Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Sámúẹ́lì Kejì

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Sámúẹ́lì Kejì

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Sámúẹ́lì Kejì

ǸJẸ́ ó pọn dandan pé ká jẹ́ onígbọràn tí kì í ṣàṣìṣe rárá ká tó lè fi hàn pé a gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run? Ṣé gbogbo ìgbà ni olóòótọ́ èèyàn lè máa ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run? Irú èèyàn wo ni “ó tẹ́ ọkàn-àyà [Ọlọ́run tòótọ́] lọ́rùn”? (1 Sámúẹ́lì 13:14) Ọ̀nà tí Sámúẹ́lì Kejì gbà dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn tuni lára gan-an ni.

Wòlíì Gádì àti wòlíì Nátánì ló kọ ìwé Sámúẹ́lì Kejì, àwọn méjèèjì sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. a Nǹkan bí ọdún 1040 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ ìwé náà tán, ìyẹn lákòókò tí ogójì ọdún tí Dáfídì fi jọba ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Ọ̀rọ̀ nípa Dáfídì àti àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà ló pọ̀ jù nínú ìwé náà. Ìtàn tó ń wúni lórí tó wà nínú ìwé náà sọ bí orílẹ̀-èdè kan tí ìjà pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ṣe padà wà níṣọ̀kan tí wọ́n sì láásìkí lábẹ́ ìjọba ọkùnrin kan tó jẹ́ akíkanjú. Téèyàn bá ń ka ìtàn tó wà nínú ìwé náà, kò ní fẹ́ gbé e sílẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé èèyàn wà níbi tóhun tó ń kà ti ṣẹlẹ̀ gan-an.

DÁFÍDÌ Ń “PỌ̀ SÍ I ṢÁÁ”

(2 Sámúẹ́lì 1:1–10:19)

Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì kú, ohun tó ṣe fi hàn pé ó dùn ún gan-an ni, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó. Wọ́n fi Dáfídì jẹ ọba lórí ẹ̀yà Júdà ní Hébúrónì. Iṣi-bóṣẹ́tì ọmọ Sọ́ọ̀lù sì di ọba lórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì yòókù. Dáfídì wá bẹ̀rẹ̀ sí í “pọ̀ sí i ṣáá” débi pé nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún méje ààbọ̀, Dáfídì di ọba lórí gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì pátá.—2 Sámúẹ́lì 5:10.

Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Jébúsì, ó gba Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ wọn, ó sì fi í ṣe olú ìlú ìjọba rẹ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Dáfídì ní kóun gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerúsálẹ́mù, àjálù ló já sí fún un. Àmọ́, ó ṣàṣeyọrí lẹ́ẹ̀kejì, ló bá ń jo ijó ayọ̀. Jèhófà bá Dáfídì dá májẹ̀mú pé òun máa gbé ìjọba kan lé e lọ́wọ́. Dáfídì ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ọlọ́run kò sì fi í sílẹ̀.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

2:18—Kí nìdí tí ẹsẹ Bíbélì yìí fi pe Jóábù àtàwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní àwọn ọmọkùnrin Seruáyà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nígbà tó jẹ́ pé ìyá wọn ni Seruáyà jẹ́? Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, àtọ̀dọ̀ bàbá ni wọ́n ti sábà máa ń tọpasẹ̀ orúkọ àwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ ìtàn ìdílé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni ọkọ Seruáyà ṣẹ́kú tàbí pé kò yẹ lẹ́ni tí wọ́n lè fi orúkọ rẹ̀ sínú Ìwé Mímọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọlá pé Seruáyà jẹ́ ọmọ ìyá kan náà pẹ̀lú Dáfídì ni wọ́n ṣe dá orúkọ rẹ̀ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. (1 Kíróníkà 2:15, 16) Ibì kan ṣoṣo tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa bàbá àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò mẹ́ta náà jẹ́ ìgbà tó sọ̀rọ̀ nípa ibi tí wọ́n sìnkú rẹ̀ sí, ìyẹn ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.—2 Sámúẹ́lì 2:32.

3:29—Kí ni gbólóhùn náà “ọkùnrin tí ń di ìrànwú ayíbíríbírí mú” túmọ̀ sí? Àwọn obìnrin ló sábà máa ń hun aṣọ. Nítorí náà, ó lè jẹ́ pé àwọn ọkùnrin tí wọn ò lẹ́mìí ogun jíjà, tó jẹ́ pé iṣẹ́ táwọn obìnrin sábà máa ń ṣe ni wọ́n lè ṣe ni gbólóhùn yẹn ń tọ́ka sí.

