Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nígbà tí Jésù Kristi rán àwọn àpọ́sítélì méjìlá jáde láti lọ wàásù, ṣé ó sọ fún wọn pé kí wọ́n mú ọ̀pá, kí wọ́n sì wọ sálúbàtà?

Àwọn kan sọ pé ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́ta sọ nípa bí Jésù ṣe rán àwọn àpọ́sítélì jáde ta ko ara wọn. Àmọ́, tá a bá fi ohun táwọn ìwé náà sọ wé ara wọn, ohun tá a máa kíyè sí á wú wa lórí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, fi ohun tí Máàkù àti Lúùkù sọ wéra. Máàkù sọ pé: “[Jésù] pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn láti má ṣe gbé nǹkan kan dání fún ìrìnnà àjò náà àyàfi ọ̀pá nìkan, kí ó má ṣe sí búrẹ́dì, kí ó má ṣe sí àsùnwọ̀n oúnjẹ, kí ó má ṣe sí owó bàbà nínú àpò ara àmùrè wọn, ṣùgbọ́n kí wọ́n de sálúbàtà mọ́ ẹsẹ̀, kí wọ́n má sì wọ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì.” (Máàkù 6:7-9) Lúùkù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe gbé nǹkan kan dání fún ìrìnnà àjò náà, yálà ọ̀pá tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ, tàbí búrẹ́dì tàbí owó fàdákà; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ní ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì.” (Lúùkù 9:1-3) A lè kíyè sí i pé ibí yìí ṣe bí ẹní ta kora. Máàkù ní kí àwọn àpọ́sítélì yẹn mú ọ̀pá, kí wọ́n sì wọ sálúbàtà, àmọ́ Lúùkù ní wọn kò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun, títí kan ọ̀pá. Máàkù mẹ́nu kan sálúbàtà ṣùgbọ́n Lúùkù kò mẹ́nu kàn án ní tirẹ̀.

Ká bàa lè lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí, kíyè sí gbólóhùn tó fara hàn nínú ìwé Ìhìn Rere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kọ sókè yìí àti nínú Mátíù 10:5-10, Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì yẹn pé wọn kò gbọ́dọ̀ wọ “ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì,” wọn kò sì gbọ́dọ̀ ní in. Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì kọ̀ọ̀kan ti wọ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ kan ṣoṣo tó ní. Torí náà, wọn kò gbọ́dọ̀ mú òmíràn dání lọ sí ìrìn àjò náà. Bákan náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wọ sálúbàtà. Ìdí nìyẹn tí Máàkù fi sọ pé “kí wọ́n de sálúbàtà mọ́ ẹsẹ̀,” ìyẹn sálúbàtà tí wọ́n ti wọ̀ tẹ́lẹ̀. Ọ̀pá wá ńkọ́? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Jewish Encyclopedia sọ pé: “Ó jọ pé àṣà tó tún wọ́pọ̀ láàárín àwọn Hébérù ìgbàanì ni pé kí wọ́n máa mú ọ̀pá rìn.” (Jẹ́n. 32:10) Máàkù sọ pé kí àwọn àpọ́sítélì “má ṣe gbé nǹkan kan dání fún ìrìnnà àjò náà” àfi ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ wọn nígbà tí Jésù pàṣẹ yìí fún wọn. Torí náà, ohun tí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ń tẹnu mọ́ ni ìtọ́ni tí Jésù fún wọn pé kí wọ́n má ṣẹ̀ṣẹ̀ fi àkókò ṣòfò nípa lílọ ra àwọn nǹkan míì láfikún sí èyí tí wọ́n ti ní.

Mátíù wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀. Torí náà ó ṣeé ṣe fún un láti sọ̀rọ̀ síwájú sí i nípa kókó yìí. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣe wúrà tàbí fàdákà tàbí bàbà sínú àpò ara àmùrè yín, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ fún ìrìnnà àjò náà, tàbí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì, tàbí sálúbàtà tàbí ọ̀pá; nítorí òṣìṣẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀.” (Mát. 10:9, 10) Sálúbàtà tí àwọn àpọ́sítélì wọ̀ àti ọ̀pá tí wọ́n mú dání ńkọ́? Jésù kò sọ pé kí wọ́n kó èyí tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ dà nù, àmọ́ ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe wá irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tí Jésù fi pa irú àṣẹ yìí fún wọn? Ìdí ni pé “òṣìṣẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀.” Ohun tí àṣẹ Jésù dá lé lórí gan-an nìyẹn, èyí sì bá ọ̀rọ̀ ìyànjú tó sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè mu, nígbà tó sọ pé kí wọ́n má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohun tí wọ́n máa jẹ tàbí ohun tí wọ́n máa mu, tàbí ohun tí wọ́n máa wọ̀.—Mát. 6:25-32.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè kọ́kọ́ dà bíi pé àkọsílẹ̀ inú Ìhìn Rere ta kóra, ohun kan náà ni gbogbo wọn ń sọ. Ohun tó wà lọ́wọ́ àwọn àpọ́sítélì náà ni Jésù fẹ́ kí wọ́n mú dání lọ sẹ́nu iṣẹ́ tó rán wọn, wọn kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wíwá àwọn nǹkan míì pín ọkàn wọn níyà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà máa pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.

