Jeremáyà 5:1-31
5 Ẹ lọ káàkiri àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.
Ẹ wò yí ká, kí ẹ sì kíyè sí i.
Ẹ wo àwọn ojúde rẹ̀
Bóyá ẹ lè rí ẹnì kan tó ń ṣe ohun tó tọ́,+Ẹni tó fẹ́ máa ṣòótọ́,Màá sì dárí jì í.
2 Bí wọ́n bá tiẹ̀ sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè!”
Irọ́ ni wọ́n ṣì máa pa.+
3 Jèhófà, ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn olóòótọ́ ni ojú rẹ ń wò?+
O lù wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ ọ́n lára.*
O pa wọ́n run, àmọ́ wọn ò gba ìbáwí.+
Wọ́n mú ojú wọn le ju àpáta lọ,+Wọn kò sì yí pa dà.+
4 Ṣùgbọ́n mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ó dájú pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan.
Wọ́n hùwà òmùgọ̀, torí pé wọn ò mọ ọ̀nà Jèhófà,Wọn ò mọ òfin Ọlọ́run wọn.
5 Màá lọ sọ́dọ̀ àwọn olókìkí èèyàn, màá sì bá wọn sọ̀rọ̀,Torí wọ́n á ti mọ ọ̀nà Jèhófà,Wọ́n á ti mọ òfin Ọlọ́run wọn.+
Àmọ́ gbogbo wọn ti ṣẹ́ àjàgàWọ́n sì ti fa ìdè* já.”
6 Ìdí nìyẹn tí kìnnìún inú igbó fi bẹ́ mọ́ wọn,Tí ìkookò inú aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ń pa wọ́n jẹ,Tí àmọ̀tẹ́kùn sì lúgọ ní àwọn ìlú wọn.
Gbogbo ẹni tó ń jáde láti inú wọn ló máa fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Torí pé ìṣìnà wọn pọ̀;Ìwà àìṣòótọ́ wọn sì pọ̀.+
7 Báwo ni mo ṣe lè dárí ohun tí o ṣe yìí jì ọ́?
Àwọn ọmọ rẹ ti fi mí sílẹ̀,Wọ́n sì ń fi ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.+
Gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ ni mo fún wọn,Ṣùgbọ́n wọn ò jáwọ́ nínú àgbèrè,Wọ́n sì ń rọ́ lọ sí ilé aṣẹ́wó.
8 Wọ́n dà bí àwọn ẹṣin tí ara wọn ti wà lọ́nà láti gùn,Kálukú wọn ń yán sí aya ọmọnìkejì rẹ̀.*+
9 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.
“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?”+
10 “Ẹ wá sí pooro* oko àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì bà á jẹ́,Ṣùgbọ́n ẹ má pa á run.+
Ẹ gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ,Nítorí wọn kì í ṣe ti Jèhófà.
11 Nítorí ilé Ísírẹ́lì àti ilé JúdàTi hùwà àìṣòótọ́ sí mi gan-an,” ni Jèhófà wí.+
12 “Wọ́n ti kọ Jèhófà, wọ́n sì ń sọ pé,‘Kò ní ṣe nǹkan kan.*+
Àjálù kankan kò ní bá wa;A kò ní rí idà tàbí ìyàn.’+
13 Àwọn wòlíì jẹ́ àgbá òfìfo,Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sì sí lẹ́nu wọn.
Kí ó rí bẹ́ẹ̀ fún wọn!”
14 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Nítorí ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ,Wò ó, màá sọ ọ̀rọ̀ mi di iná ní ẹnu rẹ,+Àwọn èèyàn yìí yóò sì dà bí igi,Yóò sì jó wọn run.”+
15 “Wò ó, màá mú orílẹ̀-èdè kan láti ibi tó jìnnà wá bá yín, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,”+ ni Jèhófà wí.
“Orílẹ̀-èdè tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni.
Orílẹ̀-èdè àtijọ́ ni,Orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè rẹ̀,Tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò lè yé ọ.+
16 Apó wọn dà bíi sàréè tó la ẹnu sílẹ̀;Jagunjagun ni gbogbo wọn.
17 Wọ́n á jẹ irè oko rẹ àti oúnjẹ rẹ.+
Wọ́n á pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ.
Wọ́n á jẹ àwọn agbo ẹran rẹ àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ.
Wọ́n á jẹ àjàrà rẹ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.
Wọ́n á fi idà pa ìlú olódi rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé run.”
18 “Kódà ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “Mi ò ní pa yín run pátápátá.+
19 Tí wọ́n bá sì béèrè pé, ‘Kí ló dé tí Jèhófà Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo nǹkan yìí sí wa?’ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ẹ ṣe fi mí sílẹ̀ láti sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiyín.’”+
20 Ẹ kéde èyí ní ilé Jékọ́bù,Ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà pé:
21 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin òmùgọ̀ àti aláìlọ́gbọ́n:*+
Wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè ríran;+Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ràn.+
22 ‘Ṣé ẹ kò bẹ̀rù mi ni?’ ni Jèhófà wí,‘Ṣé kò yẹ kí ẹ̀rù bà yín níwájú mi?
Èmi ni mo fi iyanrìn pààlà òkun,Ó jẹ́ ìlànà tó wà títí láé tí òkun kò lè ré kọjá.
Bí àwọn ìgbì rẹ̀ tiẹ̀ ń bì síwá-sẹ́yìn, wọn kò lè borí;Bí wọ́n tiẹ̀ pariwo, síbẹ̀, wọn kò lè ré e kọjá.+
23 Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí jẹ́ alágídí ọkàn, wọ́n sì ya ọlọ̀tẹ̀;Wọ́n fi ọ̀nà mi sílẹ̀, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ.+
24 Wọn ò sì sọ lọ́kàn wọn pé:
“Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa,Ẹni tó ń fúnni ní òjò ní àsìkò rẹ̀,Òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé,Ẹni tí kò jẹ́ kí àwọn ọ̀sẹ̀ ìkórè wa yẹ̀.”+
25 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín kò jẹ́ kí gbogbo nǹkan yìí wáyé;Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín sì ti gba ohun rere kúrò lọ́wọ́ yín.+
26 Nítorí àwọn èèyàn burúkú wà láàárín àwọn èèyàn mi.
Wọ́n ń wò bí àwọn pẹyẹpẹyẹ tó lúgọ.
Wọ́n ń dẹ pańpẹ́ ikú.
Èèyàn ni wọ́n ń mú.
27 Bí àgò tí ẹyẹ kún inú rẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tàn kún ilé wọn.+
Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi di alágbára tí wọ́n sì lọ́rọ̀.
28 Wọ́n ti sanra, ara wọn sì ń dán;Iṣẹ́ ibi kún ọwọ́ wọn fọ́fọ́.
Wọn kò gba ẹjọ́ ọmọ aláìníbaba rò,+Kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí;Wọ́n ò fi òdodo dá ẹjọ́ àwọn aláìní.’”+
29 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.
“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?
30 Ohun burúkú àti ẹ̀rù ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:
31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba.
Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+
Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “wọn ò ṣàárẹ̀.”
^ Ní Héb., “ọ̀já.”
^ Tàbí “ń lé aya ọmọnìkejì rẹ̀ kiri.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ilẹ̀ onípele.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Kò sí níbì kankan.”
^ Ní Héb., “ẹ̀yin òmùgọ̀ tí kò ní ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”