Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ

Bó O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ọ̀daràn

Bó O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ọ̀daràn

“Àwọn ọ̀rẹ́ mi sábà máa ń sìn mí lọ sílé tílẹ̀ bá ti ṣú. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ kan tó ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu, ọkọ̀ takisí ni mo wọ̀.

“Dípò kí awakọ̀ yẹn gbé mi lọ sílé, pápá kan tó pa rọ́rọ́ ló gbé mi lọ, ó sì fẹ́ fipá bá mi lò pọ̀. Mo fi gbogbo agbára mi pariwo, ló bá fi mí sílẹ̀. Bó tún ṣe pakuru mọ́ mi, mo tún kígbe, mo sì sá lọ.

“Mo ti máa ń rò ó tẹ́lẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ àǹfààní kankan tiẹ̀ wà nínú kéèyàn pariwo tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?’ Àmọ́ mo wá rí i pé àǹfààní tó pọ̀ ló wà ńbẹ̀!”—KARIN. *

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ máà sí ibi tí kò sí ìwà ọ̀daràn. Bí àpẹẹrẹ, adájọ́ kan sọ pé: “Kò sẹ́ni tí kò ní kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn, ìgbà tó máa kan kálukú la ò mọ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ọ̀daràn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ láwọn ibì kan, síbẹ̀ ó ṣì yẹ kéèyàn wà lójúfò, torí ìyẹn lè mú kó rọrùn láti kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn.

Yálà ìwà ọ̀daràn pọ̀ níbi tó ò ń gbé tàbí kò pọ̀, kí lo lè ṣe láti túbọ̀ dáàbò bo ara rẹ àtàwọn èèyàn rẹ? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ọlọgbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè a kọjá, a sì jẹ wọ́n níyà.” (Òwe 22:3, Bíbélì Mímọ́) Kódà, àwọn ọlọ́pàá máa ń tẹnu mọ́ ọn pé ká máa ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ ká kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn, torí pé ojú ni alákàn fi ń ṣọ́rí.

Láfikún sí ohun táwọn ọ̀daràn máa ń jí lọ́wọ́ ẹni àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn èèyàn léṣe, ìpayà àti ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n máa ń kó bá àwọn èèyàn tí wọ́n ṣe lọ́ṣẹ́ kì í lọ bọ̀rọ̀ lọ́kàn. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ààbò jẹ wá lógún gan-an. Torí náà, jẹ́ ká wo àwọn ohun tó o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn bí àwọn adigunjalè, àwọn tó ń fipá báni lò pọ̀, àwọn oníjìbìtì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn tó máa ń jí ìsọfúnni ẹlòmíì.

ÀWỌN ADIGUNJALÈ

Bí wọ́n ṣe ń ṣọṣẹ́. Àwọn adigunjalè máa ń fipá gba ohun tí kì í ṣe tiwọn, wọ́n sì tún máa ń halẹ̀ mọ́ni.

Àkóbá tí wọ́n máa ń ṣe. Lẹ́yìn táwọn adigunjalè ṣọṣẹ́ léraléra nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, amòfin kan sọ pé, òótọ́ ni pé wọn ò ṣe ẹnikẹ́ni léṣe, àmọ́ wọ́n kó ìpayà bá gbogbo àwọn tọ́rọ̀ náà kàn. Ó ní: “Ìdààmú ọkàn bá ọ̀pọ̀ wọn, wọn ò sì rí oorun sùn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló ń sọ pé ohun tójú àwọn rí yẹn máa ń ṣàkóbá fún àwọn lẹ́nu iṣẹ́ lójoojúmọ́.”

Ohun tó o lè ṣe

 • Máa ṣọ́ra. Ìfà làwọn olè sábà máa ń wá. Wọ́n sì máa ń dọdẹ àwọn tí kò bá fura. Torí náà, máa ṣọ́ àwọn tó ń ṣọ́ ẹ, rí i pé o mọ ohun tó ń lọ níbikíbi tó o bá wà. Má ṣe mutí yó, má sì ṣe lo oògùn nílòkulò kí ìrònú rẹ lè máa já gaara. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó dá lórí ìlera sọ pé: “Téèyàn bá ń mutí tàbí tó ń jẹ oògùn yó,” ó máa ṣòro gan-an fún un “láti ronú bó ṣe tọ́, kó sì fiyè sí àwọn ohun tó lè fa jàǹbá fún un.”

