Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè

Ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè

Ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè

JÁLẸ̀ ìtàn, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ló gbà gbọ́ pé lọ́jọ́ kan àwọn á fi ayé yìí sílẹ̀, àwọn yóò sì gba ọ̀run lọ. Ọ̀pọ̀ ló rò pé Ẹlẹ́dàá kò ní in lọ́kàn rárá pé kí ayé yìí jẹ́ ibi tá a ó máa gbé títí lọ gbére. Kódà èrò tàwọn aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ní lórí kókó yìí tún lé kenkà. Lójú ọ̀pọ̀ nínú wọn, kìkì ibi ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ jẹ́, ó sì lè ṣèdènà fún àṣeyọrí gidi nípa tẹ̀mí kí ó sì dènà sísún mọ́ Ọlọ́run.

Ó ṣeé ṣe káwọn tó ní irú èrò tá a mẹ́nu kan lókè yìí má mọ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ọ̀rọ̀ náà tàbí kí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti pa ohun tó sọ tì. Ká sòótọ́, lónìí, ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ohun tí Ọlọ́run mí sí àwọn èèyàn láti kọ sílẹ̀ lórí kókó yìí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí í ṣe Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Ṣùgbọ́n ṣe kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dípò ká gba àbá èrò orí àwọn ènìyàn? (Róòmù 3:4) Ó ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí Bíbélì ti sọ fún wa pé, olubi ẹ̀dá alágbára kan tá ò lè rí ti fọ́ àwọn èèyàn lójú nípa tẹ̀mí, ó sì ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà” nísinsìnyí.—Ìṣípayá 12:9; 2 Kọ́ríńtì 4:4.

Kí Ló Fa Oríṣiríṣi Èrò Nípa Párádísè?

Àwọn èrò tó yàtọ̀ síra nípa ọkàn ti mú kí ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé yìí dàrú mọ́ àwọn èèyàn lójú. Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé èèyàn ní ọkàn tí kò lè kú, ìyẹn ohun kan tí yóò fi ara ènìyàn sílẹ̀ tí yóò sì máa wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Àwọn mìíràn gbà gbọ́ pé ọkàn ti wà ṣáájú ká tó dá ara ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti wí, Plato tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì gbà pé “ọkàn ń ṣẹ̀wọ̀n nínú ara nítorí pé ó ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ nígbà tó ṣì wà lọ́run.” Bákan náà, Origen tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ọ̀rúndún kẹta sọ pé “ọkàn dẹ́ṣẹ̀ [lọ́run] ṣáájú kó tó dara pọ̀ mọ́ ara” ó sì “ń ṣẹ̀wọ̀n [nínú ara yẹn lórí ilẹ̀ ayé] gẹ́gẹ́ bí ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀.” Ọ̀kẹ́ àìmọye ló sì gbà gbọ́ pé ibi ìdánrawò kan ni ayé yìí jẹ́, tó o bá fẹ́ lọ sọ́run.

Ọ̀kan-kò-jọ̀kan èrò ló wà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà tí ẹnì kan bá kú. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé History of Western Philosophy sọ, àwọn ará Íjíbítì ní èrò náà pé “bí ẹnì kan bá kú, ọkàn ẹni yẹn á sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ àwọn òkú.” Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ṣàlàyé pé ọkàn ẹnì kan tó kú kì í sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ àwọn òkú tó ṣókùnkùn biribiri, ṣùgbọ́n ńṣe ló máa ń gòkè lọ sí ibùgbé gíga tí àwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé. Wọ́n ní Socrates tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì gbà pé bí ẹnì kan bá kú, ọkàn ẹni yẹn á “jáde kúrò lára rẹ̀ lọ sí ibi kan tí kò ṣeé rí . . . yóò sì wà níbẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run níbi tí yóò ti lo èyí tó kù nínú ìgbà tí yóò fi wà láàyè.”

Kí ni Bíbélì Sọ?

