Nehemáyà 8:1-18

  • Wọ́n ka ìwé Òfin, wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn èèyàn (1-12)

  • Wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà (13-18)

8  Gbogbo àwọn èèyàn náà kóra jọ ní ìṣọ̀kan sí gbàgede ìlú tó wà níwájú Ẹnubodè Omi,+ wọ́n sì sọ fún Ẹ́sírà+ adàwékọ* pé kó mú ìwé Òfin Mósè+ wá, èyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.+  Torí náà, ní ọjọ́ kìíní oṣù keje,+ àlùfáà Ẹ́sírà mú ìwé Òfin náà wá síwájú àpéjọ*+ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin pẹ̀lú gbogbo àwọn tó lè lóye ohun tí wọ́n bá gbọ́.  Ó sì kà á sókè+ ní gbàgede ìlú tó wà níwájú Ẹnubodè Omi, láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọ̀sán gangan, fún àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà lè yé; gbogbo àwọn èèyàn náà sì fetí sílẹ̀ dáadáa+ sí ìwé Òfin náà.  Ẹ́sírà adàwékọ* dúró lórí pèpéle onígi tí wọ́n ṣe fún àpéjọ náà; àwọn tó dúró sápá ọ̀tún rẹ̀ ni Matitáyà, Ṣímà, Ánáyà, Ùráyà, Hilikáyà àti Maaseáyà; àwọn tó sì wà lápá òsì rẹ̀ ni Pedáyà, Míṣáẹ́lì, Málíkíjà,+ Háṣúmù, Haṣi-bádánà, Sekaráyà àti Méṣúlámù.  Ẹ́sírà ṣí ìwé náà lójú gbogbo èèyàn, nítorí ó yọ sókè ju gbogbo wọn lọ. Bí ó sì ṣe ṣí i, gbogbo àwọn èèyàn náà dìde.  Nígbà náà, Ẹ́sírà yin Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, gbogbo àwọn èèyàn náà sọ pé, “Àmín!* Àmín!”+ wọ́n sì gbé ọwọ́ wọn sókè. Wọ́n tẹrí ba, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀ fún Jèhófà.  Jéṣúà, Bánì, Ṣerebáyà,+ Jámínì, Ákúbù, Ṣábétáì, Hodáyà, Maaseáyà, Kélítà, Asaráyà, Jósábádì,+ Hánánì àti Pẹláyà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, ń ṣàlàyé Òfin náà fún àwọn èèyàn náà,+ orí ìdúró sì ni àwọn èèyàn náà wà.  Wọ́n ń ka ìwé náà sókè nìṣó látinú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀; torí náà, wọ́n jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lóye ohun tí wọ́n kà.+  Nehemáyà tó jẹ́ gómìnà* nígbà yẹn, Ẹ́sírà + tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ* pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Ẹ má ṣọ̀fọ̀, ẹ má sì sunkún.” Nítorí gbogbo àwọn èèyàn náà ń sunkún bí wọ́n ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Òfin náà. 10  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun tó dọ́ṣọ̀,* ẹ mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ránṣẹ́+ sí àwọn tí kò ní nǹkan kan; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì banú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni ibi ààbò* yín.” 11  Àwọn ọmọ Léfì sì ń fi gbogbo àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ dákẹ́! nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́; ẹ má sì banú jẹ́.” 12  Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu, wọ́n fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí àwọn míì, inú wọn sì ń dùn gan-an,+ nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn.+ 13  Ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí agbo ilé gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kóra jọ sọ́dọ̀ Ẹ́sírà adàwékọ,* kí wọ́n lè túbọ̀ lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin náà. 14  Wọ́n wá rí i nínú Òfin pé Jèhófà pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé inú àtíbàbà ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé nígbà àjọyọ̀ ní oṣù keje+ 15  àti pé kí wọ́n polongo,+ kí wọ́n sì kéde káàkiri gbogbo ìlú wọn àti ní gbogbo Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ lọ sí àwọn agbègbè olókè, kí ẹ sì mú ẹ̀ka eléwé igi ólífì, ti igi ahóyaya, ti igi mátílì àti imọ̀ ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹ̀ka àwọn igi míì tó léwé dáadáa wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀.” 16  Ni àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó wọn wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà fún ara wọn, kálukú sórí òrùlé rẹ̀ àti sí àgbàlá wọn àti àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ bákan náà, wọ́n ṣe é sí gbàgede ìlú ní Ẹnubodè Omi+ àti gbàgede ìlú tó wà ní Ẹnubodè Éfúrémù.+ 17  Bí gbogbo àwùjọ* àwọn tó dé láti ìgbèkùn ṣe ṣe àwọn àtíbàbà nìyẹn, wọ́n sì ń gbé inú àwọn àtíbàbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe é báyìí rí láti ìgbà ayé Jóṣúà+ ọmọ Núnì títí di ọjọ́ yẹn, ìdí nìyẹn tí ìdùnnú fi ṣubú layọ̀ láàárín wọn.+ 18  Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ka ìwé Òfin Ọlọ́run tòótọ́,+ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di ọjọ́ tó kẹ́yìn. Wọ́n sì fi ọjọ́ méje ṣe àjọyọ̀ náà, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “akọ̀wé òfin.”
Tàbí “ìjọ.”
Tàbí “akọ̀wé òfin.”
Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí.”
Tàbí “akọ̀wé òfin.”
Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.
Ní Héb., “ohun tó lọ́ràá.”
Tàbí “agbára.”
Tàbí “akọ̀wé òfin.”
Tàbí “ìjọ.”