Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ọlọ́run Ń Ṣe?

Kí Ni Ọlọ́run Ń Ṣe?

Kí Ni Ọlọ́run Ń Ṣe?

“Jèhófà, èé ṣe tí ìwọ fi dúró lókèèrè réré? Èé ṣe tí ìwọ fi ara rẹ pa mọ́ ní àwọn àkókò wàhálà?” aSÁÀMÙ 10:1.

TÓ O bá kàn wo àkòrí àwọn ìwé ìròyìn gààràgà, wàá rí ẹ̀rí pé “àkókò wàhálà” là ń gbé. Bí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tó sì kàn wá, irú bí ìwà ọ̀daràn, jàǹbá burúkú kan, tàbí kí èèyàn ẹni kú, a lè béèrè pé, Ṣé Ọlọ́run rí i? Ǹjẹ́ ó bìkítà nípa wa? Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ wà?

Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé èrò wa ni kò tọ́ lórí ohun tá à ń retí pé kí Ọlọ́run ṣe? A lè ṣàkàwé rẹ̀ lọ́nà yìí, wo ọmọ kan tó bínú gan-an torí pé bàbá rẹ̀ ti lọ síbi iṣẹ́. Àárò bàbá rẹ̀ ń sọ ọ́, ó sì ń fẹ́ kó pa dà sílé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó rò pé bàbá òun ti pa òun tì. Látòwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ló ń béèrè ṣáá pé, “Bàbá mi dà?”

A mọ̀ pé èrò ọmọ yẹn kò tọ̀nà. Ó ṣe tán, àkókò yẹn gan-an ni bàbá rẹ̀ wà lẹ́nu iṣẹ́ tó ń wá owó tó máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Ṣé kì í ṣe bí ọ̀ràn tiwa náà ṣe rí nìyẹn nígbà tá a bá ń ké jáde pé, “Ọlọ́run dà”?

Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè fẹ́ kí Ọlọ́run ṣèdájọ́ àwọn aṣebi, kó fìyà jẹ wọ́n ní kíákíá. Àwọn míì ti sọ Ọlọ́run di Bàbá Kérésì tó kàn máa ń fúnni lẹ́bùn bó ṣe wù ú, wọ́n retí pé kí Ọlọ́run fún àwọn ní iṣẹ́, ọkọ tàbí aya, kódà, kó jẹ́ kí àwọn jẹ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì.

Àwọn èèyàn yìí rò pé bí Ọlọ́run kò bá ṣèdájọ́ àwọn aṣebi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí kó fún àwọn ní nǹkan táwọn ń béèrè, a jẹ́ pé ìyà tó ń jẹ wá kò ká a lára nìyẹn, kò sì mọ ohun tá a nílò. Àmọ́ ṣá o, irọ́ gbuu ni èrò tí wọ́n ní yẹn! Ohun tó jóòótọ́ ni pé, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Jèhófà Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ láti pèsè fún aráyé lápapọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe lọ́nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò.

Nígbà náà, kí ni Ọlọ́run ń ṣe? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, a ní láti ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ìran èèyàn ní ìbẹ̀rẹ̀ nígbà tí àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run bà jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kọjá àtúnṣe.

Àbájáde Búburú Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Mú Wá

Wo ilé kan tó ti bà jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Òrùlé rẹ̀ ti jìn wọnú, àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ti yọ kúrò lára ohun tó gbé wọn ró, wọ́n sì ti ṣe ara ilé náà báṣabàṣa. Nígbà kan rí, ilé náà dáa, àmọ́ nísinsìnyí kò dáa mọ́. Téèyàn bá wo bí ilé náà ṣe bà jẹ́ tó, iṣẹ́ kékeré kọ́ ló máa gbà láti tún un ṣe. Àtúnṣe náà kò lè wáyé ní ọ̀sán kan, òru kan.

Ṣàgbéyẹ̀wò jàǹbá tó bá aráyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà [6,000] sẹ́yìn nígbà tí ẹ̀mí àìrí náà, Sátánì sún Ádámù àti Éfà láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, tọkọtaya àkọ́kọ́ ń gbádùn ìlera pípé, wọ́n sì nírètí pé àwọn máa gbé títí láé pẹ̀lú àwọn àtọmọdọ́mọ àwọn lọ́jọ́ iwájú. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Àmọ́, nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ni wọ́n ṣàkóbá fún àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí.