5:1, 2—Ó tó ọdún mélòó lẹ́yìn tí wọ́n pa Iṣi-bóṣẹ́tì kí wọ́n tó fi Dáfídì jẹ ọba lórí gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì? Ó bọ́gbọ́n mu tá a bá sọ pé ọdún méjì tí Iṣi-bóṣẹ́tì lò lórí àlééfà bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn ikú Sọ́ọ̀lù. Èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí àkókò kan náà tí Dáfídì di ọba ní Hébúrónì. Ọdún méje ààbọ̀ ni Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì tó sì ń tibẹ̀ ṣàkóso lórí gbogbo Júdà. Kò pẹ́ tí wọ́n fi Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ló gbé olú ìlú ìjọba rẹ̀ kúrò ní Hébúrónì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, ó tó nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn ikú Iṣi-bóṣẹ́tì kí Dáfídì tó di ọba gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì.—2 Sámúẹ́lì 2:3, 4, 8-11; 5:4, 5.

8:2—Mélòó làwọn ọmọ Móábù tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣá balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wọn jagun? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi nǹkan kan díwọ̀n òkú wọn dípò kí wọ́n ka iye wọn níkọ̀ọ̀kan. Ó jọ pé ńṣe ni Dáfídì mú káwọn ọmọ Móábù dùbúlẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá fi okùn kan díwọ̀n wọn. Ó hàn gbangba pé, ìwọ̀n okùn méjì tàbí ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọ Móábù ni wọ́n pa, ìwọ̀n okùn kan tàbí ìdá kan nínú mẹ́ta ni wọ́n sì dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

2:1; 5:19, 23. Kí Dáfídì tó lọ máa gbé ní Hébúrónì, ó kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ohun kan náà ló ṣe kó tó lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà. Èyí kọ́ wa pé káwa náà tó ṣe ìpinnu èyíkéyìí tó kan ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, ó yẹ ká kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà.

3:26-30. Téèyàn bá ń gbẹ̀san, ó lè kóni síyọnu.—Róòmù 12:17-19.

3:31-34; 4:9-12. Dáfídì jẹ́ ẹnì kan tí kì í gbẹ̀san, kì í sì í fi èèyàn sínú. Ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

5:12. Kò yẹ ká gbàgbé pé Jèhófà ti kọ́ wa ní àwọn ohun tó fẹ́, ó sì tún jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀.

6:1-7. Ohun tó dára ló wà lọ́kàn Dáfídì tó fi lọ gbé Àpótí Májẹ̀mú, àmọ́ gbígbé tó gbé àpótí náà sórí kẹ̀kẹ́ kó bá bí Ọlọ́run ṣe ní kí wọ́n máa gbé e mu, èyí sì kó Dáfídì síyọnu. (Ẹ́kísódù 25:13, 14; Númérì 4:15, 19; 7:7-9) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úsà nígbà tó di àpótí náà mu jẹ́ ká mọ̀ pé béèyàn tiẹ̀ ní ohun tó dára lọ́kàn, ìyẹn ò ní kí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe yí padà.

6:8, 9. Nígbà tí ohun ìbànújẹ́ kan ṣẹlẹ̀, inú kọ́kọ́ bí Dáfídì, ẹ̀rù tún bà á, àfàìmọ̀ kó má tiẹ̀ di ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ru Jèhófà. Ó yẹ káwa náà ṣọ́ra, ká má lọ máa dá Jèhófà lẹ́bi nítorí ìṣòro tá a ní torí pe a ò pa òfin rẹ̀ mọ́.

7:18, 22, 23, 26. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Dáfídì, tọkàntọkàn ló fi ń sin Jèhófà, bó sì ṣe máa gbé orúkọ Ọlọ́run lárugẹ ló ń jẹ ẹ́ lọ́kàn nígbà gbogbo. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé.

8:2. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu Báláámù sọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn ṣẹ. (Númérì 24:17) Èyí jẹ́ ká rí i pé Awímáyẹhùn ni Jèhófà.

9:1, 6, 7. Dáfídì ṣe ìlérí, ó sì mú un ṣẹ. Ó yẹ káwa náà gbìyànjú láti máa mú ìlérí wa ṣẹ.

