Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́

Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́

Irú ara wo ni Ọlọ́run ní?

“Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.”—Jòhánú 4:24.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀mí. (2 Kọ́ríńtì 3:17) Torí náà, a kò lè fi wé àwa èèyàn rárá, ó sì jù wá lọ fíìfíì. 1 Tímótì 1:17 pè é ní, “Ọba ayérayé, tí kò lè díbàjẹ́, tí a kò lè rí.” Bíbélì tún sọ pé, “Kò tíì sí ìgbà kan rí tí ẹnikẹ́ni rí Ọlọ́run.”—1 Jòhánù 4:12.

Ẹlẹ́dàá wa jù wá lọ débi pé ó máa ṣòro gan-an fún wa láti fojú inú wo bó ṣe rí. Aísáyà 40:18 sọ pé: “Ta sì ni ẹ lè fi Ọlọ́run wé, ohun ìrí wo sì ni ẹ lè mú kí ó bá a dọ́gba?” Kódà, a ò lè fi Ọlọ́run Olódùmarè wé àgbàyanu ọ̀run tó tẹ́ lọ rẹrẹ.—Aísáyà 40:22, 26.

Àmọ́ àwọn ẹ̀dá onílàákàyè kan wà tó lè rí Ọlọ́run, tí wọ́n sì lè bá a sọ̀rọ̀ lójú kojú. Kí ló jẹ́ kí wọ́n lè rí Ọlọ́run? Torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí làwọn náà, ọ̀run ni wọ́n sì ń gbé. (1 Àwọn Ọba 22:21; Hébérù 1:7) Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ni Bíbélì pè ní áńgẹ́lì, wọ́n lágbára ju àwa èèyàn lọ. Jésù sọ nípa wọn pé wọ́n “ń wo ojú Baba [òun] tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 18:10.

Ṣé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà lóòótọ́?

“Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.’”—Mátíù 6:9.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kò sọ pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run máa ń wà nígbà gbogbo bí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ kárí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú ìwé Mátíù 6:9 àti 18:10 Jésù pe Ọlọ́run ní “Baba,” ó sì sọ pé ọ̀run ló ń gbé. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, ọ̀run sì ni “ibùgbé” rẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 8:43, Bíbélì Mímọ́.

Nígbà tí àkókò tí Jésù fẹ́ lò lórí ilẹ̀ ayé ń parí lọ, ó ní: “Mo ń fi ayé sílẹ̀, mo sì ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 16:28) Lẹ́yìn tí Kristi kú gẹ́gẹ́ bí èèyàn tó sì wá jíǹde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, ó lọ “sí ọ̀run, . . . láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀.Hébérù 9:24.

Òtítọ́ ni àwọn ohun tá a sọ yìí jẹ́ nípa Ọlọ́run, ó sì ṣe pàtàkì ká mọ̀ wọ́n. Kí nìdí? Torí pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, a lè mọ̀ ọ́n, ká sì sún mọ́ ọn. (Jákọ́bù 4:8) Yàtọ̀ síyẹn, òtítọ́ tá a bá kọ́ nípa Ọlọ́run lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké, irú bí ìjọsìn ère. 1 Jòhánù 5:21 sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”

Báwo ni àwa èèyàn ṣe jẹ́ àwòrán Ọlọ́run?

“Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àwa èèyàn lè fìwà jọ Ọlọ́run, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, tí a kì í rẹ́ wọn jẹ, tá a sì ń fọgbọ́n hùwà. Kódà Bíbélì sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—Éfésù 5:1, 2.

Ọlọ́run kì í fipá mú wa ṣe ohunkóhun, ó fún wa lómìnira láti yan ohun rere dípò búburú, ó tún kọ́ wa bá a ṣe lè fi hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) Ó fún wa ní ọpọlọ tá a lè fi ṣe onírúurú nǹkan ká sì ronú lórí àwọn nǹkan mèremère tó wà láyìíká wa, ká sì tún mọyì wọn. Pabanbarì rẹ̀ ni pé, a tún máa ń fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, a máa ń fẹ́ mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá wa àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ ọ̀la.—Mátíù 5:3.

Àǹfààní tí òtítọ́ inú Bíbélì máa ṣe fún ẹ. Bó o bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó, tó o sì ń fara wé e, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Wàá sì ní ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn, àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Aísáyà 48:17, 18) Ọlọ́run mọ̀ dájú pé inú àwa èèyàn dùn sí bí òun ṣe ń ṣe sí wa, èyí sì ń mú ká túbọ̀ máa sún mọ́ ọn, ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.—Jòhánù 6:44; 17:3.