Ìdárò 3:1-66

  • Jeremáyà sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ àti ìrètí rẹ̀

    • ‘Màá fi sùúrù dúró dè ọ́’ (21)

    • Tuntun ni àánú Ọlọ́run láràárọ̀ (22, 23)

    • Ọlọ́run jẹ́ ẹni rere sí àwọn tó ní ìrètí nínú rẹ̀ (25)

    • Ó dára kí àwọn ọ̀dọ́ ru àjàgà (27)

    • Ọlọ́run fi àwọsánmà dí ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ (43, 44)

א [Áléfì] 3  Èmi ni ọkùnrin tó ti rí ìpọ́njú nítorí ọ̀pá ìbínú rẹ̀.   Ó ti lé mi jáde, ó sì mú kí n rìn nínú òkùnkùn, kì í ṣe nínú ìmọ́lẹ̀.+   Ní tòótọ́, ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ gbá mi léraléra láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+ ב [Bétì]   Ó ti mú kí ara mi ṣàárẹ̀, àwọ̀ mi sì ti ṣá;Ó ti fọ́ egungun mi.   Ó ti dó tì mí; ó sì ti fi májèlé kíkorò+ àti ìnira yí mi ká.   Ó ti fipá mú mi jókòó síbi tó ṣókùnkùn, bí àwọn tó ti kú tipẹ́tipẹ́. ג [Gímélì]   Ó ti fi ògiri ká mi mọ́, kí n má bàa sá lọ;Ó ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà tó wúwo dè mí.+   Nígbà tí mo bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, kì í gbọ́* àdúrà mi.+   Ó ti fi òkúta gbígbẹ́ dí àwọn ọ̀nà mi pa;Ó ti lọ́ àwọn ojú ọ̀nà mi po.+ ד [Dálétì] 10  Ó lúgọ dè mí bíi bíárì àti bíi kìnnìún tó fara pa mọ́.+ 11  Ó fipá wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà, ó sì fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ;*Ó ti sọ mí di ahoro.+ 12  Ó ti fa ọfà* rẹ̀, ó sì gbé mi kalẹ̀ bí ohun tí a fẹ́ ta ọfà sí. ה [Híì] 13  Ó ti ta ọfà* inú apó rẹ̀ lu kíndìnrín mi. 14  Mo ti di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo èèyàn, ọ̀rọ̀ mi sì ni wọ́n fi ń ṣe orin kọ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. 15  Ó ti fi àwọn ohun tó korò kún inú mi, ó sì fún mi ní iwọ* mu ní àmuyó.+ ו [Wọ́ọ̀] 16  Ó ti fi òkúta kán eyín mi;Ó ti tì mí ṣubú sínú eérú.+ 17  O ti gba àlàáfíà mi;* mo ti gbàgbé ohun rere. 18  Torí náà mo sọ pé: “Ògo mi ti pa rẹ́ àti ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ Jèhófà.” ז [Sáyìn] 19  Rántí ìyà tó ń jẹ mí àti bí mi ò ṣe rílé gbé,+ má gbàgbé pé mo jẹ iwọ* àti májèlé kíkorò.+ 20  Ó dájú pé o* máa rántí, wàá sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí o lè ràn mí lọ́wọ́.+ 21  Mo rántí èyí nínú ọkàn mi; ìdí nìyẹn tí màá ṣe fi sùúrù dúró dè ọ́.+ ח [Hétì] 22  Nítorí ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé,+Nítorí àánú rẹ̀ kò ní dópin láé.+ 23  Tuntun ni wọ́n láràárọ̀;+ ìṣòtítọ́ rẹ pọ̀ gan-an.+ 24  Mo* sọ pé, “Jèhófà ni ìpín mi,+ ìdí nìyẹn tí màá ṣe fi sùúrù dúró dè é.”+ ט [Tétì] 25  Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé e,+ ìyẹn ẹni* tó ń wá a.+ 26  Ó dáa kí èèyàn dúró jẹ́ẹ́*+ de ìgbàlà Jèhófà.+ 27  Ó dáa kí ọkùnrin ru àjàgà ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀.+ י [Yódì] 28  Kí ó dá jókòó, kí ó sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ nígbà tí Ọlọ́run bá gbé e le lórí.+ 29  Kí ó dojú bolẹ̀ nínú eruku;+ bóyá ìrètí ṣì lè wà fún un.+ 30  Kí ó gbé etí rẹ̀ fún ẹni tó ń gbá a; kí ó gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀gàn. כ [Káfì] 31  Nítorí Jèhófà kò ní kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé.+ 32  Bí ó tilẹ̀ fa ẹ̀dùn ọkàn, á tún fi àánú hàn nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+ 33  Nítorí kò ní in lọ́kàn láti kó ìdààmú tàbí ẹ̀dùn ọkàn bá ọmọ èèyàn.