Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 APA 11

Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo Lóde Òní

Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo Lóde Òní

LÓDE òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́. Àmọ́ Jésù sọ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló máa ní ìgbàgbọ́ tó jẹ́ ìgbàgbọ́ òdodo. Ó sọ pé: “Fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.

Báwo la ṣe lè mọ àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo lóde òní? Jésù sọ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀ . . . Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde.” (Mátíù 7:16, 17) Èyí fi hàn pé “èso àtàtà” ni ìgbàgbọ́ òdodo máa ń so. Ìyẹn ni pé ó ń mú kéèyàn máa hu àwọn ìwà tí Ọlọ́run fẹ́. Bí irú àwọn ìwà wo?

Wọn Kì Í Ṣi Agbára Lò

Àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń lo agbára àti àṣẹ tí wọ́n bá ní láti fi gbé Ọlọ́run ga, wọ́n sì máa fi ń ṣe ọmọnìkejì wọn lóore. Jésù kọ́ wa pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Máàkù 10:43) Bákan náà, àwọn ọkùnrin tó ní ìgbàgbọ́ òdodo kì í hùwà ìkà sí àwọn tó wà ní abẹ́ àṣẹ wọn, yálà nínú ilé wọn tàbí níbòmíràn. Wọ́n máa ń ṣìkẹ́ aya wọn, wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì máa ń fi ìfẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.”—1 Pétérù 3:7.

Bákan náà, aya tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo gbọ́dọ̀ “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Àwọn aya gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn” kí wọ́n sì “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.” (Títù 2:4) Àwọn bàbá àti ìyá tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo máa rí i dájú pé àwọn ń rí àyè gbọ́ ti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì máa ń kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣe àpọ́nlé àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n, yálà ní ilé tàbí ibi iṣẹ́ tàbí ní ibikíbi. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí, pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.

Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìṣítí tí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kí o má [ṣe] gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Ẹ́kísódù 23:8) Wọn kì í hùwà àbòsí tàbí ìwà ìrẹ́jẹ ní ipòkípò tí wọ́n bá wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Torí náà, wọ́n máa ń rí ẹ̀san tí Jésù sọ pé ó wà fún irú èèyàn bíi tiwọn, ó ní: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Wọ́n Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Bí Ọlọ́run Ṣe Là Á Kalẹ̀

Àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń fínnúfíndọ̀ tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run, lójú tiwọn  sì rèé, “àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Wọ́n mọ̀ dájú pé “òfin Jèhófà pé . . . Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.”—Sáàmù 19:7, 8.

Nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo, wọ́n kórìíra gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ṣíṣe ẹ̀tanú. Wọn kì í gbé ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan tàbí àwọn èèyàn kan ga ju àwọn míì lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Ọlọ́run ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Nítorí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Ìgbàgbọ́ òdodo ń mú kéèyàn máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo kì í bani jẹ́ tàbí kó máa sọ̀rọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀ láìdáa. Ìwé Sáàmù kan tí Dáfídì kọ sọ irú èèyàn tí Ọlọ́run máa ń dunnú sí, ó ní ẹni náà: “Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́, kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”—Sáàmù 15:3.

Wọ́n Ń Ṣe Ohun Tó Bá Ọgbọ́n Ọlọ́run Mu

Ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nìkan ṣoṣo ni àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń tẹ̀ lé nínú ẹ̀sìn wọn. Wọ́n gbà gbọ́ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Wọ́n máa ń rí i dájú pé ìwà tó bá “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” mu nìkan ni àwọn ń hù sí ọmọnìkejì wọn, torí “ọgbọ́n” yìí máa ń “mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere.” (Jákọ́bù 3:17) Wọ́n máa ń kórìíra àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti àṣà ẹ̀sìn tí Ọlọ́run kò dunnú sí, wọn kì í lọ́wọ́ sí ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀mí òkùnkùn, wọ́n sì máa ń “ṣọ́ra fún [bíbọ] òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.

Wọ́n Ní Ojúlówó Ìfẹ́

Mósè tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5) Bí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ òdodo sì ṣe máa ń fẹ́ràn Ọlọ́run nìyẹn. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Wọ́n máa ń “fi ọpẹ́ fún Jèhófà,” wọ́n sì máa ń “ké pe orúkọ rẹ̀,” torí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé ó ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn. (Sáàmù 105:1) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tún máa ń tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Wọ́n kórìíra ìwà jàgídíjàgan, wọ́n sì máa ń rí i pé àwọn “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Wọn kò “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́,” torí náà a lè ṣe àkàwé ìwà wọn lọ́nà báyìí pé, wọ́n ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” wọ́n sì “fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” (Aísáyà 2:4) Nítorí èyí, wọ́n “ní ìfẹ́ láàárín ara” wọn, wọ́n sì ń hùwà bí ọmọ ìyá sí ara wọn ní gbogbo ibi tí wọ́n bá wà kárí ayé. (Jòhánù 13:35) Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ àwọn èèyàn kan tó ní irú ìwà wọ̀nyí lóde òní?