Àwọn wo ni “ọmọge, àní àwọn ọmọge” tí Sólómọ́nì ń sọ?—Oníw. 2:8.

A kò mọ àwọn tí Sólómọ́nì ń sọ, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ àwọn obìnrin olókìkí tí wọ́n wá sí ààfin Sólómọ́nì.

Nínú Oníwàásù orí 2 Sólómọ́nì sọ ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ohun tó ti gbé ṣe, títí kan àwọn ilé jàǹkànjàǹkàn tó kọ́. Ó fi kún un pé: “Mo tún kó fàdákà àti wúrà jọ rẹpẹtẹ fún ara mi, àti dúkìá tí ó jẹ́ àkànṣe ìní àwọn ọba àti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ. Mo kó àwọn ọkùnrin akọrin àti àwọn obìnrin akọrin jọ fún ara mi àti àwọn ohun tí ó jẹ́ inú dídùn kíkọyọyọ fún àwọn ọmọ aráyé, ọmọge, àní àwọn ọmọge.”—Oníw. 2:8.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì máa ń sọ pé “àwọn ọmọge” tí Sólómọ́nì ń sọ ni àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn wáhàrì tó kó jọ ní apá ìgbẹ̀yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn àwọn obìnrin tí wọ́n mú kó lọ́wọ́ sí ìsìn èké. (1 Ọba 11:1-4) Àmọ́, àlàyé yìí kò kúnná tó. Nígbà tí Sólómọ́nì kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, ó ti mọ̀ nípa “ọmọge, àní àwọn ọmọge” tó mẹ́nu kàn yìí. Síbẹ̀, ó ṣì ní ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, torí Ọlọ́run ń mí sí i láti kọ àwọn ìwé Bíbélì. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní apá ìgbẹ̀yìn ìgbésí ayé rẹ̀, lákòókò tó kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn wáhàrì jọ, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn èké.

Nínú Oníwàásù, Sólómọ́nì sọ pé òun “wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” (Oníw. 12:10) Ó ṣe kedere pé ó mọ ọ̀rọ̀ tó lè fi júwe “aya,” “ayaba” àti “wáhàrì,” torí pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nínú àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ. (Òwe 5:18; 12:4; 18:22; Oníw. 9:9; Orin Sól. 6:8, 9) Àmọ́, kò lo àwọn ọ̀rọ̀ tá a mọ̀ yẹn nínú Oníwàásù 2:8.

Nínú gbólóhùn náà “ọmọge, àní àwọn ọmọge,” a kíyè sí i pé ẹsẹ yìí nìkan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ Hébérù tó ṣàjèjì yìí (tá a lò fún ẹnì kan àti ẹni púpọ̀) ti fara hàn. Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé kò sí ẹni tó mọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Púpọ̀ lára àwọn atúmọ̀ Bíbélì gbà pé ọ̀rọ̀ inú Oníwàásù 2:8 ń tọ́ka sí obìnrin kan ṣoṣo àti lẹ́yìn náà ó tún lò ó lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n pọ̀ tàbí gẹ́gẹ́ bí èdè àpọ́nlé. Ohun tí gbólóhùn náà “ọmọge, àní àwọn ọmọge,” gbé wá síni lọ́kàn nìyẹn.

Sólómọ́nì gbajúmọ̀ débi pé ọbabìnrin kan láti ilẹ̀ ọba Ṣébà tí wọ́n ti ní ọrọ̀ púpọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, ó wá a wá, ohun tó rí sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (1 Ọba 10:1, 2) Ìyẹn tún jẹ́ ká rí ohun míì tó ṣeé ṣe kí èdè náà “ọmọge, àní àwọn ọmọge,” túmọ̀ sí. Ó ṣeé ṣe kó lò ó láti tọ́ka sí àwọn obìnrin olókìkí tí wọ́n wá sí ààfin rẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọdún tó fi gbádùn ojú rere Ọlọ́run.