Àkọsílẹ̀ Lúùkù 5:1-39

  • Wọ́n rí ẹja kó lọ́nà ìyanu; àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́ (1-11)

  • Ó wo adẹ́tẹ̀ sàn (12-16)

  • Jésù wo alárùn rọpárọsẹ̀ sàn (17-26)

  • Jésù pe Léfì (27-32)

  • Ìbéèrè nípa ààwẹ̀ (33-39)

5  Nígbà kan tí àwọn èrò ń fún mọ́ ọn, tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún omi Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.*+  Ó sì rí ọkọ̀ ojú omi méjì tó gúnlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ adágún náà, àmọ́ àwọn apẹja ti jáde kúrò nínú wọn, wọ́n sì ń fọ àwọ̀n wọn.+  Ó wọnú ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, èyí tó jẹ́ ti Símónì, ó sì sọ fún un pé kó wa ọkọ̀ náà lọ síwájú díẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀. Ó wá jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èrò náà látinú ọkọ̀ ojú omi náà.  Nígbà tó sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Símónì pé: “Wa ọkọ̀ lọ síbi tí omi ti jìn, kí ẹ sì rọ àwọ̀n yín sísàlẹ̀ láti kó ẹja.”  Àmọ́ Símónì fèsì pé: “Olùkọ́, gbogbo òru la fi ṣiṣẹ́ kára, a ò sì rí nǹkan kan mú,+ ṣùgbọ́n torí ohun tí o sọ, màá rọ àwọ̀n náà sísàlẹ̀.”  Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja ni wọ́n kó.* Kódà, àwọ̀n wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fà ya.+  Torí náà, wọ́n ṣẹ́wọ́ sí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, nínú ọkọ̀ ojú omi kejì, pé kí wọ́n wá ran àwọn lọ́wọ́, wọ́n wá, wọ́n sì rọ́ ẹja kún inú ọkọ̀ méjèèjì, débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.  Nígbà tí Símónì Pétérù rí èyí, ó wólẹ̀ síbi orúnkún Jésù, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Olúwa, torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”  Ìdí ni pé ẹnu ya òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gan-an torí bí ẹja tí wọ́n kó ṣe pọ̀ tó, 10  bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí lára Jémíìsì àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè,+ tí àwọn àti Símónì jọ ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ Jésù sọ fún Símónì pé: “Má bẹ̀rù mọ́. Láti ìsinsìnyí lọ, wàá máa mú àwọn èèyàn láàyè.”+ 11  Wọ́n wá dá àwọn ọkọ̀ ojú omi náà pa dà sórí ilẹ̀, wọ́n pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 12  Ní àkókò míì, nígbà tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú náà, wò ó! ọkùnrin kan wà tí ẹ̀tẹ̀ bò! Nígbà tó tajú kán rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 13  Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀.+ 14  Ó wá pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni, ó ní: “Àmọ́ lọ, kí o fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì ṣe ọrẹ láti wẹ̀ ọ́ mọ́, bí Mósè ṣe sọ,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 15  Àmọ́ ìròyìn rẹ̀ ń tàn káàkiri ṣáá, èrò rẹpẹtẹ sì máa ń kóra jọ kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó sì lè wò wọ́n sàn.+ 16  Ṣùgbọ́n ó sábà máa ń lọ sí àwọn ibi tó dá láti gbàdúrà. 17  Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ Òfin tí wọ́n wá láti gbogbo abúlé Gálílì àti Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù jókòó níbẹ̀; agbára Jèhófà* sì wà lára rẹ̀ láti wo àwọn èèyàn sàn.+ 18  Wò ó! àwọn ọkùnrin kan fi ibùsùn gbé ọkùnrin kan tó ní àrùn rọpárọsẹ̀, wọ́n sì ń gbìyànjú láti gbé e wọlé, kí wọ́n lè gbé e síwájú Jésù.+ 19  Torí náà, nígbà tí wọn ò rí ọ̀nà gbé e wọlé torí àwọn èrò náà, wọ́n gun orí òrùlé, wọ́n sì fi ibùsùn náà sọ̀ ọ́ kalẹ̀ gba àárín ohun tí wọ́n fi bo ilé náà, wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ sí àárín àwọn tó wà níwájú Jésù. 20  Nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní, ó sọ pé: “Ọkùnrin yìí, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 21  Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó, wọ́n ń sọ pé: “Ta lẹni tó ń sọ̀rọ̀ òdì yìí? Ta ló lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 22  Àmọ́ Jésù fòye mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó sì dá wọn lóhùn pé: “Kí lẹ̀ ń rò lọ́kàn yín? 23  Èwo ló rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’? 24  Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn ní àṣẹ ní ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún ọkùnrin tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.”+ 25  Ló bá dìde níwájú wọn, ó gbé ohun tó ti ń dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọ́run lógo. 26  Ẹnu ya gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé: “A ti rí àwọn nǹkan àgbàyanu lónìí!” 27  Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ, ó sì rí agbowó orí kan tó ń jẹ́ Léfì, tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”+ 28  Ló bá fi ohun gbogbo sílẹ̀, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. 29  Léfì wá gbà á lálejò, ó se àsè rẹpẹtẹ fún un nílé rẹ̀, àwọn agbowó orí àti àwọn míì tó ń bá wọn jẹun* sì pọ̀ gan-an níbẹ̀.+ 30  Ni àwọn Farisí àti àwọn tó jẹ́ akọ̀wé òfin lára wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, tí ẹ sì ń bá wọn mu?”+ 31  Jésù fún wọn lésì pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.+ 32  Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè kí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+ 33  Wọ́n sọ fún un pé: “Léraléra ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù máa ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n sì ń mu.”+ 34  Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ò lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó gbààwẹ̀ tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀? 35  Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó+ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní tòótọ́; wọ́n máa wá gbààwẹ̀ láwọn ọjọ́ yẹn.”+ 36  Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Kò sí ẹni tó máa gé lára aṣọ àwọ̀lékè tuntun, kó sì rán ègé náà mọ́ ara aṣọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ègé aṣọ tuntun náà máa ya kúrò, aṣọ tí wọ́n gé lára aṣọ tuntun náà kò sì ní bá èyí tó ti gbó mu.+ 37  Bákan náà, kò sí ẹni tó máa rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wáìnì tuntun náà máa bẹ́ àpò awọ náà, ó máa dà nù, àpò náà sì máa bà jẹ́. 38  Àmọ́ inú àpò awọ tuntun la gbọ́dọ̀ rọ wáìnì tuntun sí. 39  Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tó ti mu wáìnì tó ti pẹ́, torí ó máa sọ pé, ‘Èyí tó ti pẹ́ yẹn dáa.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, Òkun Gálílì.
Tàbí “mú.”
Tàbí “jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú wọn.”