “Ahoro ni gbogbo ilẹ̀ náà yóò dà, èmi kò ha sì ní mú kìkìdá ìparun pátápátá ṣẹ bí? Ní tìtorí èyí, ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ọ̀run lókè yóò sì ṣókùnkùn dájúdájú.” (Jeremáyà 4:27, 28) Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ, lóòótọ́ làwọn nǹkan ṣókùnkùn fáwọn èèyàn Jèhófà. Àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Olú ìlú wọn, Jerúsálẹ́mù. Wọ́n pa tẹ́ńpìlì wọn run, ilẹ̀ wọn sì di ahoro. Kò sí ìmọ́lẹ̀ ìtùnú kankan láti ọ̀run fún wọn mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Jeremáyà ṣe fi ohùn arò bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ló ṣe rí, ó wí pé: “O ti pa; ìwọ kò sì fi ìyọ́nú hàn. O ti fi ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ ara rẹ, kí àdúrà má lè là á kọjá.” (Ìdárò 3:43, 44) Ikú àti ìparun ni òkùnkùn òkè ọ̀run yẹn túmọ̀ sí fún Jerúsálẹ́mù.

19. (a) Báwo ni Aísáyà, wòlíì Ọlọ́run, ṣe ṣàpèjúwe òkùnkùn kan ní ọ̀run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Bábílónì ìgbàanì? (b) Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ, báwo ló sì ṣe ní ìmúṣẹ?

19 Lẹ́yìn náà, irú òkùnkùn kan náà ní ọ̀run túmọ̀ sí ìjábá fún Bábílónì ìgbàanì. Nípa èyí, wòlíì Ọlọ́run kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Wò ó! Àní ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, ó níkà pẹ̀lú ìbínú kíkan àti pẹ̀lú ìbínú jíjófòfò, láti lè sọ ilẹ̀ náà di ohun ìyàlẹ́nu, kí ó sì lè pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò lórí rẹ̀. Nítorí pé àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti àwọn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì wọn pàápàá kì yóò mú kí ìmọ́lẹ̀ wọn kọ mànà; oòrùn yóò ṣókùnkùn nígbà ìjáde lọ rẹ̀ ní ti tòótọ́, òṣùpá pàápàá kì yóò sì mú kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn. Dájúdájú, èmi yóò mú ìwà búburú tirẹ̀ wọlé wá sórí ilẹ̀ eléso náà, àti ìṣìnà tiwọn wá sórí àwọn ẹni burúkú tìkára wọn.” (Aísáyà 13:9-11) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì. Ó ṣàpèjúwe bí òkùnkùn biribiri ṣe bo Bábílónì, bó ṣe wà láìní ìrètí, àti bí kò ṣe sí ìmọ́lẹ̀ ìtùnú èyíkéyìí fún un nígbà táwọn ọmọ ogun ṣẹ́gun rẹ̀ títí gbére tí kò sì sí nípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbára ayé tó gba iwájú jù lọ mọ́.

20. Àbárèbábọ̀ bíbanilẹ́rù wo ló ń dúró de ètò àwọn nǹkan yìí nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ ńlá náà bá sẹ̀?

20 Bákan náà, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ délé-dóko náà bá sẹ̀, gbogbo ètò ayé yìí ni òkùnkùn biribiri á bò nítorí pé kò ní sí ìrètí kankan fún wọn. Ìrètí kankan ò ní sí látọ̀dọ̀ ètò Sátánì orí ilẹ̀ ayé, tó dà bí orísun ìmọ́lẹ̀ tí ń dán yanran. Àní lákòókò wa yìí, àwọn olóṣèlú ayé, pàápàá jù lọ, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, làwọn èèyàn ti mọ̀ pé wọ́n ń hùwà ìbàjẹ́, wọ́n ń pa fóò nínú irọ́, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe. (Aísáyà 28:14-19) Wọn ò yẹ lẹ́ni téèyàn í gbẹ́kẹ̀ lé mọ́. Ìmọ́lẹ̀ wọn tí ń di bàìbàì yóò sì mòòkùn pátápátá nígbà tí Jèhófà bá mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún. Àṣírí agbára tí wọ́n ní lórí bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ayé máa tú, a óò rí i pé ọwọ́ wọn kún fún ẹ̀jẹ̀, apààyàn sì ni wọ́n. Títán máa dé bá àwọn ògbóǹtarìgì tó ń tàn bí ìràwọ̀ lára wọn, wọ́n á di fífẹ́ pa bí ìràwọ̀ tó já wálẹ̀ dòò, ìjì ẹ̀fúùfù ńláńlá á sì tú wọn ká bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò gbó. ‘Ìpọ́njú ńlá, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, tí kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́,’ á mi gbogbo ilẹ̀ ayé wa tìtì. (Mátíù 24:21) Ẹ wo bí ohun tá à ń retí yìí ti bani lẹ́rù tó!

