Sámúẹ́lì Kejì 15:1-37

  • Ọ̀tẹ̀ àti rìkíṣí tí Ábúsálómù dì (1-12)

  • Dáfídì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù (13-30)

  • Áhítófẹ́lì dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù (31)

  • Ọba rán Húṣáì láti ta ko Áhítófẹ́lì (32-37)

15  Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, Ábúsálómù ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, ó kó àwọn ẹṣin jọ pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+  Ábúsálómù máa ń dìde láàárọ̀ kùtù, á sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tó lọ sí ẹnubodè ìlú.+ Nígbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní ẹjọ́ tó ń gbé bọ̀ lọ́dọ̀ ọba,+ Ábúsálómù á pè é, á sì sọ pé: “Ìlú wo lo ti wá?” onítọ̀hún á sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ rẹ ti wá.”  Ábúsálómù á wá sọ fún un pé: “Wò ó, ẹjọ́ rẹ dára, ó sì tọ́, àmọ́ kò sí ẹnì kankan láti ọ̀dọ̀ ọba tó máa fetí sí ọ.”  Ábúsálómù á tún sọ pé: “Ká ní wọ́n yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni! Nígbà náà, gbogbo ẹni tó ní ẹjọ́ tàbí tó ń wá ìdájọ́ á lè wá sọ́dọ̀ mi, màá sì rí i pé mo dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́.”  Nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ Ábúsálómù kí ó lè tẹrí ba fún un, Ábúsálómù á na ọwọ́ rẹ̀, á gbá a mú, á sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+  Ohun tí Ábúsálómù máa ń ṣe sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó gbé ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba nìyẹn; torí náà, Ábúsálómù ń dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra.*+  Nígbà tí ọdún mẹ́rin* parí, Ábúsálómù sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí Hébúrónì,+ kí n lè lọ san ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà.  Nítorí ìránṣẹ́ rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ ńlá kan+ nígbà tí mò ń gbé ní Géṣúrì+ ní Síríà pé: ‘Tí Jèhófà bá mú mi pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù, màá rúbọ sí* Jèhófà.’”  Torí náà, ọba sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ló bá gbéra, ó sì lọ sí Hébúrónì. 10  Ábúsálómù wá rán àwọn amí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé: “Gbàrà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ kéde pé, ‘Ábúsálómù ti di ọba ní Hébúrónì!’”+ 11  Nígbà náà, igba (200) ọkùnrin tẹ̀ lé Ábúsálómù lọ láti Jerúsálẹ́mù; ó pè wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé e láìfura, wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 12  Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí ó rú àwọn ẹbọ náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Áhítófẹ́lì+ ará Gílò, agbani-nímọ̀ràn*+ Dáfídì, láti Gílò+ ìlú rẹ̀. Ọ̀tẹ̀ náà ń gbilẹ̀ sí i, àwọn tó sì wà lẹ́yìn Ábúsálómù ń pọ̀ sí i.+ 13  Nígbà tó yá, ẹnì kan wá yọ́ ọ̀rọ̀ sọ fún Dáfídì pé: “Ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti yí sọ́dọ̀ Ábúsálómù.” 14  Ní kíá, Dáfídì sọ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a sá lọ,+ nítorí kò sí ìkankan lára wa tó máa bọ́ lọ́wọ́ Ábúsálómù! Ẹ ṣe kíá, kí ó má bàa yára lé wa bá, kí ó mú àjálù bá wa, kí ó sì fi idà pa ìlú yìí!”+ 15  Àwọn ìránṣẹ́ ọba sọ fún ọba pé: “Ohunkóhun tí olúwa wa ọba bá sọ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ṣe tán láti ṣe.”+ 16  Nítorí náà, ọba jáde, gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀ lé e, àmọ́ ọba ní kí àwọn wáhàrì*+ mẹ́wàá dúró láti máa tọ́jú ilé. 17  Ọba ń bá ìrìn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn èèyàn náà ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì dúró ní Bẹti-méhákì. 18  Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ kúrò* àti gbogbo àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti àwọn ará Gátì,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń kọjá bí ọba ti ń yẹ̀ wọ́n wò.