Sámúẹ́lì Kejì 8:1-18

  • Àwọn tí Dáfídì ṣẹ́gun (1-14)

  • Ìjọba Dáfídì (15-18)

8  Nígbà tó yá, Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì,+ ó borí wọn,+ Dáfídì sì gba Metegi-ámà lọ́wọ́ àwọn Filísínì.  Ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Móábù,+ ó dá wọn dùbúlẹ̀, ó sì fi okùn wọ̀n wọ́n. Ó ní kí wọ́n pa àwọn tó wà níbi tí okùn ìwọ̀n méjì gùn dé, àmọ́ kí wọ́n dá àwọn tó wà níbi okùn ìwọ̀n kan sí.+ Àwọn ọmọ Móábù di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀*+ wá.  Dáfídì ṣẹ́gun Hadadésà ọmọ Réhóbù ọba Sóbà+ bí ó ṣe ń lọ láti gba àkóso rẹ̀ pa dà ní odò Yúfírétì.+  Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) agẹṣin àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́wọ́ rẹ̀. Dáfídì sì já iṣan ẹsẹ̀* gbogbo àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun, àmọ́ ó dá ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn ẹṣin+ náà sí.  Nígbà tí àwọn ará Síríà tó wà ní Damásíkù+ wá ran Hadadésà ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ará Síríà+ náà.  Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Damásíkù ní Síríà, àwọn ará Síríà wá di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá. Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+  Láfikún sí i, Dáfídì gba àwọn apata* wúrà tó wà lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù.+  Ọba Dáfídì kó bàbà tó pọ̀ gan-an láti Bétà àti Bérótáì, àwọn ìlú Hadadésà.  Lásìkò yìí, Tóì ọba Hámátì+ gbọ́ pé Dáfídì ti ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadésà.+ 10  Torí náà, Tóì rán Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóì jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó àwọn ohun èlò fàdákà, ohun èlò wúrà àti ohun èlò bàbà wá. 11  Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà bó ṣe ya fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣẹ́gun+ sí mímọ́: 12  ó kó wọn láti Síríà àti Móábù,+ látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì+ àti látinú ẹrù ogun Hadadésà+ ọmọ Réhóbù ọba Sóbà. 13  Òkìkí Dáfídì túbọ̀ kàn nígbà tí ó pa dà láti ibi tó ti lọ pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lára àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+ 14  Ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Édómù. Gbogbo Édómù ni ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì di ìránṣẹ́ Dáfídì.+ Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+ 15  Dáfídì ń jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ Dáfídì ń dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì ń ṣe òdodo+ sí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+ 16  Jóábù+ ọmọ Seruáyà ni olórí àwọn ọmọ ogun, Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí. 17  Sádókù+ ọmọ Áhítúbù àti Áhímélékì ọmọ Ábíátárì ni àlùfáà, Seráyà sì ni akọ̀wé. 18  Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ni olórí àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì di olórí àwọn òjíṣẹ́.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “owó òde.”
Tàbí “pátì.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Tàbí “apata ribiti.”
Tàbí “gba Dáfídì là.”
Ní Héb., “àlùfáà.”