Náhúmù 1:1-15

  • Ọlọ́run máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ (1-7)

    • Ọlọ́run fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo (2)

    • Jèhófà mọ àwọn tó ń wá ibi ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀ (7)

  • Nínéfè máa pa run (8-14)

    • Wàhálà kò ní dìde lẹ́ẹ̀kejì (9)

  • Ìròyìn ayọ̀ fún Júdà (15)

1  Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Nínéfè:+ Èyí ni ìwé tó sọ nípa ìran tí Náhúmù* ará Élíkóṣì rí:   Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo,+ ó sì ń gbẹ̀san;Jèhófà ń gbẹ̀san, ó sì ṣe tán láti bínú.+ Jèhófà ń gbẹ̀san lára àwọn elénìní rẹ̀,Ó sì ń to ìbínú rẹ̀ jọ de àwọn ọ̀tá rẹ̀.   Jèhófà kì í tètè bínú,+ agbára rẹ̀ sì pọ̀,+Àmọ́, Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ìyà bá tọ́ sí.+ Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú ẹ̀fúùfù àti ìjì líle,Àwọsánmà sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.+   Ó bá òkun wí,+ ó mú kí ó gbẹ;Ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ.+ Báṣánì àti Kámẹ́lì rọ,+Ìtànná Lẹ́bánónì sì rọ.   Àwọn òkè ńlá mì tìtì nítorí rẹ̀,Àwọn òkè kéékèèké sì yọ́.+ Ayé á ru sókè nítorí ojú rẹ̀,Àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.+   Ta ló lè dúró nígbà tó bá ń bínú?+ Ta ló sì lè fara da ooru ìbínú rẹ̀?+ Yóò tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná,Àwọn àpáta á sì fọ́ sí wẹ́wẹ́ nítorí rẹ̀.   Jèhófà jẹ́ ẹni rere,+ odi agbára ní ọjọ́ wàhálà.+ Ó sì mọ* àwọn tó ń wá ibi ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.+   Àkúnya omi ló máa fi pa Nínéfè* run,Òkùnkùn á sì lé àwọn ọ̀tá rẹ̀.   Kí lẹ rò pé ẹ lè ṣe sí Jèhófà? Ó ń fa ìparun yán-án yán-án. Wàhálà kò ní dìde lẹ́ẹ̀kejì.+ 10  Wọ́n ṣù pọ̀ mọ́ra bí ẹ̀gún,Wọ́n sì dà bí àwọn tó mu ọtí bíà yó;*Ṣùgbọ́n iná á jó wọn run bí àgékù pòròpórò gbígbẹ. 11  Ẹni tó ń gbèrò ibi sí Jèhófà máa jáde wá láti ọ̀dọ̀ rẹ,Á sì máa fúnni ní ìmọ̀ràn tí kò dáa. 12  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní agbára, tí wọ́n sì pọ̀ gan-an,Síbẹ̀, a máa gé wọn lulẹ̀, wọ́n á sì kọjá lọ.* Mo ti fìyà jẹ ọ́* tẹ́lẹ̀, àmọ́ mi ò ní fìyà jẹ ọ́ mọ́. 13  Nítorí náà, màá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ,+Màá sì já ìdè rẹ sí méjì. 14  Jèhófà ti pàṣẹ nípa rẹ* pé,‘Kò ní sí ẹni tí á máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́. Màá run àwọn ère gbígbẹ́ àti ère onírin* kúrò ní ilé* àwọn ọlọ́run rẹ. Màá gbẹ́ sàréè fún ọ torí pé mo kórìíra rẹ gan-an.’ 15  Wò ó! Orí àwọn òkè ni ẹsẹ̀ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá wà,Ẹni tó ń kéde àlàáfíà.+ Ṣe àwọn àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ Júdà, kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ,Nítorí ẹni tí kò ní láárí kò tún ní gba àárín rẹ kọjá mọ́. Ṣe ni yóò pa run pátápátá.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Olùtùnú.”
Tàbí “ń tọ́jú.”
Ní Héb., “àyè rẹ̀.”
Tàbí “bíà tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”
Tàbí kó jẹ́, “yóò sì là á kọjá.”
Ìyẹn, “Júdà.”
Ìyẹn, “Ásíríà.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”