Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Sátánì

Sátánì

Ṣé Èṣù wà lóòótọ́?

“Ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, . . . ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣípayá 12:9.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan gbà gbọ́ pé Èṣù kì í ṣe ẹni gidi, pé ìwà burúkú tó ń gbé inú gbogbo èèyàn là ń pè ní Èṣù.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Sátánì wà lóòótọ́ o. Áńgẹ́lì ni tẹ́lẹ̀ kó tó di ọlọ̀tẹ̀ àti alátakò sí Ọlọ́run. Bíbélì pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31) Ó máa ń lo “àwọn iṣẹ́ àmì” àti “ẹ̀tàn” láti fi ṣe àwọn ohun tó fẹ́.—2 Tẹsalóníkà 2:9, 10.

Ṣebí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run bá Sátánì sọ̀rọ̀ ní ọ̀run, tó bá jẹ́ pé ìwà burúkú kan tó ń gbé inú ẹ̀dá, tó sì ń gbé inú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Sátánì, báwo ni Ọlọ́run á ṣe bá a sọ̀rọ̀? Ó ṣe tán, Ọlọ́run kò lè máa bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀, irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ kò sì lè ríbi gbé nínú Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé tó sì jẹ́ Mímọ́ láìkù síbì kan. (Diutarónómì 32:4; Jóòbù 2:1-6) Ó ṣe kedere pé ẹni gidi ni Sátánì, kì í ṣe ìwà burúkú tó wà nínú èèyàn.

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ NÁÀ FI KÀN Ọ́

Sátánì kò fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé òun wà, kó lè máa yọ́ kẹ́lẹ́ bá iṣẹ́ ibi rẹ̀ nìṣó. Ó dà bí ọ̀daràn tí kò fẹ́ kí àwọn èèyàn dá òun mọ̀ kó lè máa hùwàkiwà rẹ̀ nìṣó. Tí o kò bá fẹ́ kó fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀ tàn ọ́ jẹ, ó yẹ kó o kọ́kọ́ gbà pé Èṣù wà lóòótọ́.

Ibo ni Èṣù ń gbé?

“Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín.”—Ìṣípayá 12:12.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé inú iná ọ̀run àpáàdì nínú kòtò tó jìn lábẹ́ ilẹ̀ ni Sátánì ń gbé. Àwọn míì gbà gbọ́ pé inú àwọn èèyàn burúkú ni Sátánì ń gbé.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ẹ̀dá ẹ̀mí ni Sátánì, ibi tí a kò lè rí ló ń gbé. Nígbà kan, Sátánì lè lọ síbi táwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ àti Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń gbé. (Jóòbù 1:6) Àmọ́, ní báyìí, Ọlọ́run ti lé òun àtàwọn áńgẹ́lì burúkú yòókù kúrò ní ọ̀run wá sí ayé. Wọn ò sì lè pa dà sí ọ̀run mọ́.—Ìṣípayá 12:12.

Ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé ó ní ibì kan pàtó tí Sátánì ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí? Bí àpẹẹrẹ, o lè ti ka ohun tí Bíbélì sọ pé ìlú Págámù àtijọ́ ni ‘ibi tí Sátánì ń gbé.’ (Ìṣípayá 2:13) Àmọ́ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn ni pé àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Sátánì pọ̀ gan-an ní ìlú yẹn. Èṣù kò ní ibì kan pàtó tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé “gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” jẹ́ ti Èṣù.—Lúùkù 4:5, 6.

Ǹjẹ́ Sátánì lè darí àwọn èèyàn tàbí kó ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́?

“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ti jẹ́ kí Sátánì tan àwọn, torí náà a lè sọ pé Èṣù ló ń darí wọn. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn èèyàn kò fi lè tún ayé ṣe títí di báyìí.

Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì míì tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ ṣe ń darí àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́.—Mátíù 12:22; 17:15-18; Máàkù 5:2-5.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Má ṣe jẹ́ kí Sátánì fi agbára rẹ̀ kó ẹ láyà jẹ. Ó yẹ kó o mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n tó máa ń lò láti fi tan àwọn èèyàn, kí ìwọ náà má bàa kó sọ́wọ́ rẹ̀, torí a “kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:11) Tó o bá ń ka Bíbélì, wàá ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ọgbọ́n àyínìke tí Èṣù máa ń lò, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o tẹsẹ̀ bọ pàkúté rẹ̀.

Má ṣe tọ́jú ohunkóhun tó jẹ́ ti àwọn ẹ̀mí Èṣù sọ́wọ́. (Ìṣe 19:19) Àwọn nǹkan bí ìfúnpá, ìwé, fídíò, orin àtàwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tó jẹ mọ́ wíwo iṣẹ́ tàbí bíbá ẹ̀mí Èṣù lò.

Bíbélì sọ pé “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì, wàá lè gba ara rẹ lọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì.—Éfésù 6:11-18.