Má ṣe fojú kékeré wo ìpalára tí ọ̀tẹ̀ yẹn ṣe fún aráyé. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀  . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [ìyẹn Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Yàtọ̀ sí pé ẹ̀ṣẹ̀ mú ikú wá, ó tún ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa jẹ́, ó sì ṣàkóbá fún ara wa, ọpọlọ wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Nítorí èyí, ńṣe ni ipò tá a wà dà bíi ti ilé kan tó ti bà jẹ́. Nígbà tí ọkùnrin olódodo náà, Jóòbù ń sọ̀rọ̀ nípa ipò tí ẹ̀dá èèyàn wà, ó sọ pé, èèyàn jẹ́ “ọlọ́jọ́ kúkúrú  . . . ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.”—Jóòbù 14:1.

Àmọ́, ṣé Ọlọ́run pa aráyé tì lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀? Rárá o! Kódà, láti ìgbà yẹn títí di ìsinsìnyí ni Bàbá wa ọ̀run ti ń ṣe àwọn nǹkan nítorí àwa èèyàn. Ká bàa lè mọyì ohun tó ti ń ṣe fún wa, ẹ jẹ́ ká gbé ohun mẹ́ta téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe yẹ̀ wò nígbà tó bá fẹ́ tún ilé kan ṣe àti bí àwọn ohun mẹ́tà náà ṣe bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe láti mú aráyé pa dà bọ̀ sípò mu.

1 Lẹ́yìn tí onílé kan bá ti ṣàyẹ̀wò ilé rẹ̀ tó bà jẹ́, ó máa pinnu bóyá kóun tún un ṣe tàbí kóun wó o dà nù.

Kété lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà Ọlọ́run kéde ohun tó fẹ́ ṣe láti mú aráyé pa dà bọ̀ sípò. Ó sọ fún ẹ̀mí àìrí tó wà nídìí ọ̀tẹ̀ náà pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jèhófà fi ṣèlérí pé òun máa pa ẹni tó dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì run. (Róòmù 16:20; Ìṣípayá 12:9) Síwájú sí i, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé “irú ọmọ” kan máa ra aráyé pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. b (1 Jòhánù 3:8) Àwọn ìlérí wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì kan pé, ńṣe ni Ọlọ́run yóò mú àwọn ẹ̀dá rẹ̀ pa dà bọ̀ sípò, kò ní pa wọ́n run. Àmọ́, ìmúpadàbọ̀sípò yìí yóò gba àkókò.

2 Ayàwòrán ilé ní láti ya àwòrán bí iṣẹ́ àtúnṣe náà ṣe máa rí.

Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin, ó sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa kọ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n á ti máa jọ́sìn òun. Bíbélì sọ pé: “Nǹkan wọnnì jẹ́ òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀.” (Kólósè 2:17) Nítorí náà, òfin àti tẹ́ńpìlì dà bí àwòrán ìkọ́lé, wọ́n sì ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó tóbi jù.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi àwọn ẹran rúbọ láti lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Léfítíkù 17:11) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣàpẹẹrẹ ẹbọ ńlá kan tó máa wáyé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ẹbọ tó máa pèsè ìràpadà tòótọ́ fún aráyé. c Bí wọ́n ṣe ṣe àgọ́ ìjọsìn náà àti tẹ́ńpìlì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jọ́sìn jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí Mèsáyà yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú, láti ìgbà ikú ìrúbọ rẹ̀ títí dé ìgbà tí yóò gòkè re ọ̀run.—Wo àtẹ tó wà lójú ìwé 7.

3 A ní láti yan kọ́lékọ́lé tó máa fi àwòrán ilé náà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe náà.

Jésù ni Mèsáyà tá a ṣèlérí tó máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ irú èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rú, tá á sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti fi ra aráyé pa dà. Ìdí nìyẹn tí Jòhánù Oníbatisí fi pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29) Jésù gba iṣẹ́ náà tọkàntọkàn. Ó sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 6:38.

Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run fẹ́ kí Jésù “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” ó tún fẹ́ kó bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dá májẹ̀mú fún Ìjọba kan. (Mátíù 20:28; Lúùkù 22:29, 30) Ipasẹ̀ Ìjọba yìí ni Ọlọ́run fi máa mú ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé ṣẹ. “Ìhìn rere” là ń pe ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, nítorí pé ó ṣàlàyé pé Ọlọ́run ti gbé ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run láti máa ṣàkóso ọ̀ràn aráyé!—Mátíù 24:14; Dáníẹ́lì 2:44. d

Iṣẹ́ Àtúnṣe Náà Ń Bá A Nìṣó

Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́ . . . Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:19, 20.

Nítorí náà, mímú ọmọ aráyé pa dà bọ̀ sípò kò dópin nígbà tí Jésù kú. Yóò máa bá a lọ títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ìyẹn ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run á bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ayé. A ti wà nínú ìparí ètò àwọn nǹkan yẹn báyìí. Ìdí tí èyí fi dá wa lójú ni pé, ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa jẹ́ àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan” ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí. eMátíù 24:3-14; Lúùkù 21:7-11; 2 Tímótì 3:1-5.

Lóde òní, ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236], àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa pé, ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kódà, ìdí tá a fi tẹ ìwé ìròyìn yìí ni láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ̀ nípa Ìjọba náà àti ohun tó máa gbé ṣe. Ní ojú ìwé 2 ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá rí ìsọfúnni tó sọ nípa ìtẹ̀jáde yìí pé: “Ó ń fi ìhìn rere tu àwọn èèyàn nínú pé, láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣàkóso ní ọ̀run, yóò fòpin sí gbogbo ìwà ibi, á sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ìwé ìròyìn yìí ń gbani níyànjú láti nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ẹni tó kú nítorí ká lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun tó sì ti ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.”

Lóòótọ́, o ṣì lè máa gbọ́ nípa àwọn aṣekúpani tàbí àwọn àjálù, tàbí kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò bára dé ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì máa jẹ́ kó o mọ̀ pé Ọlọ́run kò fi aráyé sílẹ̀. Nítorí pé, “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Àti pé Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa dá ohun táwọn òbí wa gbé sọ nù ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pa dà.—Aísáyà 55:11.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn.

b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ka orí 19 ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe e.

c Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 5 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

d Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run, ka orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

e Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

“Ẹ̀da Ti Òtítọ́”—Ohun tí Àgọ́ Ìjọsìn Ṣàpẹẹrẹ

PẸPẸ

Ìfẹ́ Ọlọ́run láti tẹ́wọ́ gba ìrúbọ Jésù.—HÉBÉRÙ 13:10-12.

ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ

Jésù.—HÉBÉRÙ 9:11.

1 Lọ́jọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà máa ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn.—LÉFÍTÍKÙ 16:15, 29-31.

1 Ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí tiwa.—HÉBÉRÙ 10:5-10; 1 JÒHÁNÙ 2:1, 2.

IBI MÍMỌ́

Ipò Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tá a fi ẹ̀mí bí.—MÁTÍÙ 3:16, 17; RÓÒMÙ 8:14-17; HÉBÉRÙ 5:4-6.

AṢỌ ÌKÉLÉ

Ìyẹn ara tí Jésù ní nígbà tó wà láyé tí kò ṣeé gbé lọ sí ọ̀run.—1 KỌ́RÍŃTÌ 15:44, 50; HÉBÉRÙ 6:19, 20; 10:19, 20.

2 Àlùfáà àgbà yóò wá lọ sí òdì kejì aṣọ ìkélé tó pààlà sí Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.

2 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ‘ré aṣọ ìkélé kọjá’ ìyẹn ni pé ó lọ sí ọ̀run “láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.”—HÉBÉRÙ 9:24-28.

IBI MÍMỌ́ JÙ LỌ

Ọ̀run.—HÉBÉRÙ 9:24.

3 Nígbà tí àlùfáà àgbà bá ti dé inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, yóò wá wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹran tó fi rúbọ níwájú àpótí májẹ̀mú.—LÉFÍTÍKÙ 16:12-14.

3 Bí Jésù ṣe gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó ta sílẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó ṣe ètùtù tó tọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.—HÉBÉRÙ 9:12, 24; 1 PÉTÉRÙ 3:21, 22.