Kò sí ibi tí Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọ́run, ìyẹn Bíbélì ti sọ pé ènìyàn ní ọkàn tí kò lè kú. Ka àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 2:7 fúnra rẹ. Ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Ìyẹn ṣe kedere, o sì yéni yékéyéké. Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù, kò fi ohun kan tí kò ṣeé rí sínú rẹ̀. Rárá, kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, nítorí Bíbélì sọ pé “ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Kì í ṣe pé ọkàn ń gbé inú ọkùnrin náà. Ọkùnrin náà fúnra rẹ̀ ni ọkàn.

Nígbà tí Jèhófà ń dá ayé àti ìdílé ènìyàn, kò ní i lọ́kàn rárá pé kí èèyàn máa kú. Ète Ọlọ́run ni pé kí àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè. Ádámù kú kìkì nítorí pé ó ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 15-17; 3:1-6; Aísáyà 45:18) Nígbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́ kú, ṣé ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí ló lọ ni? Rárá o! Ọkùnrin náà, ìyẹn ọkàn náà, Ádámù padà sínú ekuru tí kò lẹ́mìí tí a fi dá a.—Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19.

Gbogbo wa ló ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ baba ńlá wa, Ádámù. (Róòmù 5:12) Ikú tá a sì jogún yìí ló máa ń fòpin sí ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bó ṣe fòpin sí ìwàláàyè ti Ádámù. (Sáàmù 146:3, 4) Àní, nínú gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin tó wà nínú Bíbélì, kò sí ibi kan níbẹ̀ tá a ti sọ pé “ọkàn” jẹ́ “aláìleèkú” tàbí pé yóò ‘wà títí láé.’ Dípò ìyẹn, Ìwé Mímọ́ sọ ní kedere pé ọkàn kan, ìyẹn ènìyàn fúnra rẹ̀ lè kú. Ọkàn máa ń kú.—Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4.

Ṣé Ibi ni Àwọn Nǹkan Tara Jẹ́ Lóòótọ́?

Kí ni ká wá sọ nípa èrò àwọn tó sọ pé ibi ni gbogbo nǹkan tara títí kan ayé fúnra rẹ̀? Àwọn ẹlẹ́sìn Mani ló gba irú èrò bẹ́ẹ̀ gbọ́, ìyẹn ẹ̀sìn tí Mani dá sílẹ̀ ní Páṣíà ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Èrò ìgbàgbọ́ Mani jáde látinú ipò hílàhílo tí ìran èèyàn wà.” Mani gbà gbọ́ pé jíjẹ́ tá a jẹ́ ènìyàn yìí “ṣàjèjì, ohun tí kò ṣeé fara dà ni, nǹkan ibi gbáà ló sì jẹ́.” Ó tún gbà pé ọ̀nà àbáyọ kan tá a fi lè kúrò nínú “làásìgbò” yìí kò ju pé kí ọkàn jáde kúrò nínú ara, kó kúrò ní sàkáání ilẹ̀ ayé, kó di ẹni ẹ̀mí, kó wá lọ máa gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí.

Àmọ́ ṣá o, èrò Bíbélì yàtọ̀, ó sọ fún wa pé lójú Ọlọ́run “ohun gbogbo tí ó ti ṣe” nígbà tí ó ń dá ayé àti ìran ènìyàn “dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Nígbà yẹn, kò sí ìdènà èyíkéyìí láàárín ènìyàn àti Ọlọ́run. Ádámù àti Éfà gbádùn àjọse tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, àní bí ọkùnrin pípé náà Jésù Kristi ṣe gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run.—Mátíù 3:17.

Ká sọ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà kò tọ ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ ni, wọn ì bá gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Inú Párádísè ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn, nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn, ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Inú ọgbà Párádísè yẹn lá tí dá Éfà. Ká sọ pé Ádámù àti Éfà kò dẹ́sẹ̀ ni, tayọ̀tayọ̀ ni àwọn àti ọmọ wọn pípé ì bá fi ṣiṣẹ́ pa pọ̀ títí dìgbà tí wọn máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21; 3:23, 24) Párádísè orí ilẹ̀ ayé ì bá jẹ́ ilé ìran ènìyàn títí láé.