JÈHÓFÀ GBÉ ÌYỌNU ÀJÁLÙ DÌDE SÍ ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ RẸ̀

(2 Sámúẹ́lì 11:1–20:26)

Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Kíyè sí i, èmi yóò gbé ìyọnu àjálù dìde sí ọ láti inú ilé rẹ; dájúdájú, èmi yóò sì gba àwọn aya rẹ ní ojú rẹ, èmi yóò sì fi wọ́n fún ọmọnìkejì rẹ, òun yóò sì sùn ti àwọn aya rẹ dájúdájú ní ojú oòrùn yìí.” (2 Sámúẹ́lì 12:11) Kí ló mú kí Jèhófà sọ pé irú nǹkan báyìí máa ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì? Ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì àti Bátí-ṣébà jọ dá ló fà á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dárí ji Dáfídì nígbà tó ronú pìwà dà, síbẹ̀ ó ṣì forí fá ohun tó tìdí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá náà jáde.

Àjálù àkọ́kọ́ ni pé ọmọ tí Bátí-ṣébà bí kú. Lẹ́yìn ìyẹn, Ámínónì fipá bá Támárì àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ wúńdíá, tí ìyá ọ̀tọ̀ bí fún Dáfídì, dàpọ̀. Ábúsálómù, ẹ̀gbọ́n Támárì, tí òun àti Támárì jọ jẹ́ ọmọ ìyá ọmọ bàbá ṣekú pa Ámínónì láti gbẹ̀san ohun tó ṣe yẹn. Ábúsálómù ṣọ̀tẹ̀ sí bàbá rẹ̀, ó sì lọ kéde ara rẹ̀ ní Hébúrónì pé òun lọba. Ni Dáfídì bá sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Ábúsálómù ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú mẹ́wàá lára àwọn wáhàrì tí bàbá rẹ̀ fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ilé. Ẹ̀yìn ìgbà tí Ábúsálómù kú ni Dáfídì tó padà sí ààfin. Ọ̀tẹ̀ tí Ṣébà tó wá látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì dì ṣekú pa á.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

14:7—Kí ni gbólóhùn náà “ìpọ́nyòò èédú mi” ṣàpẹẹrẹ? Ìpọ́nyòò èédú tó rọra ń jó ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ ẹni tí ń bẹ láàyè.

19:29—Nígbà tí Mefibóṣẹ́tì ṣàlàyé bí ọ̀ràn ṣe jẹ́ fún Dáfídì, kí nìdí tí Dáfídì fi dá a lóhùn lọ́nà tó gbà dá a lóhùn? Nígbà tí Mefibóṣẹ́tì ṣàlàyé ara rẹ̀ tán, ó ṣeé ṣe kí Dáfídì ti rí i pé kò dáa bí òun kàn ṣe gba ọ̀rọ̀ Síbà gbọ́ láìṣe ìwádìí kankan. (2 Sámúẹ́lì 16:1-4; 19:24-28) Ó lè jẹ́ pé ohun tó dun Dáfídì nìyẹn tí kò fi fẹ́ gbọ́ àlàyé kankan mọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

11:2-15. Bí Bíbélì ṣe sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì láìfi ìkankan bò jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ni Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

11:16-27. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá kan, kò yẹ ká bo ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún mọ́lẹ̀ bí Dáfídì ṣe ṣe. Dípò ìyẹn, ńṣe ló yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà, ká sì lọ bá àwọn alàgbà ìjọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́.—Òwe 28:13; Jákọ́bù 5:13-16.

12:1-14. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Nátánì fi lélẹ̀ fáwọn alàgbà ìjọ láti tẹ̀ lé. Ojúṣe wọn ni láti ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tún ìwà wọn ṣe. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi òye ṣe iṣẹ́ ọ̀hún.

12:15-23. Dáfídì ní èrò tó tọ̀nà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ìyẹn ni kò jẹ́ kó bara jẹ́ púpọ̀.

15:12; 16:15, 21, 23. Nígbà tí Áhítófẹ́lì tó máa ń fúnni nímọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání rí i pé ó dà bí ẹni pé ipò ọba máa bọ́ sí Ábúsálómù lọ́wọ́, ìgbéraga àti ìfẹ́ láti dé ipò ọlá mú kó di ọlọ̀tẹ̀. Èyí fi hàn pé tí ẹnì kan bá gbọ́n féfé àmọ́ tí kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí kò sì jẹ́ adúróṣinṣin, onítọ̀hún lè jìn sí ọ̀fìn.

