Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè?

Ǹjẹ́ ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè?

Ǹjẹ́ ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè?

ÌWỌ̀NBA èèyàn díẹ̀ ló gbà gbọ́ pé ilẹ̀ ayé yìí máa di Párádísè. Ọ̀pọ̀ ló rò pé ilẹ̀ ayé yìí kò tiẹ̀ ní sí mọ́ tó bá yá. Ìwé The Sacred Earth, tí Brian Leigh Molyneaux kọ, sọ pé ‘ìbúgbàù ńlá kan’ tó wáyé ní nǹkan bí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ọdún sẹ́yìn ló jẹ́ kí ayé wa yìí wà. Bí àwọn èèyàn ò bá sì pa ayé yìí run, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé ayé yìí àti gbogbo àgbáyé lápapọ̀ lè “bú kẹ̀ù lọ́jọ́ kan, kó sì di ẹyín iná.”

Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó jẹ́ akéwì ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Milton kò ní irú èrò tí kò dára bẹ́ẹ̀. Nínú ewì rẹ̀ kan tó kàmàmà tó pè ní Paradise Lost, ó kọ̀wé pé Ọlọ́run dá ayé wa yìí láti jẹ́ Párádísè fún ìdílé ìran ènìyàn. Ṣùgbọ́n a pàdánù Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀ yẹn. Àmọ́ ṣá o, Milton gbà gbọ́ pé a ó mú Párádísè padà bọ̀ sórí ilẹ̀ ayé, àti pé lọ́jọ́ kan Jésù Kristi tó jẹ́ olùràpadà yóò “san ẹ̀san fáwọn olóòótọ́, yóò sì fi wọ́n sínú ìgbádùn kẹlẹlẹ . . . bóyá Lọ́run tàbí Láyé.” Milton fi ìdánilójú sọ pé: “Nígbà náà ni Ayé yóò wá di Párádísè.”

Párádísè—Ṣé Lọ́run Ni, àbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?

Ọ̀pọ̀ àwọn onísìn ló ní irú èrò tí Milton ní yìí pé lọ́jọ́ kan, àwọn yóò gba èrè nítorí àwọn ohun tí ń kó ìpayà báni àti ìyà àjẹkúdórógbó táwọn ti fojú winá rẹ̀ níhìn lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n ibo ni wọ́n ti máa gbádùn èrè náà? Ṣé “Lọ́run ni àbí Láyé”? Àwọn kan ò tiẹ̀ gbà pé ayé ni Párádísè máa wà. Wọ́n sọ pé àwọn èèyàn yóò jẹ “ìgbádùn kẹlẹlẹ” kìkì bí wọ́n bá kúrò láyé tí wọ́n sì ń gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí lọ́run.

Ìwé Heaven—A History tí C. McDannell àti B. Lang kọ, sọ pé Irenaeus, tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ọ̀rúndún kejì gbà gbọ́ pé ìwàláàyè nínú Párádísè tá a mú padà bọ̀ sípò “kì yóò jẹ́ ní ibì kan tó jìnnà réré lọ́run, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ níhìn ín lórí ilẹ̀ ayé.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé yẹn sọ, o ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn bíi John Calvin àti Martin Luther nírètí pé àwọn ń lọ sọ́run, wọ́n tún gbà gbọ́ pé “Ọlọ́run yóò tún sọ ayé yìí dọ̀tun.” Àwọn tó jẹ́ onísìn mìíràn náà ní irú ìgbàgbọ́ kan náà. McDannell àti Lang tún sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Júù gbà gbọ́ pé nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ‘yóò mú gbogbo ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn kúrò tí àwọn èèyàn yóò wá máa gbé ìgbésí ayé tó gbádùn mọ́ni lórí ilẹ̀ ayé.’ Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopædia of Middle Eastern Mythology and Religion sọ pé ìgbàgbọ́ àwọn ará Páṣíà ìgbàanì ni pé “a óò dá ayé padà sí bó ṣe wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn yóò wá máa gbé ní àlàáfíà lẹ́ẹ̀kan sí i.”

Kí ló wá dé táwọn èèyàn ò fi gbà pé ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè? Ṣé àkókò kúkúrú kan là óò fi wà láàyè ni? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Philo tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí Júù ní ọ̀rúndún kìíní gbà gbọ́, ṣé ká kàn gbé ayé fún “àkókò kúkúrú kan pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìṣòro” ká sì kọjá sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí ni? Àbí ṣé Ọlọ́run ní ohun mìíràn lọ́kàn nígbà to dá ayé tó sì fi àwọn èèyàn sínú rẹ̀ láti gbádùn ipò Párádísè níbẹ̀? Ṣé ìran èèyàn lè rí ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́ nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì jẹ ìgbádùn kẹlẹlẹ níhìn lórí ilẹ̀ ayé? Ẹ ò ṣe jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí? Ó ṣeé ṣe kó o parí èrò sí ibi tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn parí èrò sí pé o bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ láti retí pé ilẹ̀ ayé yóò padà di Párádísè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

John Milton tó jẹ́ akéwì gbà gbọ́ pé a óò mú Párádísè padà bọ̀ sípò

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ilẹ̀ Ayé: U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./⁠NASA

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Ilẹ̀ Ayé: U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./NASA; John Milton: Leslie’s