 • Máa tọ́jú ẹrù rẹ. Máa ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ rẹ dáadáa àtàwọn ilẹ̀kùn àti fèrèsé ilé rẹ. Má ṣe gba ẹni tí o kò mọ̀ sínú ilé tàbí ọkọ̀ rẹ. Má ṣe gbé ohun tó jojú ní gbèsè síbi tí gbogbo èèyàn á ti máa rí i, má sì fi ṣe fọ́rífọ́rí. Ìwé Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” Àwọn tó ń lo ohun ìṣaralóge olówó gọbọi, àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé làwọn olè, títí kan àwọn ewèlè ọmọ tó ń wá owó lójú méjéèjì sábà máa ń fojú sí lára.

 • Máa gba ìmọ̀ràn. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà òmùgọ̀ tọ̀nà ní ojú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fetí sí ìmọ̀ràn ni ọlọ́gbọ́n.” (Òwe 12:15) Tó o bá ń rìnrìn àjò, máa gba ìmọ̀ràn àwọn tó mọ ìlú náà dáadáa, títí kan ohun táwọn tó ń bójú tó ìlú náà bá sọ. Wọ́n lè sọ àwọn ibi tó yẹ kó o ṣọ́ra fún àti bó o ṣe lè tọ́jú ẹrù rẹ tó ò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn.

ÀWỌN TÓ Ń FIPÁ BÁNI LÒ PỌ̀

Bí wọ́n ṣe ń ṣọṣẹ́. Àwọn tó ń fipá báni lò pọ̀ máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn, wọ́n tún máa ń kó jìnnìjìnnì bá wọn, wọ́n sì máa ń fipá bá àwọn èèyàn ṣe oríṣiríṣi ìṣekúṣe.

Àkóbá tí wọ́n máa ń ṣe. Ẹnì kan tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ rí sọ pé: “Kì í ṣe ìgbà tó ṣẹlẹ̀ yẹn nìkan ni wàá mọ̀ ọ́n lára. Ọgbẹ́ yẹn kì í kúrò lọ́kàn ẹni bọ̀rọ̀, ó sì máa ń máyé súni. Kódà, àwọn èèyàn rẹ gan-an á mọ̀ ọ́n lára.” Ohun kan tó dájú ni pé ẹni tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ kọ́ ló máa ń jẹ̀bi, ẹni tó fipá bá ẹlòmìí lò pọ̀ ló máa ń jẹ̀bi.

Ohun tó o lè ṣe

 • Tètè wá nǹkan ṣe tára bá ti ń fu ẹ́. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní ìpínlẹ̀ North Carolina lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Bó o bá rí i pé ara rẹ kò balẹ̀ tàbí tí ara ń fun ẹ́ níbì kan, tètè fi ibẹ̀ sílẹ̀ kíá. Tí o bá ń ronú pé ó yẹ kó o kúrò, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn ẹ́ pé kó o dúró síbẹ̀.”

 • Lo ìgboyà, kó o sì tara ṣàṣà. Àwọn tí kò fura tí kò sì dákan mọ̀ ni àwọn tó ń fipá báni lòpọ̀ sábà máa ń wá láti ṣe lọ́ṣẹ́. Jẹ́ kí ìrìn rẹ fi hàn pé o mohun tí ò ń ṣe, kó o sì máa kíyè sí ohun tó ń lọ láyìíká rẹ.

 • Tètè ṣe ohun tó yẹ. Pariwo. (Diutarónómì 22:25-27) Sá kúrò tàbí kó o gbèjà ara rẹ nípa ṣíṣe ohun tó máa dẹ́rù ba ọ̀daràn náà. Tó bá ṣeé ṣe, sá lọ síbi tí ọkàn rẹ ti máa balẹ̀, kó o sì tètè pe ọlọ́pàá. *

ÀWỌN ONÍJÌBÌTÌ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ

Bí wọ́n ṣe ń ṣọṣẹ́. Jìbìtì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ń tọká sí gbogbo ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn ń hù lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lára rẹ̀ ni lílu jìbìtì owó orí, kíkó owó ìrànwọ́ aráàlú jẹ, fífi káàdì tí wọ́n fi ń rajà àwìn lu jìbìtì àti gbígba owó ọjà tí wọn ò tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó tún kan àwọn gbájú ẹ̀ lóríṣiríṣi, irú bí àwọn tó ń ṣòwò jìbìtì àtàwọn tó ń ta ọjà bàsá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Àkóbá tí wọ́n máa ń ṣe. Àìmọye bílíọ̀nù owó làwọn oníjìbìtì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń fi èrú gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Sandra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, lẹ́tà náà jọ èyí tó máa ń wá láti báńkì tó tọ́jú owó sí. Wọ́n ní ìsọfúnni tó fún àwọn nípa bó ṣe ń lo àkáǹtì rẹ̀ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì kò kún tó, torí náà kó fi àwọn ìsọfúnni kan ránṣẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló rí àtẹ̀jíṣẹ́ pé wọ́n ti yọ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin owó dọ́là [$4,000] kúrò nínú àkáǹtì rẹ̀. Ìgbà yẹn ló tó mọ̀ pé àwọn gbájú ẹ̀ ti lu òun ní jìbìtì.