19:24, 30. Mefibóṣẹ́tì mọrírì inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Dáfídì ṣe sí i. Èyí ló mú kó fara mọ́ gbogbo ohun tí Dáfídì ọba sọ nípa Síbà. Ó yẹ kí ìmọrírì tá a ní fún Jèhófà àti ètò rẹ̀ mú ká fara mọ́ gbogbo ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe.

20:21, 22. Ìwà ọgbọ́n tẹ́nì kan bá hù lè kó ọ̀pọ̀ èèyàn yọ nínú àjálù ńlá.—Oníwàásù 9:14, 15.

Ẹ JẸ́ KÁ ṢUBÚ “SÍ ỌWỌ́ JÈHÓFÀ”

(2 Sámúẹ́lì 21:1–24:25)

Ìyàn mú fún odindi ọdún mẹ́ta nítorí àwọn ará Gíbéónì tí Sọ́ọ̀lù pa. (Jóṣúà 9:15) Kí àwọn ará Gíbéónì sì lè gbẹ̀san ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe yìí, wọ́n ní kí Dáfídì fa àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù méje lé àwọn lọ́wọ́ láti pa wọ́n. Dáfídì fa àwọn ọmọ méje náà lé àwọn ará Gíbéónì lọ́wọ́, ni ọ̀dá náà bá kásẹ̀ nílẹ̀, òjò ńlá kan sì wá rọ̀. Àwọn ọmọ Filísínì mẹ́rin tó jẹ́ òmìrán ló “ṣubú nípa ọwọ́ Dáfídì àti nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”—2 Sámúẹ́lì 21:22.

Dáfídì lọ ka àwọn èèyàn, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì lohun tó ṣe yẹn. Ó ronú pìwà dà, ó sì gbà láti ṣubú sí “ọwọ́ Jèhófà.” (2 Sámúẹ́lì 24:14) Ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá yìí mú kí àjàkálẹ̀ àrùn pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000] èèyàn. Dáfídì ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, àrùn náà sì kásẹ̀ nílẹ̀.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:

21:8—Kí nìdí tí ẹsẹ Bíbélì yìí fi sọ pé Míkálì ọmọ Sọ́ọ̀lù ní ọmọkùnrin márùn-ún, nígbà tí 2 Sámúẹ́lì 6:23 sọ pé kò lọ́mọ kankan títí dọjọ́ ikú rẹ̀? Ìdáhùn tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn fara mọ́ ni pé ẹ̀gbọ́n Míkálì tó ń jẹ́ Mérábù, tí í ṣe ìyàwó Ádíríélì, ló bí àwọn ọmọ náà. Ó jọ pé Mérábù ò tíì dàgbà púpọ̀ tó fi kú, Míkálì sì wá tọ́jú àwọn ọmọ náà dàgbà torí pé òun ò bímọ kankan.

21:9, 10—Báwo ni àkókò tí Rísípà fi ṣọ́ òkú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì àtàwọn ọmọ ọmọ Sọ́ọ̀lù márùn-ún táwọn ará Gíbéónì pa ṣe gùn tó? “Ọjọ́ àkọ́kọ́ ìkórè,” ìyẹn oṣù March tàbí April, làwọn ará Gíbéónì gbé òkú àwọn méjèèje kọ́. Wọ́n fi òkú àwọn ọmọkùnrin náà sílẹ̀ sórí òkè kan láìfi nǹkan kan bò ó. Tọ̀sántòru ni Rísípà fi ń ṣọ́ òkú wọn títí Jèhófà fi mú kí ọ̀dá náà kásẹ̀ nílẹ̀ láti fi hàn pé òun ò bínú mọ́. Ó dà bí ẹni pé òjò ńlá kankan ò rọ̀ láàárín àkókò tó fi ń ṣọ́ àwọn òkú yìí títí dìgbà tí wọ́n máa kórè oko tán ní oṣù October. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó tó oṣù márùn-ún sí mẹ́fà tí Rísípà fi ṣọ́ òkú àwọn ọmọkùnrin náà. Lẹ́yìn ìyẹn, Dáfídì rán àwọn kan pé kí wọ́n lọ sin egungun òkú àwọn ọmọkùnrin náà.