* 19  Nígbà náà, ọba sọ fún Ítáì+ ará Gátì pé: “Kí ló dé tí ìwọ náà fi fẹ́ bá wa lọ? Pa dà, kí o sì lọ máa gbé pẹ̀lú ọba tuntun, nítorí àjèjì ni ọ́, ńṣe ni o sì sá kúrò ní ìlú rẹ. 20  Kò tíì pẹ́ tí o dé, ṣé kí n wá sọ pé kí o máa bá wa rìn káàkiri lónìí, láti lọ síbi tí mo bá ń lọ nígbà tí mo bá ń lọ? Pa dà, ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ, kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́+ hàn sí ọ!” 21  Ṣùgbọ́n Ítáì dá ọba lóhùn pé: “Bí Jèhófà àti olúwa mi ọba ti wà láàyè, ibikíbi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!”+ 22  Dáfídì bá sọ fún Ítáì+ pé: “Ó yá sọdá.” Nítorí náà, Ítáì ará Gátì sọdá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin àti àwọn ọmọ tó wà pẹ̀lú rẹ̀. 23  Gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń sunkún kíkankíkan nígbà tí àwọn èèyàn náà ń sọdá, ọba sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Kídírónì;+ gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sọdá sójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù. 24  Sádókù+ wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n ru àpótí+ májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́; wọ́n sì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ kalẹ̀; Ábíátárì+ náà wà níbẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn èèyàn náà sọdá láti inú ìlú náà. 25  Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Sádókù pé: “Gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sínú ìlú.+ Tí Jèhófà bá ṣojú rere sí mi, á mú mi pa dà, á tún jẹ́ kí n rí i àti ibi tó máa ń wà.+ 26  Àmọ́ tí ó bá sọ pé, ‘Inú mi ò dùn sí ọ,’ nígbà náà, kí ó ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀ sí mi.” 27  Ọba wá sọ fún àlùfáà Sádókù pé: “Ṣebí aríran+ ni ọ́? Pa dà sínú ìlú ní àlàáfíà, kí o mú àwọn ọmọ yín méjèèjì dání, Áhímáásì ọmọ rẹ àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì. 28  Wò ó, màá dúró ní ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò aginjù, títí màá fi rí ẹni tí wàá ní kí ó wá jíṣẹ́ fún mi.”+ 29  Torí náà, Sádókù àti Ábíátárì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbẹ̀. 30  Bí Dáfídì ṣe ń gun Òkè* Ólífì,+ ó ń sunkún bí ó ṣe ń gòkè lọ; ó bo orí rẹ̀, ó sì ń rìn lọ láìwọ bàtà. Gbogbo àwọn èèyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà bo orí wọn, wọ́n sì ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ. 31  Dáfídì gbọ́ pé: “Áhítófẹ́lì wà lára àwọn tí ó dìtẹ̀+ pẹ̀lú Ábúsálómù.”+ Ni Dáfídì bá sọ pé: “Jèhófà,+ jọ̀wọ́ sọ ìmọ̀ràn* Áhítófẹ́lì di ti òmùgọ̀!”+ 32  Nígbà tí Dáfídì dé orí òkè tí àwọn èèyàn ti máa ń forí balẹ̀ fún Ọlọ́run, Húṣáì+ ará Áríkì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀, ẹ̀wù rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. 33  Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: “Tí o bá bá mi sọdá, wàá di ẹrù sí mi lọ́rùn. 34  Àmọ́ tí o bá pa dà sínú ìlú, tí o sì sọ fún Ábúsálómù pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, Ọba. Ìránṣẹ́ bàbá rẹ ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́,’+ ìgbà náà ni wàá lè bá mi sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di asán.+ 35  Ṣebí àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ? Gbogbo ohun tí o bá gbọ́ ní ilé ọba+ ni kí o sọ fún àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì. 36  Wò ó! Àwọn ọmọ wọn méjèèjì wà pẹ̀lú wọn, Áhímáásì+ ọmọ Sádókù àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì, kí o ní kí wọ́n wá sọ gbogbo ohun tí o bá gbọ́ fún mi.” 37  Nítorí náà, Húṣáì, ọ̀rẹ́* Dáfídì,+ wá sínú ìlú bí Ábúsálómù ṣe ń wọ Jerúsálẹ́mù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “jí ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.”
Tàbí kó jẹ́, “40 ọdún.”
Tàbí “jọ́sìn.” Ní Héb., “ṣe iṣẹ́ ìsìn fún.”
Tàbí “olùdámọ̀ràn.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “tí wọ́n ń sọdá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “sì ń sọdá níwájú ọba.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.”
Tàbí “àmọ̀ràn.”
Tàbí “ọ̀rẹ́ àfinúhàn.”