Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀

Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé bí àwọn èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ ṣe lè láyọ̀ tí wọ́n bá lè mú kí ìgbàgbọ́ wọn jinlẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ń da ọkàn wọ́n láàmú.

APÁ 1

Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Wa Jẹ Ọlọ́run Lógún?

Ìṣòro pọ̀ láyé lónìí. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ní àwọn nǹkan tí ò ń ṣe àníyàn lé lórí. Ta ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wa tiẹ̀ jẹ ẹnì kankan lógún?

APÁ 2

Kí Ni Ìgbàgbọ́ Òdodo?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń hùwà láabi. Èyí fí hàn pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ òdodo ju pé kó ṣáà ti gbà pé Ọlọ́run wà.

APÁ 3

Ìtọ́sọ́nà Rere Tó Ń Mú Kí Ayé Ẹni Dára

Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wà nínú Ìwé Mímọ́ tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ, kó o kápá ìbínú, kó o jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, kó o borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, kó o sì jáwọ́ nínú ìwà ipá àtàwọn ìṣòro míì.

APÁ 4

Ta Ni Ọlọ́run?

Oríṣiríṣi òrìṣà ni àwọn èèyàn ń jọ́sìn, àmọ́ Ìwé Mímọ kọ́ wa pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà.

APÁ 5

Mọyì Àwọn Ìwà Dáadáa tí Ọlọ́run Ní

Ìwé Mímọ́ sọ púpọ̀ nínú ìwà tó dáa gan-an tí Ọlọ́run ní, èyí tó jẹ́ ká lè mọ Ọlọ́run.

APÁ 6

Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé??

Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run “kò wulẹ̀ dá [ayé] lásán, [ṣe ni] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” Àmọ́ ṣe bí ayé ṣe rí lónìí ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí lóòótọ́?

APÁ 7

Ìlérí tí Ọlọ́run Ṣe Láti Ẹnu Àwọn Wòlíì

Ìbùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé!

APÁ 8

Mèsáyà Dé

Ìwé Mímọ́ sọ fún wa nípa ìgbésí ayé rẹ̀ àtàwọn ohun tó kọ́ni.

APÁ 9

Ẹ̀kọ́ tí A Lè Rí Kọ́ Lára Mèsáyà Tó Jẹ́ Aṣáájú

Ọlọ́run mọ irú aṣáájú tó máa ṣe wá láǹfààní gan-an, Aṣáájú tí kò lẹ́gbẹ́ ló sì fún wa.

APÁ 10

Ta Ni Ọ̀tá Ìgbàgbọ́ Òdodo?

Áńgẹ́lì kan sọ ara rẹ̀ di alátakò Ọlọ́run.

APÁ 11

Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo Lóde Òní

Jésù sọ pé àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń so “èso àtàtà”, tàbí ìwà rere. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà náà?

APÁ 12

Fi Hàn Pé O Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo!

Kí lo lè máa ṣe láti kọjú ìjà sí Èṣù?

APÁ 13

Ìgbàgbọ́ Òdodo Máa Mú Kí O Ní Ayọ̀ Ayérayé

Ìlérí kan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó kan ìwọ náà