Jẹ́nẹ́sísì 32:1-32

  • Àwọn áńgẹ́lì pàdé Jékọ́bù (1, 2)

  • Jékọ́bù múra láti pàdé Ísọ̀ (3-23)

  • Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì (24-32)

    • Orúkọ Jékọ́bù yí pa dà di Ísírẹ́lì (28)

32  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù ń bá tirẹ̀ lọ, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀.  Gbàrà tí Jékọ́bù rí wọn, ó sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run nìyí!” Torí náà, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Máhánáímù.*  Nígbà náà, Jékọ́bù ní kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ilẹ̀ Séírì,+ ní agbègbè* Édómù,+  ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Ísọ̀ olúwa mi nìyí, ‘Ohun tí Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ sọ nìyí: “Ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbé* lọ́dọ̀ Lábánì títí di báyìí.+  Mo ti ní àwọn akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin,+ mo sì ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi láti fi èyí tó o létí, kí n lè rí ojúure rẹ.”’”  Nígbà tó yá, àwọn ìránṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ Jékọ́bù, wọ́n sì sọ fún un pé: “A rí Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ, ó sì ti ń bọ̀ wá pàdé rẹ+ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.”  Ẹ̀rù wá ba Jékọ́bù gan-an, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀.+ Torí náà, ó pín àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ àtàwọn agbo ẹran, àwọn màlúù àtàwọn ràkúnmí, ó pín wọn sí ọ̀nà méjì.  Ó ní: “Bí Ísọ̀ bá gbéjà ko apá kan, apá kejì á lè sá lọ.”  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ pé: “Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá mi àti Ọlọ́run Ísákì bàbá mi, Jèhófà, ìwọ tí ò ń sọ fún mi pé, ‘Pa dà sí ilẹ̀ rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, màá sì ṣe dáadáa sí ọ,’+ 10  ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn àti bí o ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí ìránṣẹ́+ rẹ kò tọ́ sí mi, mi ò ní ju ọ̀pá kan ṣoṣo nígbà tí mo sọdá odò Jọ́dánì, àmọ́ mo ti wá di àgọ́ méjì+ báyìí. 11  Mo bẹ̀ ọ́,+ gbà mí lọ́wọ́ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi, torí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, ó lè wá gbógun ja èmi+ àti àwọn ọmọ mi pẹ̀lú àwọn ìyá wọn. 12  O sì ti sọ pé: ‘Ó dájú pé màá ṣe dáadáa sí ọ, màá sì mú kí àtọmọdọ́mọ* rẹ pọ̀ bí iyanrìn òkun, débi pé wọn ò ní lè kà wọ́n.’”+ 13  Ó wá sun ibẹ̀ mọ́jú. Ó sì mú ẹ̀bùn fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ látinú àwọn ohun ìní rẹ̀: 14  igba (200) abo ewúrẹ́, ogún (20) òbúkọ, igba (200) abo àgùntàn, ogún (20) àgbò, 15  ọgbọ̀n (30) ràkúnmí tó ń tọ́mọ, ogójì (40) màlúù, akọ màlúù mẹ́wàá, ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ mẹ́wàá tó ti dàgbà dáadáa. 16  Ó fà wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, agbo ẹran kan tẹ̀ lé òmíràn, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ sọdá, kí ẹ máa lọ níwájú mi, kí ẹ sì fi àyè sílẹ̀ láàárín agbo ẹran kan àti èyí tó tẹ̀ lé e.” 17  Ó tún pàṣẹ fún èyí tó ṣáájú pé: “Tí Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi bá pàdé rẹ, tó sì bi ọ́ pé, ‘Ta ni ọ̀gá rẹ, ibo lò ń lọ, ta ló sì ni àwọn ohun tó wà níwájú rẹ yìí?’ 18  kí o sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ni. Ẹ̀bùn yìí ló fi ránṣẹ́ sí Ísọ̀+ olúwa mi. Wò ó! Òun náà ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” 19  Ó sì pàṣẹ fún ẹnì kejì, ẹnì kẹta àti gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé agbo ẹran pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Ísọ̀ nìyẹn tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20  Kí ẹ tún sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” Torí ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Tí mo bá kọ́kọ́ fi ẹ̀bùn ránṣẹ́,+ tí mo fi wá ojúure rẹ̀, tí mo bá wá rí òun fúnra rẹ̀, bóyá ó lè tẹ́wọ́ gbà mí.’ 21  Wọ́n sì kó àwọn ẹ̀bùn náà sọdá ṣáájú rẹ̀, àmọ́ inú àgọ́ ni òun sùn. 22  Lóru ọjọ́ yẹn, ó dìde, ó mú àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì,+ àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ rẹ̀ méjèèjì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kànlá (11) tí wọ́n ṣì kéré, wọ́n sì gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò Jábókù+ sọdá. 23  Ó kó gbogbo wọn, ó mú wọn sọdá odò,* ó sì kó gbogbo ohun míì tó ní kọjá. 24  Níkẹyìn, ó ṣẹ́ ku Jékọ́bù nìkan. Ọkùnrin kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jìjàkadì títí ilẹ̀ fi mọ́.+ 25  Nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun ò borí, ó fọwọ́ kan egungun ìbàdí rẹ̀; egungun ìbàdí Jékọ́bù sì yẹ̀ nígbà tó ń bá a jìjàkadì.+ 26  Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé: “Jẹ́ kí n máa lọ, torí ilẹ̀ ti ń mọ́.” Àmọ́ ó fèsì pé: “Mi ò ní jẹ́ kí o lọ, àfi tí o bá súre fún mi.”+ 27  Ó wá bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Jékọ́bù.” 28  Ó wá sọ fún un pé: “O ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì*+ ni wàá máa jẹ́, torí o ti bá Ọlọ́run + àti èèyàn wọ̀jà, o sì ti wá borí.” 29  Ni Jékọ́bù bá sọ pé: “Jọ̀ọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Àmọ́ ó fèsì pé: “Kí nìdí tí o fi ń béèrè orúkọ mi?”+ Ó sì súre fún un níbẹ̀. 30  Torí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ ó dá ẹ̀mí* mi sí.”+ 31  Oòrùn wá yọ ní gbàrà tó kọjá Pénúélì,* àmọ́ ó ń tiro torí ohun tó ṣe ìbàdí+ rẹ̀. 32  Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé títí dòní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í jẹ iṣan tó wà níbi itan* ní oríkèé egungun ìbàdí, torí ó fọwọ́ kan iṣan tó wà níbi itan ní oríkèé egungun ìbàdí Jékọ́bù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Àgọ́ Méjì.”
Ní Héb., “pápá.”
Tàbí “gbé bí àjèjì.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “àfonífojì.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Bá Ọlọ́run Wọ̀jà” (“Ẹni Tó Rọ̀ Mọ́ Ọlọ́run”) tàbí “Ọlọ́run Wọ̀jà.”
Ó túmọ̀ sí “Ojú Ọlọ́run.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Péníélì.”
Ní Héb., “fọ́nrán iṣan tó wà níbi itan.”