“Ọ̀run” Lọ Kúrò

21. Nínú ìran rẹ̀, kí ni Jòhánù rí nípa “ọ̀run” àti “gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù”?

21 Ìran Jòhánù ń bá a lọ pé: “Ọ̀run sì lọ kúrò bí àkájọ ìwé tí a ń ká, gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù ni a sì ṣí kúrò ní àyè wọn.” (Ìṣípayá 6:14) Ó dájú pé, ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀run gidi tàbí àwọn òkè ńlá àti àwọn erékùṣù gidi. Ṣùgbọ́n kí ni wọ́n dúró fún?

22. Ní Édómù irú “ọ̀run” wo ló di ‘kíká jọ gẹ́gẹ́ bí ìwé àkájọ’?

22 Irú àsọtẹ́lẹ̀ kan náà tó sọ nípa ìrunú Jèhófà lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí “ọ̀run” dúró fún. Ó sọ pé: “Gbogbo àwọn tí í ṣe ara ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run yóò sì jẹrà dànù. A ó sì ká ọ̀run jọ, gẹ́gẹ́ bí ìwé àkájọ.” (Aísáyà 34:4) Édómù ní pàtàkì gbọ́dọ̀ jìyà. Lọ́nà wo? Àwọn ará Bábílónì gba ilẹ̀ rẹ̀ kété lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni. Lákòókò yẹn, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ títayọ èyíkéyìí ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run gidi. Ṣùgbọ́n àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alájàálù wà ní “ọ̀run” ìṣàpẹẹrẹ ti Édómù. e Àwọn agbára ìjọba èèyàn di rírẹ̀sílẹ̀ láti ipò gíga bí ọ̀run tí wọ́n wà. (Aísáyà 34:5) Ṣe ló dà bíi pé a ‘ká wọn jọ’ a sì rọ́ wọn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, bí àkájọ ìwé ògbólógbòó kan tí kò wúlò fún ohunkóhun àti fún ẹnikẹ́ni mọ́.

23. Kí ni “ọ̀run” tí yóò “lọ kúrò bí àkájọ ìwé,” báwo sì ni àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe túbọ̀ fìdí òye yìí múlẹ̀?

23 Nípa báyìí, “ọ̀run” yẹn tí yóò “lọ kúrò bí àkájọ ìwé” ni àwọn ìjọba tó ta ko Ọlọ́run tí ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé. Agẹṣin funfun tó jẹ́ aṣẹ́gun gbogbo ogun náà yóò mú wọn wá sópin pátápátá. (Ìṣípayá 19:11-16, 19-21) Ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ nígbà tó ń wọ̀nà fáwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ṣíṣí èdìdì kẹfà ṣàpẹẹrẹ túbọ̀ fìdí èyí múlẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:7) Tí apá tó sọ pé “gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù ni a sì ṣí kúrò ní àyè wọn” ńkọ́?

24. (a) Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ pé àwọn òkè ńlá àti àwọn erékùṣù mì jìgìjìgì tàbí tí wọ́n di èyí tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́? (b) Báwo ni ‘àwọn òkè ńlá ṣe mì jìgìjìgì’ nígbà táwọn ọmọ ogun ṣẹ́gun Nínéfè?