+ ל [Lámédì] 34  Láti tẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n gbogbo ayé mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ ẹni,+ 35  Láti yí ìdájọ́ ẹnì kan po níwájú Ẹni Gíga Jù Lọ,+ 36  Láti rẹ́ ẹnì kan jẹ nínú ẹjọ́ rẹ̀,Jèhófà kò fàyè gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. מ [Mémì] 37  Ta ló wá lè sọ̀rọ̀ kó sì mú un ṣẹ láìjẹ́ pé Jèhófà pa á láṣẹ? 38  Ohun búburú àti ohun rereKì í ti ẹnu Ẹni Gíga Jù Lọ jáde. 39  Kí nìdí tí alààyè yóò fi ráhùn nítorí àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? + נ [Núnì] 40  Ẹ jẹ́ ká yẹ ọ̀nà wa wò, ká wò ó fínnífínní,+ ẹ sì jẹ́ ká pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.+ 41  Ẹ jẹ́ ká gbé ọkàn wa àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run lókè ọ̀run:+ 42  “A ti dẹ́ṣẹ̀, a ti ṣọ̀tẹ̀,+ ìwọ kò sì tíì dárí jì wá.+ ס [Sámékì] 43  O ti fi ìbínú dí ọ̀nà àdúrà wa;+O lé wa, o sì pa wá láìṣàánú.+ 44  O ti fi àwọsánmà dí ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ rẹ, kí àdúrà wa má bàa kọjá.+ 45  Ó sọ wá di èérí àti pàǹtírí láàárín àwọn èèyàn.” פ [Péè] 46  Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn sí wa.+ 47  Inú ẹ̀rù àti kòtò la wà,+ a ti di ahoro, a sì ti di àwókù.+ 48  Omi ń ṣàn wálẹ̀ ní ojú mi nítorí ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi ti ṣubú lulẹ̀.+ ע [Áyìn] 49  Omijé ń dà lójú mi pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀, kò dáwọ́ dúró,+ 50  Títí Jèhófà fi bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, tí ó sì rí i.+ 51  Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nígbà tí mo rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin ìlú mi.+ צ [Sádì] 52  Àwọn ọ̀tá mi ti dẹkùn mú mi bí ẹyẹ, láìnídìí. 53  Wọ́n ti mú kí ẹ̀mí mi dákẹ́ sínú kòtò; wọ́n sì ń sọ òkúta lù mí. 54  Omi ti ṣàn bò mí lórí, mo sì sọ pé: “Tèmi ti tán!” ק [Kófì] 55  Mo ké pe orúkọ rẹ, Jèhófà, láti inú kòtò tó jìn.+ 56  Gbọ́ ohùn mi; má ṣe dí etí rẹ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ àti fún ìtura. 57  O sún mọ́ tòsí ní ọjọ́ tí mo pè ọ́. O sọ pé: “Má bẹ̀rù.” ר [Réṣì] 58  O ti gbèjà mi,* Jèhófà, o ti ra ẹ̀mí mi pa dà.+ 59  O ti rí àìtọ́ tí wọ́n ṣe sí mi, Jèhófà; jọ̀ọ́ dá mi láre.+ 60  O ti rí gbogbo bí wọ́n ṣe ń gbẹ̀san, gbogbo ètekéte wọn sí mi. ש [Sínì] tàbí [Ṣínì] 61  O ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn, Jèhófà, gbogbo ètekéte wọn sí mi,+ 62  Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tó ń ta kò mí àti ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n ń sọ nípa mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. 63  Wò wọ́n; bóyá wọ́n jókòó ni o àbí wọ́n dúró, èmi ni wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ nínú orin wọn! ת [Tọ́ọ̀] 64  Wàá san án pa dà fún wọn, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. 65  Wàá mú kí ọkàn wọn le, gẹ́gẹ́ bí o ti gégùn-ún fún wọn. 66  Wàá lé wọn nínú ìbínú rẹ, Jèhófà, wàá sì pa wọ́n rẹ́ lábẹ́ ọ̀run rẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ó ń dínà.”
Tàbí kó jẹ́, “ó ti jẹ́ kí n dà bí ilẹ̀ tí a pa tì.”
Ní Héb., “tẹ ọrun.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Tàbí “ọkàn mi.”
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “fi sùúrù dúró.”
Tàbí “gba ẹjọ́ ọkàn mi rò.”