Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí!

A Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí!

A Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí!

ǸJẸ́ àdánwò kan wà tó ò ń bá yí lọ́wọ́lọ́wọ́? Ṣé ọ̀rọ̀ náà kò ti sú ọ débi pé o ti ro ara rẹ pin? Ǹjẹ́ ìgbà míì wà tí ẹ̀rù máa ń bà ọ́ pé bóyá nìṣòro rẹ ò ti kọjá ti gbogbo èèyàn, àti pé bóyá lo lè rí ọ̀nà àbáyọ? Tó bá jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn, má ṣe bọkàn jẹ́! Àdánwò yòówù tí ì báà dé bá wa, Bíbélì mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí wọn.

Bíbélì sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò “bá onírúurú àdánwò pàdé.” (Jákọ́bù 1:2) Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà “onírúurú” tá a fi tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, poi·kiʹlos. Tá a bá wo bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí láyé ọjọ́un, ohun tó túmọ̀ sí ni “onírúurú nǹkan” tàbí “onírúurú àwọ̀,” ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tá a fi ń mọ̀ pé ‘àdánwò náà pín sí onírúurú ẹ̀ka.’ Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá sọ pé “onírúurú àdánwò” ó túmọ̀ sí pé àwọn àdánwò náà pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà. Bó sì ti wù kó rí, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí wọn níkọ̀ọ̀kan. Kí ló mú èyí dá wa lójú?

“Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run Tí A Fi Hàn ní Onírúurú Ọ̀nà”

Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé “a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá” àwọn Kristẹni. (1 Pétérù 1:6) Nínú lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí Pétérù láti kọ lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” ni “a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pétérù 4:10) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, poi·kiʹlos, tá a sọ lókè ni wọ́n túmọ̀ sí “ní onírúurú ọ̀nà” níbí. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lórí gbólóhùn yìí, ó ní: “Ọ̀rọ̀ ńlá gbáà lọ̀rọ̀ yẹn. . . . Níwọ̀n bí a ti pe oore ọ̀fẹ́ [tàbí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí] Ọlọ́run ní poikilos, ó túmọ̀ sí pé kò sí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ síni láyé yìí tí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ò ní lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí.” Ọ̀mọ̀wé náà tún sọ pé: “Kò sí ipò ìbànújẹ́ téèyàn lè wà, tàbí àjálù tó lè ṣẹlẹ̀, tàbí ipò pàjáwìrì téèyàn lè bá ara rẹ̀ tí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ò ní lè yanjú tàbí tí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ò ní lè borí. Kò sí ìṣòro kan láyé yìí tí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ò lè ṣẹ́gun. Ọ̀rọ̀ náà poikilos, tó gbé ìtumọ̀ yọ yìí, jẹ́ ká mọ̀ pé oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó wà ní onírúurú ọ̀nà lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da gbogbo nǹkan.”

Inú Rere Ń Jẹ́ Ká Lè Fara Da Àdánwò

Pétérù jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn jẹ́ nípasẹ̀ onírúurú èèyàn tó wà nínú ìjọ Kristẹni. (1 Pétérù 4:11) Olúkúlùkù ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló ní ẹ̀bùn tẹ̀mí tàbí agbára tẹ̀mí tó lè fi fún àwọn tó wà nínú àdánwò níṣìírí. (Róòmù 12:6-8) Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan wà nínú ìjọ tó jẹ́ pé wọ́n ta yọ tó bá di pé ká kọ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ olóye tí wọ́n ń sọ máa ń wú àwọn ẹlòmíràn lórí, ó sì máa ń mú kí wọ́n fẹ́ láti lo ìfaradà. (Nehemáyà 8:1-4, 8, 12) Àwọn mìíràn máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn déédéé sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Irú àwọn ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ máa ń fúnni níṣìírí, ó sì máa ń ‘tuni nínú.’ (Kólósè 2:2) Nígbà táwọn alábòójútó bá ṣe irú ìbẹ̀wò tó lè mú kí ìgbàgbọ́ lágbára bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn tẹ̀mí ló máa ń jẹ́ fáwọn tí wọ́n lọ bá. (Jòhánù 21:16) Síbẹ̀, àwọn kan wà nínú ìjọ tó jẹ́ pé wọ́n máa ń kó èèyàn mọ́ra, wọ́n ní ẹ̀mí ìyọ́nú, wọ́n sì ń fi ẹ̀mí jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó wà nínú ìṣòro lò. (Ìṣe 4:36; Róòmù 12:10; Kólósè 3:10) Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò táwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyí ní àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tí Ọlọ́run gbà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn.—Òwe 12:25; 17:17.

“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”

Paríparí rẹ̀ ni pé Jèhófà ń tù wá nínú. Òun ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti okun tí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń fún wa ni àwọn ọ̀nà pàtàkì tí Jèhófà gbà ń dá wa lóhùn nígbà tá a bá gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Aísáyà 30:18, 21; Lúùkù 11:13; Jòhánù 14:16) Ìṣírí ńlá ni ìlérí tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ jẹ́ fún wa. Ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.

Bẹ́ẹ̀ ni o, àdánwò tàbí ìṣòro yòówù ká ní, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run yóò jẹ́ ká lè borí wọn. (Jákọ́bù 1:17) Ìrànlọ́wọ́ tó máa ń bọ́ sákòókò tó sì máa ń bá a mu gẹ́ẹ́ tí Jèhófà ń ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láìka bí ìṣòro tàbí àdánwò wọn ṣe pọ̀ tó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń lo “ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n” rẹ̀. (Éfésù 3:10) Ǹjẹ́ o ò gbà bẹ́ẹ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àdánwò tá a bá ní