JÍ! July 2013 | Bó O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ọ̀daràn

Ìwà ọ̀daràn ni ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí ọ̀kan lára ìṣòro tó lè jù tí wọ́n ń kojú. Kọ́ bó o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ.

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Lára ẹ̀ ni: Àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ní pápákọ̀ òfuurufú gba àwọn ohun ọlọ́ṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n fẹ́ wọnú bàlúù, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-èdè Norway ṣe àyípadà sí òfin tó fi dandan lé àjọṣe tó wà láàárín Ìjọba àti Ṣọ́ọ̀ṣì àti ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Yan Odì

Báwo làwọn tọkọtaya kan ṣe máa ń bá a débi tí wọn ò fi ní bá ara wọn sọ̀rọ̀, kí ni wọ́n lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè náà?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bó O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ọ̀daràn

Kí lo lè ṣe láti túbọ̀ dáàbò bo ara rẹ àtàwọn èèyàn rẹ?

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ

Obìnrin Júù Kan Sọ Ìdí Tó Fi Yí Ẹ̀sìn Rẹ̀ Pa Dà

Àwọn ẹ̀rí wo ni Racquel Hall rí tó mú kó dá a lójú pé Jésù ni Mèsáyá tó ti ń yán hànhàn fún?

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́

Ṣé ẹni gidi ni Ọlọ́run àbí agbára kan lásán tí kò sí níbì kankan? Báwo ni Ọlọ́run ṣe dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀?

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Sátánì

Ṣé ẹni gidi ni Sátánì, àbi ìwà burúkú tó ń gbé inú èèyàn?

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Lẹbẹ Ẹja Àbùùbùtán

Kọ́ nípa bí lẹ́bẹ́ ẹranko ńlá yìí ṣe ti nípa lórí ìgbésí ayé rẹ.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Ní Àìsàn Tó Ò Ń Bá Fínra? (Apá 2)

Ka ìrírí táwọn ọ̀dọ́ kan tó ń ṣàìsàn tó le fẹnu ara wọn sọ nípa bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ fara da ohun tó ń ṣe wọ́n.