Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ̀ Ọlọ́run Máa Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan

Ìmọ̀ Ọlọ́run Máa Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan

“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”

Ìmọ̀ Ọlọ́run Máa Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan

TỌKỌTAYA kan ní orílẹ̀-èdè Argentina mọ ògiri kan láti fi dá ilé wọn sí méjì nítorí aáwọ̀ tó wà láàárín wọn. Ohun tí wọ́n pe ògiri náà ni “Ògiri Berlin”! Ìjà àárín tọkọtaya yìí pọ̀ débi pé ìkíní ò fẹ́ rí èkejì sójú rárá ni.

Ó dunni pé kárí ayé ni irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ń wáyé nínú ìdílé. Aáwọ̀, ìjà àti àìṣòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni pọ̀ gan-an lónìí. Èyí bani nínú jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá ètò ìdílé sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:23, 24) Ìdílé tí Ọlọ́run dá sílẹ̀ yìí jẹ́ ibi tí èèyàn á ti lè máa fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn. (Rúùtù 1:9) Bí àwọn tí ń bẹ nínú ìdílé bá ń ṣe ojúṣe wọn bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, ìyẹn á gbé Jèhófà ga, ilé wọn á sì jẹ́ ilé ayọ̀. a

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá ètò ìdílé sílẹ̀, ó yẹ ká fi ohun tó sọ ṣe atọ́nà wa nípa bó ṣe yẹ kí nǹkan máa lọ nínú ìdílé. Ìtọ́sọ́nà tó wúlò gan-an sì ń bẹ nínú Bíbélì, ìyẹn ìtọ́sọ́nà tó dìídì ṣe láti fi ran ìdílé lọ́wọ́ kí ibẹ̀ lè máa tòrò, pàápàá nígbà ìṣòro. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ lórí ojúṣe ọkọ nínú ìdílé, ó ní: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” Bí ọkọ bá ń ṣe ohun tí ibí yìí wí, yóò rọ aya lọ́rùn láti “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:25-29, 33.

Ní ti bó ṣe yẹ kí àárín òbí àti ọmọ rí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Bí àwọn òbí bá tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, ìdílé wọn á dùn, á sì rọrùn fáwọn ọmọ láti gbọ́rọ̀ sáwọn òbí wọn lẹ́nu.—Éfésù 6:1.

Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a sọ lókè yìí jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìtọ́sọ́nà inú Bíbélì lórí ọ̀ràn ìdílé ṣe dára tó. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ṣe ń fi ìlànà Ọlọ́run sílò ni wọ́n ń rí i pé ayọ̀ ń pọ̀ sí i nínú ilé àwọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti tọkọtaya ará Argentina tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún oṣù mẹ́ta, àwọn méjèèjì ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nípa ètò ìdílé tí wọ́n ń kọ́ sílò. Wọ́n sapá gidigidi láti rí i pé àwọn túbọ̀ ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ dáadáa, àwọn ń gba ti ara wọn rò, àwọn sì lẹ́mìí ìdáríjì. (Òwe 15:22; 1 Pétérù 3:7; 4:8) Wọ́n máa ń fọwọ́ wọ́nú tínú bá ń bí wọn, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tí nǹkan bá fẹ́ dojú rú. (Kólósè 3:19) Bí wọ́n ṣe wó ohun tí wọ́n pè ní “Ògiri Berlin” lulẹ̀ nìyẹn!

Ọlọ́run Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan

Bí a bá mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run tá a sì ń tẹ̀ lé e nínú ìdílé, ó máa jẹ́ kí ìdílé lágbára débi pé ìṣòro ò ní lè borí rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ àwọn ìlànà yìí ká sì máa tẹ̀ lé e, nítorí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé onírúurú ìṣòro líle koko ni yóò wà nínú ìdílé lákòókò tá a wà yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ìwàkiwà yóò gbòde kan àti pé kò ní sí ìfìmọ̀ṣọ̀kan láàárín àwùjọ ló ń ṣẹ lóde òní. Ó sọ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìwà àìdúróṣinṣin, àìní “ìfẹ́ni àdánidá” àti àìgbọràn sí òbí yóò wà, àní láàárín “àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run” pàápàá.—2 Tímótì 3:1-5.

Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ò ní wọnú ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ló ti rí i pé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè yanjú àwọn ìṣòro tó ń bá ìdílé àwọn fínra. Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá wá ń fẹ́ kí àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí wọ́n ní láti ṣe ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, kí wọ́n sì mọ̀ dájú pé “bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.” (Sáàmù 127:1) Bí ìdílé èyíkéyìí bá ń fẹ́ kí ojúlówó ayọ̀ máa wà nínú ìdílé wọn, ńṣe ni kí wọ́n fi ti Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo nínú ìdílé wọn.—Éfésù 3:14, 15.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dennis ní Hawaii rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Kristẹni ló pera ẹ̀ o, àmọ́, ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú àti aríjàgbà ẹ̀dá ni. Àgàgà nígbà tó tún wá wọṣẹ́ sójà, ńṣe ló ń ṣoro bí agbọ́n. Nígbà tó ń sọ̀tàn ara ẹ̀, ó ní: “Ìjà ni ṣáá ní gbogbo ìgbà. Mi ò kì í bẹ̀rù ohun tẹ́nikẹ́ni bá fẹ́ fi bá mi jà, kódà ikú ò bà mí lẹ́rù. Èébú ẹnu mi àti ìjà tí mò ń jà kò ṣeé kó. Ìyàwó mi tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà mí níyànjú pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Dennis ò gba ohun tí ìyàwó rẹ̀ wí rárá. Àmọ́, ìwà Kristẹni tí aya rẹ̀ ń hù sè é rọ̀. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Dennis bá aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ sípàdé ìjọ lọ́jọ́ kan. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tẹ̀ síwájú gan-an. Ó jáwọ́ nínú sìgá tó ti ń mu bọ̀ láti ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, ó sì já gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń hu ìwà àìdáa tẹ́lẹ̀ dà nù. Dennis dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an, ó sì sọ pé: “Nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí dáa nínú ìdílé mi. Ńṣe lèmi àti ìdílé mi jìjọ ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí. Àwọn ọmọ mi méjèèjì ò bẹ̀rù láti sún mọ́ mi mọ́ nítorí pé mi ò kì í ṣe onínú fùfù mọ́, èébú sì ti kúrò lẹ́nu mi. A máa ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀, a sì máa ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí Bíbélì lọ́nà tó lárinrin. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́, ǹ bá máà sí láyé mọ́ lónìí nítorí onínú fùfù gbáà ni mí tẹ́lẹ̀ rí.”

Bí àwọn ìdílé bá ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ilé wọn á di ibi aláyọ̀. Ìrírí fi hàn pé bó bá tiẹ̀ jẹ́ ẹyọ ẹnì kan péré nínú ìdílé ló ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, ọ̀rọ̀ ìdílé náà á ṣì lójú ju ìgbà tí kò bá sí ìkankan nínú wọn tó ń tẹ̀ lé e. Kí ìdílé kan tó lè rí bó ṣe yẹ kí ìdílé Kristẹni rí, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ní láti sapá gidigidi, kí wọ́n jẹ́ olóye, kí wọ́n sì mọ̀ pé ó gba àkókò kó tó lè ṣeé ṣe. Àmọ́, kí irú ìdílé bẹ́ẹ̀ mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò mú kí ìsapá wọn yọrí sí rere. Ńṣe ni kí wọ́n ṣáà fi ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ṣe àkọmọ̀nà wọn, èyí tó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù May àti June nínú kàlẹ́ńdà 2005 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni “olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀.”—ÉFÉSÙ 3:15

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọ̀RỌ̀ ÌDÍLÉ JẸ JÈHÓFÀ LÓGÚN GAN-AN NI

“Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.’”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

“Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà . . . Aya rẹ yóò dà bí àjàrà tí ń so èso ní ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ilé rẹ.” —Sáàmù 128:1, 3.