Kí Nìdí Táwọn Kan Fi Ń Lọ Sọ́run?

O lè sọ pé, ‘Ṣebí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń lọ sọ́run, àbí kò sọ bẹ́ẹ̀ ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà pinnu láti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run níbi tí díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ádámù àti Jésù Kristi yóò ti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí”. (Ìṣípayá 5:10; Róòmù 8:17) A óò jí wọn dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ọ̀rúndún kìíní sì ní ìpìlẹ̀ wọn.—Lúùkù 12:32; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44; Ìṣípayá 14:1-5.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin fi ayé sílẹ̀, kí wọ́n lọ sọ́run. Kódà nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn.” (Jòhánù 3:13) Nípasẹ̀ “Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Jésù Kristi, Ọlọ́run pèsè ìràpadà tó mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe fún àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Róòmù 5:8) Ṣùgbọ́n ibo ni ọ̀kẹ́ àìmọye irú àwọn ènìyàn tó bá ní ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa gbé títí láé?

Ète Ọlọ́run ní Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Yóò Nímùúṣẹ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ète Ọlọ́run ni pé, òun yóò mú díẹ̀ lára ìdílé ìran ènìyàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi ní Ìjọba ọ̀run, ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ẹni rere ló ń lọ sọ́run. Jèhófà dá ayé yìí láti jẹ́ ilé Párádísè fún ìdílé ìràn ènìyàn. Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò mú kí ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ nímùúṣẹ—Mátíù 6:9, 10.

Nígbà tí Jésù Kristi àti àwọn alájùmọ̀ ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ lọ́run bá ń ṣàkóso, ayọ̀ àti àlàáfíà ní yóò jọba lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9-11) À óò jí àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run dìde, wọn yóò sì gbádùn ìlera pípé. (Ìṣe 24:15) Nítorí ìṣòtítọ́ wọn sí Ọlọ́run, a óò fún ìran ènìyàn ní ohun táwọn òbí wa ìpilẹ̀ṣẹ̀ pàdánù, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun tí ìran ènìyàn pípé yóò gbádùn nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 21:3, 4.

Jèhófà Ọlọ́run kì í kùnà láti ṣàṣeparí àwọn ohun tó bá fẹ́ láti ṣe. Ó tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:10, 11.

Nínú ìwé Aísáyà nínú Bíbélì, a rí àpẹẹrẹ bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Kò sí olùgbé kankan nínú Párádísè tí yóò sọ pé, “Àìsàn ń ṣe mí.” (Aísáyà 33:24) Àwọn ẹranko kò ní ṣe ìpalára fún ènìyàn. (Aísáyà 11:6-9) Àwọn ènìyàn yóò kọ́ àwọn ilé mèremère, wọn yóò sì gbé inú wọn, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ̀ èso rẹ̀ tẹ́rùn. (Aísáyà 65:21-25) Kò tán síbẹ̀ o, Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.

Láìpẹ́ ìran èèyàn onígbọràn yóò máa gbé nínú irú ipò tó mìrìngìndìn bẹ́ẹ̀. ‘A óò dá wọn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, wọn yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.’ (Róòmù 8:21) Ẹ wo bí yóò ṣe lárinrin tó láti máa gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí! (Lúùkù 23:43) O lè gbé nínú Párádísè yẹn, tó o bá ṣe ohun tí ìmọ̀ pípéye tó wà nínu Ìwé Mímọ́ ní kó o ṣe, tó o sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Jésù Kristi. O yẹ kó dá ọ lójú nísinsìnyí pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé ayé yìí yóò di Párádísè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

A dá Ádámù àti Éfà láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé . . .

wọn yóò kọ́ ilé

wọ́n yóò gbin ọgbà àjàrà

Jèhófà yóò bù kún wọn

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./NASA