Ohun tó o lè ṣe

 • Máa ṣóra! Gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà, gbogbo ìkànnì tó dára lójú kọ́ ni ojúlówó. Má gbàgbé pé ojúlówó ilé iṣẹ́ ìdókòwò kò ní sọ pé kó o fi ìsọfúnni pàtàkì nípa àkáǹtì rẹ ránṣẹ́. Kó o tó dókòwò tàbí ra ọjà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, rí i pé o wádìí dáadáa nípa iléeṣẹ́ tó o fẹ́ bá dòwò pọ̀. Ìwé Òwe 14:15 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀.” Ó tún yẹ kó o ṣọ́ra tó o bá ń bá iléeṣẹ́ tó wà nílẹ̀ òkèèrè dòwò pọ̀. Torí tí ìṣòro bá yọjú, ó lè má rọrùn láti yanjú rẹ̀.

 • Wádìí nípa iléeṣẹ́ náà àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni àdírẹ́sì ilé iṣẹ́ náà? Ṣé ojúlówó ni nọ́ńbà tẹlifóònù wọn? Ṣé gbogbo owó tí mo bá san ló máa dé ọ̀dọ̀ wọn? Ìgbà wo ni wọ́n máa kó ọjà mi wá? Ṣé wọ́n máa dá owó mi pa dà tí mi ò bá fẹ́ ra ọjà náà mọ́?’

 • Ṣọ́ra fún àwọn ìpolówó tó dà bí ìfà. Àwọn olójú kòkòrò àtàwọn tí kò fẹ́ làágùn kí wọ́n tó rówó sábà máa ń ṣe kòńgẹ́ àwọn oníjìbìtì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wọ́n lè sọ fún wọn pé àwọn á fún wọn lówó tabua nídìí iṣẹ́ kékeré kan, pé àwọn á ta ọjà fún wọn láwìn tàbí pé àwọn á yá wọn lówó tí wọn ò bá tiẹ̀ ní ohun tí wọ́n lè fi dúró. Kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ pé tí àwọn èèyàn bá fi owó táṣẹ́rẹ́ ṣòwò, wọ́n á rí èrè gọbọi. Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìṣòwò Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Rí i pé o fara balẹ̀ wádìí nípa òwò èyíkéyìí tí wọ́n bá fi lọ̀ ẹ́. Bí èrè tí wọ́n ṣèlérí bá ṣe pọ̀ tó náà ni ewu tó máa wà nínú irú òwò bẹ́ẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń ṣe agbódegbà irú ìdókòwò bẹ́ẹ̀ fọgbọ́n tàn ẹ́ láti kówó sórí òwò kan kó o tó ṣèwádìí tó yẹ nípa rẹ̀.”

ÀWỌN TÓ Ń JÍ ÌSỌFÚNNI

Bí wọ́n ṣe ń ṣọṣẹ́. Àwọn tó ń jí ìsọfúnni tó jẹ́ ti ẹlòmíì sábà máa ń gba ìsọfúnni tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, wọ́n sì máa ń fi lu àwọn èèyàn ní jìbìtì tàbí kí wọ́n fi hùwà ọ̀daràn míì.

Àkóbá tí wọ́n máa ń ṣe. Àwọn olè lè lo orúkọ rẹ láti fi yáwó tàbí láti fi gba káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn tàbí kí wọ́n fi ṣí àkáǹtì sí báńkì. Wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ dá gbèsè ńlá sí ẹ lọ́rùn! Kódà tó o bá tiẹ̀ bọ́ nínú gbèsè yẹn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n lè ti bà ẹ́ lórúkọ jẹ́ jìnnà. Ẹnì kan tó kó sọ́wọ́ irú àwọn ọ̀daràn yìí sọ pé: “Bí àwọn ọ̀daràn bá sọni di ẹdun arinlẹ̀ tán, àkóbá tó máa ń ṣe burú ju kí wọ́n jáwó gbà lọ́wọ́ ẹni lọ.”

