Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Àwọn tó ń bójú tó ààbò ní pápákọ̀ òfuurufú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ní ọdún mẹ́wàá tó kọjá, oríṣiríṣi nǹkan tí ìjọba fòfin dè, tó lé ní àádọ́ta [50] mílíọ̀nù làwọn òṣìṣẹ́ ààbò ti gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n fẹ́ wọnú bàlúù. Lọ́dún 2011 nìkan, iye ìbọn tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn lé ní ẹgbẹ̀fà [1,200]. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gba ìbọn lọ́wọ́ wọn sọ pé àwọn gbàgbé rẹ̀ sọ́wọ́ ni.

Orílẹ̀-èdè Brazil

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi nǹkan kan sára aṣọ iléèwé àwọn ọmọ, èyí tí yóò máa fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sáwọn òbí tí àwọn ọmọ bá sá kúrò níléèwé. Àwọn òbí máa ń rí àtẹ̀jíṣẹ́ gbà tó máa sọ ìgbà tọ́mọ wọn dé iléèwé, wọ́n á sì tún rí àtẹ̀jíṣẹ́ míì gbà tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ náà fi ogún [20] ìṣẹ́jú pẹ́ dé iléèwé.

Orílẹ̀-èdè Norway

Lórílẹ̀-èdè Norway, ẹ̀sìn Ṣọ́ọ̀ṣì Luther kì í ṣe ẹ̀sìn tí ìjọba ní kí gbogbo èèyàn máa ṣe mọ́. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-èdè Norway ṣe àyípadà sí òfin tó fi dandan lé àjọṣe tó wà láàárín Ìjọba àti Ṣọ́ọ̀ṣì Luther.

Orílẹ̀-èdè Czech Republic

Ìwádìí fi hàn pé ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn òṣìṣẹ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Czech Republic ló máa ń di ọ̀ranyàn fún láti gba ìpè tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kúrò níbiṣẹ́, wọ́n tún máa ń gba lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ pàápàá. O ju ìdá kan nínú mẹ́ta lọ lára wọn tó máa ń fẹ́ láti rí i pé wọ́n dá èsì pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Orílẹ̀-èdè Íńdíà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tí wọ́n ń mú jáde lórílẹ̀-èdè Íńdíà fi nǹkan bí ìdajì pọ̀ ju ti ogún [20] ọdún sẹ́yìn lọ, tí wọ́n sì tún ń tọ́jú mílíọ̀nù mọ́kànléláàádọ́rin [71] tọ́ọ̀nù ìrẹsì àti àlìkámà, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè náà ni kò rí oúnjẹ jẹ. Nǹkan bí ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn oúnjẹ oníhóró tí wọ́n ń kó tọ́jú ló ń dé ọ̀dọ̀ àwọn aráàlù. Ìwà ìbàjẹ́ àti fífi nǹkan ṣòfò wà lára ohun tó fa ìṣòro wọn.