24 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àwọn òkè ńlá àtàwọn erékùṣù la sábà máa ń sọ pé wọ́n mì jìgìjìgì tàbí lọ́rọ̀ mìíràn pé wọn ò fìdí múlẹ̀ mọ́ láwọn àkókò tí rúkèrúdò ńláǹlà bá wà nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wòlíì Náhúmù ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìdájọ́ Jèhófà lòdì sí Nínéfè, ó kọ̀wé pé: “Àwọn òkè ńláńlá ti mì jìgìjìgì nítorí rẹ̀, àní àwọn òkè kéékèèké bẹ̀rẹ̀ sí yọ́. Ilẹ̀ ayé yóò sì ru gùdù sókè nítorí ojú rẹ̀.” (Náhúmù 1:5) Kò sí àkọsílẹ̀ kankan pé àwọn òkèyókè fọ́ sí wẹ́wẹ́ nígbà táwọn ọmọ ogun ṣẹ́gun ìlú Nínéfè lọ́dún 632 ṣááju Sànmánì Kristẹni. Ṣùgbọ́n agbára ayé kan tí agbára rẹ̀ mú kó dà bí òkè ńlá tẹ́lẹ̀ rí wó lulẹ̀ lójijì.—Fi wé Jeremáyà 4:24.

25. Lópin ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀ wá yìí, báwo ni Jèhófà àti Jésù á ṣe ṣí “gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù” kúrò ní ààyè wọn?

25 Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé “gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù” tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí Jésù ṣí èdìdì kẹfà yóò jẹ́ àwọn ìjọba ìṣèlú àti àwọn àjọ tí wọ́n gbára lé ayé yìí, tó jọ bíi pé wọ́n fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé. Jèhófà àti Jésù á mì wọ́n jìgìjìgì kúrò ní àyè wọn, èyí tó máa ya àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé wọn tẹ́lẹ̀ lẹ́nu tó sì máa da jìnnìjìnnì bò wọ́n. Àti pé bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti ń bá a lọ, kò ní sí iyè méjì kankan pé ọjọ́ ìkannú ńlá Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, ìyẹn mímì tìtì ìkẹyìn tí yóò mú gbogbo ètò Sátánì kúrò, ti dé láti gbẹ̀san!

“Ẹ Wó Bò Wá, Kí Ẹ Sì Fi Wá Pa Mọ́”

26. Kí ni ìpayà á mú káwọn èèyàn tó ta ko ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe, ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ wo ni wọn yóò sì sọ jáde?

26 Ọ̀rọ̀ Jòhánù ń bá a nìṣó: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ènìyàn onípò gíga jù lọ àti àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára àti olúkúlùkù ẹrú àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní òmìnira fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò àti sínú àwọn àpáta ràbàtà àwọn òkè ńlá. Wọ́n sì ń sọ fún àwọn òkè ńlá àti fún àwọn àpáta ràbàtà pé: ‘Ẹ wó bò wá, kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò ní ojú Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti kúrò nínú ìrunú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, nítorí ọjọ́ ńlá ìrunú wọn ti dé, ta ni ó sì lè dúró?’”—Ìṣípayá 6:15-17.

27. Igbe wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ tí wọ́n wà ní Samáríà ké, báwo làwọn ọ̀rọ̀ yẹn sì ṣe nímùúṣẹ?

