Nọ́ńbà 24:1-25

  • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kẹta (1-11)

  • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kẹrin (12-25)

24  Nígbà tí Báláámù wá rí i ó wu Jèhófà* láti súre fún Ísírẹ́lì, kò tún lọ wá bó ṣe máa ríran ìparun+ mọ́, àmọ́ ó yíjú sí aginjù.  Nígbà tí Báláámù wòkè tó sì rí i tí Ísírẹ́lì pàgọ́ wọn ní ẹ̀yà-ẹ̀yà,+ ẹ̀mí Ọlọ́run wá bà lé e.+  Ó sì sọ̀rọ̀ lówelówe pé: + “Ọ̀rọ̀ Báláámù ọmọ Béórì, Àti ọ̀rọ̀ ẹnu ọkùnrin tí ojú rẹ̀ ti là,   Ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,Tó rí ìran Olódùmarè,Tó wólẹ̀ nígbà tí ojú rẹ̀ là:+   Àwọn àgọ́ rẹ mà rẹwà o, ìwọ Jékọ́bù,Àwọn ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!+   Wọ́n tẹ́ lọ rẹrẹ+ bí àwọn àfonífojì,Bí àwọn ọgbà tó wà létí odò,Bí àwọn ewéko álóè tí Jèhófà gbìn,Bí àwọn igi kédárì létí omi.   Omi ń sun látinú àwọn korobá rẹ̀ méjì tí wọ́n fi awọ ṣe,Etí omi+ ló sì gbin àwọn irúgbìn* rẹ̀ sí. Ọba+ rẹ̀ pẹ̀lú yóò ju Ágágì+ lọ,Wọ́n á sì gbé ìjọba rẹ̀ ga.+   Ọlọ́run ń mú un kúrò ní Íjíbítì.Ó dà bí ìwo akọ màlúù igbó fún wọn. Ó máa jẹ àwọn orílẹ̀-èdè run, àwọn tó ń ni ín lára,+Ó máa jẹ egungun wọn run, ó sì máa fi àwọn ọfà rẹ̀ run wọ́n.   Ó ti dùbúlẹ̀, ó sùn sílẹ̀ bíi kìnnìún,Bíi kìnnìún, ta ló láyà láti jí i? Ìbùkún ni fún àwọn tó ń súre fún ọ,Ègún sì ni fún àwọn tó ń gégùn-ún+ fún ọ.” 10  Inú wá bí Bálákì sí Báláámù gan-an. Bálákì wá fi ìbínú pàtẹ́wọ́, ó sì sọ fún Báláámù pé: “Torí kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi ni mo ṣe pè ọ́ + wá, àmọ́ ṣe lo kàn ń súre fún wọn lẹ́ẹ̀mẹta yìí. 11  Ó yá, tètè pa dà sílé. Mo fẹ́ dá ọ lọ́lá gan-an+ tẹ́lẹ̀ ni, àmọ́ wò ó! Jèhófà ò jẹ́ kí n dá ọ lọ́lá.” 12  Báláámù dá Bálákì lóhùn pé: “Ṣebí mo sọ fún àwọn tí o rán pé, 13  ‘Bí Bálákì bá tiẹ̀ fún mi ní ilé rẹ̀ tí fàdákà àti wúrà kún inú rẹ̀, mi ò kàn ní ṣe ohunkóhun tó wù mí,* tó lòdì sí àṣẹ Jèhófà, bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá sọ fún mi nìkan ni màá sọ’?+ 14  Ní báyìí, mo fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn mi. Wá, jẹ́ kí n sọ fún ọ, ohun tí àwọn èèyàn yìí máa ṣe fún àwọn èèyàn rẹ lọ́jọ́ iwájú.”* 15  Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+ “Ọ̀rọ̀ Báláámù ọmọ Béórì,Àti ọ̀rọ̀ ẹnu ọkùnrin tí ojú rẹ̀ ti là,+ 16  Ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,Àti ẹni tó ní ìmọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,Ó rí ìran OlódùmarèNígbà tó wólẹ̀, tí ojú rẹ̀ là: 17  Màá rí i, àmọ́ kì í ṣe báyìí;Màá wò ó, àmọ́ kò tíì yá. Ìràwọ̀ kan+ máa ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá,Ọ̀pá àṣẹ+ kan sì máa dìde láti Ísírẹ́lì.+ Ó sì dájú pé ó máa fọ́ iwájú orí Móábù*+ sí wẹ́wẹ́Àti agbárí gbogbo àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀. 18  Édómù sì máa di ohun ìní,+Àní, Séírì+ máa di ohun ìní àwọn ọ̀tá+ rẹ̀,Bí Ísírẹ́lì ṣe ń fi hàn pé òun nígboyà. 19  Ẹnì kan yóò ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá, tí yóò máa ṣẹ́gun lọ,+Yóò sì pa ẹnikẹ́ni tó bá yè bọ́ nínú ìlú náà run.” 20  Nígbà tó rí Ámálékì, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé: “Ámálékì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè,+Àmọ́ ṣe ló máa ṣègbé+ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.” 21  Nígbà tó rí àwọn Kénì,+ ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé: “Ibùgbé rẹ ní ààbò, orí àpáta sì ni ilé rẹ fìkàlẹ̀ sí. 22  Àmọ́ ẹnì kan máa sun Kénì kanlẹ̀. Ìgbà mélòó ló kù tí Ásíríà fi máa kó ọ lẹ́rú?” 23  Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé: “Ó mà ṣe o! Ta ló máa yè bọ́ tí Ọlọ́run bá ṣe èyí? 24  Àwọn ọkọ̀ òkun máa wá láti etíkun Kítímù,+ Wọ́n á sì fìyà jẹ Ásíríà,+Wọ́n á tún fìyà jẹ Ébérì.Àmọ́ ṣe lòun náà máa ṣègbé pátápátá.” 25  Báláámù+ wá dìde, ó sì lọ, ó pa dà síbi tó ti wá. Bálákì náà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ó dáa ní ojú Jèhófà.”
Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”
Ní Héb., “tó wà lọ́kàn mi.”
Tàbí “ní òpin àwọn ọjọ́.”
Tàbí “ẹ̀bátí orí Móábù.”