Àkọsílẹ̀ Mátíù 17:1-27

  • Ìyípadà ológo (1-13)

  • Ìgbàgbọ́ bíi hóró músítádì (14-21)

  • Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (22, 23)

  • Wọ́n fi owó ẹnu ẹja san owó orí (24-27)

17  Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan.+  A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn; ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò* bí ìmọ́lẹ̀.+  Wò ó! Mósè àti Èlíjà fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀.  Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Tí o bá fẹ́, màá pa àgọ́ mẹ́ta síbí, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.”  Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ìkùukùu* tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, sì wò ó! ohùn kan dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.+ Ẹ fetí sí i.”+  Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.  Jésù wá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.”  Nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọn ò rí ẹnì kankan àfi Jésù nìkan.  Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má sọ ìran náà fún ẹnikẹ́ni títí a fi máa jí Ọmọ èèyàn dìde.”+ 10  Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi í pé: “Kí ló wá dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 11  Ó fèsì pé: “Èlíjà ń bọ̀ lóòótọ́, ó sì máa mú kí gbogbo nǹkan pa dà sí bó ṣe yẹ.+ 12  Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé Èlíjà ti wá, wọn ò sì dá a mọ̀, àmọ́ wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí i.+ Lọ́nà kan náà, Ọmọ èèyàn máa jìyà lọ́wọ́ wọn.”+ 13  Ìgbà yẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn fòye mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jòhánù Arinibọmi ló ń bá àwọn sọ. 14  Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn èrò,+ ọkùnrin kan wá bá a, ó kúnlẹ̀ fún un, ó sì sọ pé: 15  “Olúwa, ṣàánú ọmọkùnrin mi, torí ó ní wárápá, ara rẹ̀ ò sì yá. Ó máa ń ṣubú sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà.+ 16  Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, àmọ́ wọn ò lè wò ó sàn.” 17  Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí.” 18  Jésù wá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó sì jáde kúrò nínú ọmọkùnrin náà, ara ọmọ náà sì yá láti wákàtí yẹn.+ 19  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá Jésù lóun nìkan, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló dé tí a ò fi lè lé e jáde?” 20  Ó sọ fún wọn pé: “Torí ìgbàgbọ́ yín kéré ni. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.”+ 21 * —— 22  Ìgbà tí wọ́n kóra jọ sí Gálílì ni Jésù sọ fún wọn pé: “A máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+ 23  wọ́n máa pa á, a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ Inú wọn sì bà jẹ́ gidigidi. 24  Lẹ́yìn tí wọ́n dé Kápánáúmù, àwọn ọkùnrin tó ń gba dírákímà méjì* fún owó orí wá bá Pétérù, wọ́n sì sọ pé: “Ṣé olùkọ́ yín kì í san dírákímà méjì fún owó orí ni?”+ 25  Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Àmọ́ nígbà tó wọnú ilé, Jésù ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó bi í pé: “Kí lèrò rẹ, Símónì? Ọwọ́ ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé ọwọ́ àwọn ọmọ wọn ni àbí ọwọ́ àwọn àjèjì?” 26  Nígbà tó sọ pé: “Ọwọ́ àwọn àjèjì ni,” Jésù sọ fún un pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn ọmọ kì í san owó orí. 27  Àmọ́ ká má bàa mú wọn kọsẹ̀,+ lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, kí o sì mú ẹja tó bá kọ́kọ́ jáde, tí o bá la ẹnu rẹ̀, wàá rí ẹyọ owó fàdákà kan.* Mú un, kí o sì fún wọn, kó jẹ́ tèmi àti tìrẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “funfun.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Grk., “dírákímà méjì alápapọ̀.” Wo Àfikún B14.
Ní Grk., “ẹyọ owó sítátà kan,” òun ni wọ́n kà sí dírákímà mẹ́rin alápapọ̀. Wo Àfikún B14.