24:1—Kí ló mú kí ètò ìkànìyàn tí Dáfídì ṣe di ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sí i lọ́rùn? Òfin Mósè ò sọ pé ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láti ka èèyàn. (Númérì 1:1-3; 26:1-4) Bíbélì ò sì sọ ohun tó mú kí Dáfídì ka àwọn èèyàn náà. Àmọ́, 1 Kíróníkà 21:1 fi hàn pé Sátánì ló ti Dáfídì. Bó ti wù kó rí, Jóábù tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun Dáfídì mọ̀ pé kíkà tí Dáfídì fẹ́ ka àwọn èèyàn náà kò tọ̀nà, ó sì gbìyànjú láti dá a dúró kó má bàa ka àwọn èèyàn náà.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

22:2-51. Àwọn orin tí Dáfídì kọ gbé Jèhófà ga gan-an pé òun ni Ọlọ́run tòótọ́ tó yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé!

23:15-17. Dáfídì ka òfin Ọlọ́run nípa ẹ̀mí èèyàn àti ẹ̀jẹ̀ sí pàtàkì gan-an débi pé nínú ohun tí Bíbélì ròyìn pé ó ṣẹlẹ̀ yìí, Dáfídì ò ṣe ohun tó tiẹ̀ sún mọ́ rírú òfin Ọlọ́run yẹn. Bó ṣe yẹ káwa náà ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nípa gbogbo òfin Ọlọ́run.

24:10. Ẹ̀rí ọkàn Dáfídì mú kó ronú pìwà dà. Ǹjẹ́ ẹ̀rí ọkàn wa ń ṣiṣẹ́ dáadáa débi tó fi máa mú ká ṣe bíi ti Dáfídì?

24:14. Dáfídì mọ̀ dájú pé àánú Jèhófà ju tèèyàn lọ fíìfíì. Ǹjẹ́ àwa náà mọ̀ bẹ́ẹ̀?

24:17. Dáfídì kábàámọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó fi kó odindi orílẹ̀-èdè sínú ìyà. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ronú pìwà dà, ó yẹ kó dùn ún dọ́kàn pé ẹ̀ṣẹ̀ òun kó ẹ̀gàn bá ìjọ.

A Lè Dẹni Tó ‘Tẹ́ Ọkàn-Àyà Ọlọ́run Lọ́rùn’

Ọba kejì ní Ísírẹ́lì ‘tẹ́ ọkàn-àyà Jèhófà lọ́rùn.’ (1 Sámúẹ́lì 13:14) Dáfídì ò ṣiyèméjì rí láé pé bóyá làwọn ìlànà Jèhófà tọ̀nà, kò sì gbé ìgbésí ayé lọ́nà tó fi hàn pé kò fẹ́ kí Ọlọ́run darí òun. Gbogbo ìgbà tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ ló mọ ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, ó gba ìbáwí, ó sì tún ìwà rẹ̀ ṣe. Olóòótọ́ èèyàn ni Dáfídì. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé ká dà bíi rẹ̀, pàápàá nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀?

Ìtàn ìgbésí ayé Dáfídì fi hàn pé tá a bá ní a gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, a ní láti máa ṣe ohun tó sọ pé ó dára ká sì yàgò fáwọn ohun tó sọ pé kò dára, ká sì tún gbìyànjú láti jẹ́ oníwà títọ́. Àwọn nǹkan tá a sọ yìí ò kọjá agbára wa. A mà dúpẹ́ o fún àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí tá a rí kọ́ nínú ìwé Sámúẹ́lì Kejì! Dájúdájú, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú ìwé Sámúẹ́lì Kejì yè, ó sì ń sa agbára.—Hébérù 4:12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Sámúẹ́lì ò kọ lára Sámúẹ́lì Kejì, àmọ́ orúkọ ẹ̀ ni wọ́n fi pe ìwé náà, nítorí pé inú àkájọ ìwé kan náà ni Sámúẹ́lì Kìíní àti Sámúẹ́lì Kejì wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ti ìjímìjí. Àmọ́ ṣá o, Sámúẹ́lì ló kọ èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìwé Sámúẹ́lì Kìíní.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Bí Dáfídì ò ṣe gbàgbé ẹni tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ipò ọba mú kó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

“Kíyè sí i, èmi yóò gbé ìyọnu àjálù dìde sí ọ láti inú ilé rẹ”

Bátí-ṣébà

Támárì

Ámínónì