Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APA 9

Ẹ̀kọ́ tí A Lè Rí Kọ́ Lára Mèsáyà Tó Jẹ́ Aṣáájú

Ẹ̀kọ́ tí A Lè Rí Kọ́ Lára Mèsáyà Tó Jẹ́ Aṣáájú

ỌLỌ́RUN sọ ọ́ ṣáájú pé òun máa fi Mèsáyà ṣe Aṣáájú gbogbo èèyàn. Ọlọ́run mọ irú aṣáájú tó máa ṣe wá ní àǹfààní gan-an, ó sì yan ẹni tó jẹ́ Aṣáájú tó dára jù lọ. Irú aṣáájú wo ni Mèsáyà wá jẹ́? Ṣé ọ̀gá ológun tó lágbára gan-an ni? Ṣé olóṣèlú tó mọ ètò ìlú ṣe gan-an ni? Ṣé onímọ̀ nípa ọgbọ́n orí ni? Rárá o. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Mèsáyà jẹ́ wòlíì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, àti pé Jésù Kristi ni Mèsáyà yìí.—Mátíù 23:10.

Ọlọ́run mú kí wọ́n bí Jésù ní ẹni pípé àti ẹni tó jẹ́ mímọ́. Lẹ́yìn náà, Sátánì wá gbogbo ọ̀nà láti ṣi Jésù lọ́nà, àmọ́ Jésù kò gbà kí ó ṣi òun lọ́nà rárá. Nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe, Jésù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, pàápàá nínú bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára rẹ̀, bó ṣe ń ṣe ìdájọ́ òdodo, bó ṣe ń lo ọgbọ́n àti ìfẹ́. Wo àwọn ohun rere tí a lè rí kọ́ lára Jésù.

Jésù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ gan-an

Ó lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lógún gan-an, ó sì lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́ dáadáa. Jésù sọ pé: “Àánú ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí, nítorí pé . . . wọn kò . . . ní nǹkan kan láti jẹ.” (Máàkù 8:2) Lẹ́yìn náà, Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu láti mú kí oúnjẹ wà fún àwọn èèyàn rẹpẹtẹ yẹn tó pé jọ láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń kọ́ni.

Jésù tún rin ìrìn àjò káàkiri láti kọ́ni nípa Ọlọ́run, “ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara láàárín àwọn ènìyàn.” (Mátíù 4:23) Nítorí náà, àwọn èèyàn púpọ̀ ń tẹ̀ lé e káàkiri, “gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà sì ń wá ọ̀nà láti fọwọ́ kàn án, nítorí pé agbára ń jáde lọ láti ara rẹ̀, ó sì ń mú gbogbo wọn lára dá.” (Lúùkù 6:19) Èyí fi hàn pé bí Jésù ṣe wá sí ayé, “kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) * Mélòó nínú àwọn èèyàn tó jẹ́ aṣáájú ló fi ara wọn jin àwọn èèyàn bíi ti Jésù yìí?

Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọdé

Ohun tó bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu ló máa ń ṣe. Ohun tí àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run sọ ni Jésù ṣe, kò yà kúrò nínú rẹ̀. Jésù wá fi ìwà rẹ̀ sọ ohun tí Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, ó sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sáàmù 40:8) Jésù ṣe bí Ọlọ́run ṣe máa ń ṣe sí gbogbo èèyàn, ní ti pé ó ń pọ́n gbogbo èèyàn lé, ó fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n, kò sì ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà, ọkùnrin tàbí obìnrin, ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Nígbà kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá àwọn òbí kan wí torí pé wọ́n ń gbé ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ Jésù. Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”—Máàkù 10:14.

Ó jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run dìídì fún ní ọgbọ́n. Jésù mọ ìwà àwa èèyàn gan-an. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Òun tìkára rẹ̀ mọ ohun tí ó wà nínú ènìyàn.” (Jòhánù 2:25) Kódà, nígbà tí àwọn ọ̀tá Jésù rán àwọn kan pé kí wọ́n lọ mú Jésù, àwọn tí wọ́n rán lọ pa dà wá jíṣẹ́ fún wọn pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Kí ni Jésù sọ nípa ibi tó ti rí ọgbọ́n rẹ̀? Jésù sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 7:16, 46.

Jésù ṣàánú àwọn aláìsàn, ó wò wọ́n sàn

Jésù fìwà jọ Ọlọ́run nínú bó ṣe ní ìfẹ́ àwọn èèyàn. Jésù máa ń ṣàánú àwọn èèyàn gan-an. Ọkùnrin kan “tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀” bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Àánú ọkùnrin yìí ṣe Jésù gan-an, “ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀.” (Lúùkù 5:12, 13; Máàkù 1:41, 42) Ó wu Jésù gan-an láti gba adẹ́tẹ̀ yìí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà tó ń jẹ ẹ́.

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tìrẹ náà jẹ Jésù lógún? Jésù fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.”—Mátíù 11:28, 29.

Kò tún sí Aṣáájú mìíràn tí àwa èèyàn lè ní tó lè dára tó Jésù. Ìdí nìyẹn tó fi gbà wá níyànjú pé, ẹ “kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” Ṣé ìwọ yóò kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù bó ṣe fi ìdùnnú ké sí ọ pé kó o wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun yìí? Tí o bá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ wàá ní ayọ̀.

^ ìpínrọ̀ 6 Bí o bá fẹ́ àlàyé lórí ọ̀rọ̀ ìràpadà, wo orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?