27 Nígbà tí Hóséà ń kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí Samáríà, olú ìlú ìjọba Ísírẹ́lì ti àríwá, ó wí pé: “Àwọn ibi gíga Bẹti-áfénì, ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì, ni a ó sì pa rẹ́ ráúráú ní ti tòótọ́. Ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò hù jáde lórí pẹpẹ wọn. Àwọn ènìyàn yóò sì sọ fún àwọn òkè ńlá ní ti tòótọ́ pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ wó bò wá!’” (Hóséà 10:8) Báwo ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe ní ìmúṣẹ? Ohun kan ni pé, nígbà tí àwọn ara Ásíríà oníkà ṣẹ́gun Samáríà lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Kristẹni, kò sí ibì kankan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè sá lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ Hóséà fi hàn bí àwọn tí ọ̀tá ṣẹ́gun ò ṣe rẹni ràn wọ́n lọ́wọ́, bí ìpayà ṣe bá wọn, tí ò sì sẹ́ni tó dá sí wọn. Yálà àwọn òkè kéékèèké gidi ni o, tàbí àwọn ètò ìdásílẹ̀ bí òkè ńlá ní Samáríà ni o, kò sí èyí tó lè dáàbò bò wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fìgbà kan rí dà bí èyí tí kò ṣeé ṣí nípò.

28. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún àwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù? (b) Báwo ni ìkìlọ̀ Jésù ṣe ní ìmúṣẹ?

28 Lọ́nà kan náà, nígbà táwọn jagunjagun ará Róòmù ń mú Jésù lọ pa, ó bá àwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ pé: “Àwọn ọjọ́ ń bọ̀ nínú èyí tí àwọn ènìyàn yóò sọ pé, ‘Aláyọ̀ ni àwọn àgàn, àti àwọn ilé ọlẹ̀ tí kò bímọ àti àwọn ọmú tí a kò fi fún ọmọ mu!’ Nígbà náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó bò wá!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’” (Lúùkù 23:29, 30) Kò sí àṣìkọ kankan nínú àkọsílẹ̀ nípa bí àwọn ará Róòmù ṣe pa Jerúsálẹ́mù rún lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, ó sì hàn gbangba pé ọ̀kan ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù àti ti Hóséà já sí. Àwọn Júù tí wọ́n dúró ní Jùdíà kò rí ibì kankan fara pa mọ́ sí. Ibi yòówù kí wọ́n gbìyànjú láti sá pa mọ́ sí ní Jerúsálẹ́mù, tó fi mọ́ ibi tí wọ́n sá lọ lórí òkè ńlá ti Màsádà, wọn ò bọ́ lọ́wọ́ ìbínú gbígbóná janjan ti ìdájọ́ Jèhófà.

29. (a) Nígbà tí ọjọ́ ìkannú Jèhófà bá dé, kí ni yóò jẹ́ ìṣòro àwọn tí wọ́n ń ti ètò àwọn nǹkan yìí lẹ́yìn gbágbáágbá? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù wo ni yóò ní ìmúṣẹ lọ́jọ́ ìkannú Jèhófà?

29 Wàyí o, ṣíṣí èdìdì kẹfà ti fi hàn pé ohun tó fara jọ èyí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìkannú Jèhófà tí ń bọ̀ wá. Nígbà tí mímì tó kẹ́yìn fún ètò àwọn nǹkan orí ilẹ̀ ayé yìí bá mì, àwọn tí wọ́n ń tì í lẹ́yìn gbágbáágbá á máa wá ibi tí wọ́n máa fara pa mọ́ sí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n wọn ò ní rí ìkankan. Ìsìn èké, Bábílónì Ńlá, ti já wọn kulẹ̀ pátápátá. Àwọn hòrò inú àwọn òkè ńlá gidi àtàwọn ètò ìṣèlú àti ìṣòwò bí òkè ńlá ìṣàpẹẹrẹ sì rèé, wọn ò ní lè fowó tán ìṣòro wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn. Kò sí ohunkóhun tó máa dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìkannú Jèhófà. Jésù ò ṣi ọ̀rọ̀ sọ nígbà tó ń ṣàpèjúwe ìpayà tó máa bá wọn, ó sọ pé: “Nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.”—Mátíù 24:30.

30. (a) Kí ni ìbéèrè náà: “Ta ni ó sì lè dúró?” túmọ̀ sí? (b) Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni á lè dúró nígbà ìdájọ́ Jèhófà?