Ohun tó o lè ṣe

 • Má ṣe jẹ́ kí ìsọfúnni pàtàkì bọ́ sọ́wọ́ ẹni tí kò yẹ. Tó o bá ń ra ọjà tàbí tí ò ń wo àkáǹtì tó o ní sí báńkì látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, rí i pé ò ń yí ọ̀rọ̀ ìwọlé (ìyẹn password) rẹ pa dà déédéé, pàápàá táwọn ẹlòmíì bá tún ń lo kọ̀ǹpútà kan náà. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, máa ṣọ́ra fún àwọn lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n bá fi ń béèrè fún àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó jẹ́ ti ara ẹni.

  Kì í ṣe kọ̀ǹpútà nìkan làwọn olè tó ń jí ìsọfúnni máa ń lò. Wọ́n tún máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ àwọn ìsọfúnni pàtàkì, irú bí ìwé àkọsílẹ̀ nípa bí owó ṣe ń wọ inú àkáǹtì rẹ àti bó ṣe ń jáde, ìwé sọ̀wédowó, káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn àti nọ́ńbà ìdánimọ̀ rẹ. Torí náà, rí i pé o tọ́jú àwọn ìsọfúnni yìí dáadáa, kó o sì máa ya gbogbo èyí tí kò bá wúlò lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ sí wẹ́wẹ́ kó o tó sọ ọ́ nù. Tí ọ̀kan lára ìwé tí ìsọfúnni pàtàkì wà nínú rẹ̀ bá sọ nù, rí i pé o tètè sọ fáwọn aláṣẹ.

 • Máa yẹ àkáǹtì rẹ wò déédéé. Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìṣòwò Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Tó o bá mọ ohun tó ń lọ, wàá lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ . . . àwọn tó ń jí ìsọfúnni. Tó o bá tètè fura sí ẹni tó fẹ́ jí ìsọfúnni nípa rẹ, o kò ní kábàámọ̀.” Torí náà, máa ṣàyẹ̀wò ìwé àkọsílẹ̀ nípa bí owó ṣe ń wọ inú àkáǹtì rẹ àti bó ṣe ń jáde, kó o sì máa kíyè sí ohun tó bá rú ẹ lójú níbẹ̀.

Òótọ́ ni pé láyé tá a wà yìí, èèyàn ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun ò ní kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn. Àwọn tó ń ṣọ́ra lójú méjèèjì pàápàá ti kó sọ́wọ́ wọn. Àmọ́, àǹfààní tó pọ̀ wà nínú ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì. Ìwé Mímọ́ tiẹ̀ sọ pé: “Má fi í sílẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́. Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” (Òwe 4:6) Bíbélì sì tún sọ ìròyìn ayọ̀ kan fún wa pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ọ̀daràn.

Ìwà Ọ̀daràn Máa Tó Dópin

Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú ìwà ọ̀daràn kúrò? Wo àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí:

 • Ọlọ́run fẹ́ fòpin sí ìwà ọ̀daràn. “Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, mo kórìíra ìjanilólè pa pọ̀ pẹ̀lú àìṣòdodo.”—Aísáyà 61:8.

 • Ó ní agbára láti fòpin sí ìwà ọ̀daràn. “Ó ga ní agbára, Òun kì yóò sì fi ojú kékeré wo ìdájọ́ òdodo àti ọ̀pọ̀ yanturu òdodo.”—Jóòbù 37:23.

 • Ó ṣèlérí pé òun máa pa àwọn èèyàn burúkú run, òun á sì dá àwọn olódodo sí. “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò.” “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:9, 29.

 • Ó ṣèlérí ayé tuntun àlàáfíà fún àwọn olóòótọ́. “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ ẹ́ lọ́kàn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe kúkú fara balẹ̀ ka Bíbélì kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run tún fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn. Kò sí ìwé míì tí àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó wà nínú rẹ̀ pọ̀ tó ti Bíbélì. Kò sí ìwé míì tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó Bíbélì nípa ìgbà tí ìwà ọ̀daràn kò ní sí mọ́. *

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 22 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ sábà máa ń mọ ẹni tó ṣe iṣẹ́ ibi yẹn. Wo àkòrí tá a pè ní, “Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?” ní ojú ìwé 228 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 1. O lè rí ìwé náà lórí ìkànnì www.jw.org.

^ ìpínrọ̀ 44 Lọ wo àlàyé púpọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Gba ẹ̀dà kan lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí kó o lọ kà á lórí ìkànnì www.jw.org.