30 Ó dájú pé àwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba Agẹṣin funfun tí ń jagun mólú náà lọ́gàá, máa gbà ní dandan pé àwọn ti ṣàṣìṣe. Títán á dé bá àwọn èèyàn tí wọ́n ti fi tinútinú jẹ́ apá kan irú-ọmọ ejò náà, nígbà tí ayé Sátánì bá kọjá lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 1 Jòhánù 2:17) Báyé á ṣe rí nígbà yẹn á mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa béèrè pé: “Ta ni ó sì lè dúró?” Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n lérò pé kò ní sí ẹnì kankan táá jèrè ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà ní ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ò ní gba ibi tí wọ́n fojú sí bí ìwé Ìṣípayá ti ń bá a lọ láti fi hàn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lọ́pọ̀ ìgbà, kí ìsẹ̀lẹ̀ gidi tó wáyé, ilẹ̀ máa ń mì lọ́nà kan táá mú káwọn ajá máa gbó kí wọ́n sì máa ṣe wọ́nranwọ̀nran. Ó lè mú káwọn ẹranko míì máa rúgbó káwọn ẹja sì máa da omi rú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè máà fura títí tí ilẹ̀ á fi sẹ̀ ní ti gidi.—Wo Jí! (Gẹ̀ẹ́sì), July 8, 1982, ojú ìwé 14.

b Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé wà lójú ìwé 22 àti 24.

c Léyìí tó ju ọdún márùndínlógójì [35] lọ, látọdún 1895 sí ọdún 1931, la fi ń kọ ọ̀rọ̀ inú Lúùkù 21:25, 28, 31 sẹ́yìn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) tó ní àwòrán ilé tí ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òfuurufú tí ìjì ti ń jà tí òkun tí ń ru gùdù sì wà nísàlẹ̀.

d Bí àpẹẹrẹ, nínú àkànṣe ìgbòkègbodò kan lọ́dún 1931, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fọwọ́ ara wọn mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé kékeré náà, The Kingdom, the Hope of the World, tọ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn òṣèlú àtàwọn oníṣòwò lọ, jákèjádò ilẹ̀ ayé.

e Níbòmíì tá a tún ti lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” lọ́nà yìí, ìyẹn nínú àsọtẹ́lẹ̀ “ọ̀run tuntun” nínú ìwé Aísáyà 65:17, 18, ó kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ lórí ètò ìjọba tuntun tó kan Gómìnà Serubábélì àti Àlùfáà Àgbà Jéṣúà. Lẹ́yìn táwọn Júù padà láti ìgbèkùn Bábílónì ni ìjọba tuntun náà fìdí múlẹ̀ ní Ilẹ̀ Ìlérí.—2 Kíróníkà 36:23; Ẹ́sírà 5:1, 2; Aísáyà 44:28.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 105]

A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ọdún 1914

“Ọdún 606 ṣáájú Ìbí Kristi ni ìjọba Ọlọ́run dópin, a ṣí adé kúrò, a sì fi gbogbo ilẹ̀ ayé fún àwọn Kèfèrí. Ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rin [2,520] ọdún láti ọdún 606 ṣáájú Ìbí Kristi dópin ní ọdún 1914 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa.” f—Ìwé The Three Worlds, tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 1877, ojú ìwé 83.

“Ẹ̀rí Bíbélì ṣe kedere ó sì fìdí múlẹ̀ pé ‘Àkókò Àwọn Kèfèrí’ jẹ́ sáà ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rin [2,520] ọdún, látọdún 606 ṣáájú Ìbí Kristi, títí dé ọdún 1914 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa, tí ó sì tún ní ọdún yẹn nínú.”—Studies in the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 79. C. T. Russell ló kọ ọ́, a sì tẹ̀ ẹ́ lọ́dún 1889.

Charles Taze Russell àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú pé 1914 yóò sàmì sí òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí, tàbí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Lúùkù 21:24) Nígbà tó jẹ́ pé ní àwọn ọjọ́ ìjímìjí wọ̀nyẹn wọn ò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye nípa ohun tí èyí yóò túmọ̀ sí, wọ́n fi ìdánilójú gbà pé 1914 ni yóò jẹ́ ọdún pàtàkì nínú ìtàn ayé, wọ́n sì tọ̀nà. Kíyè sí ọ̀rọ̀ tá a fà yọ láti inú ìwé ìròyìn kan:

“Jíjà tí ogun tó bani lẹ́rù jà ní Yúróòpù ti mú àsọtẹ́lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹ. Láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn, nípasẹ̀ àwọn àlùfáà àti nípasẹ̀ ilé iṣẹ́ ìròyìn, ‘Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Àgbáyé,’ tá a mọ̀ níbi gbogbo bíi ‘Millennial Dawners,’ ti ń pòkìkí fún ayé pé Ọjọ́ Ìkannú tá a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì yóò dé lọ́dún 1914. ‘Ẹ máa fojú sọ́nà fún ọdún 1914!’ ni igbe tó gba ẹnu ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ajíhìnrere arìnrìn-àjò.”—Ìwé ìròyìn ìlú New York tó ń jẹ́ The World, àtẹ̀jáde August 30, 1914.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

f Nígbà yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò tíì mọ̀ pé kò sí àlàfo ọdún kankan láàárín sànmánì “ṣáájú Ìbí Kristi” àti sànmánì “Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa,” àmọ́, ó bà ni, kò bà jẹ́. Nígbà tí ìwádìí mú kó pọn dandan fún wọn láti ṣàtúnṣe ọdún 606 ṣáájú Ìbí Kristi sí ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, wọ́n yọ àlàfo ọdún kan yẹn kúrò, tí ìsọtẹ́lẹ̀ náà fi wá já sí òótọ́ ní ọdún “1914 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa.”—Wo ojú ìwé 203 sí 204 nínú ìwé “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde lédè Yorùbá lọ́dún 1948.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 106]

1914—Ọdún Ìyípadà

Ìwé náà Politikens Verdenshistorie—Historiens Magt og Mening (Ìtàn Ayé—Agbára àti Ìtumọ̀ Ìtàn láti ọwọ́ Politiken), tí wọ́n tẹ̀ jáde nílùú Copenhagen, lọ́dún 1987 sọ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí ní ojú ìwé 40:

“Ìgbàgbọ́ pé ìlọsíwájú á máa wà nìṣó ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ròkun ìgbàgbé lọ́dún 1914. Ní ọdún tó ṣáájú kí ogun tó jà, òpìtàn àti òṣèlú ará Denmark náà Peter Munch kọ̀wé bí ẹni tọ́rọ̀ dá lójú pé kò ní séwu, ó sọ pé: ‘Ẹ̀rí gbogbo fi hàn pé ogun èyíkéyìí ò ní jà láàárín àwọn alágbára ògbóǹtarìgì ńlá Yúróòpù. “Ewu ogun” sì tún máa pòórá lọ́jọ́ iwájú, bó ti máa ń rí látìgbàdégbà látọdún 1871 wá.’

“A rí i kà pé ọ̀nà ò gbabi tó fojú sí bó ṣe wà nínú àkọọ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣojú ẹ̀ pé: ‘Ogun tó jà lọ́dún 1914 sọ ọdún náà di ọdún ìyípadà ńláǹlà látijọ́ táláyé ti dáyé. Láti sànmánì tí nǹkan ti ń lọ geerege, téèyàn ti lè fi ìbàlẹ̀-ọkàn lé ohun tó gbé ka iwájú bá, àfi kọ́ṣọ́ tá a wọnú sànmánì ìjábá, ìpayà, àti ìkórìíra, tí ewu sì wà níbi gbogbo. Kò sẹ́ni tó lè sọ, títí dòní pàápàá kò sẹ́ni tó lè sọ, bóyá òkùnkùn birimù tó bò wá nígbà yẹn ló máa ba gbogbo àjọṣe ti ẹ̀dá téèyàn ti fọwọ́ ara ẹ̀ gbé kalẹ̀ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún jẹ́ yán-án yán-án.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 110]

‘Gbogbo òkè ńlá ni a ṣí kúrò ní àyè wọn’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 111]

Wọ́n fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò