Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ilé Gogoro Bábélì Ni Èdè Wa Ti Bẹ̀rẹ̀?

Ṣé Ilé Gogoro Bábélì Ni Èdè Wa Ti Bẹ̀rẹ̀?

“Jèhófà tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì dẹ́kun títẹ ìlú ńlá náà dó. Ìdí nìyẹn tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ní Bábélì, nítorí pé ibẹ̀ ni Jèhófà ti da èdè gbogbo ilẹ̀ ayé rú.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:8, 9.

ǸJẸ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wáyé lóòótọ́? Ṣé ó dájú pé lójijì ni àwọn èèyàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀? Àwọn kan ò gbà pé òótọ́ ni ìtàn tí Bíbélì sọ nípa bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe di pé ó wà lóríṣiríṣi. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Nínú gbogbo ìtàn tí àwọn èèyàn tíì sọ, ìtàn Ilé Gogoro Bábélì jẹ́ ìtàn àròsọ lásán tí kò nítumọ̀.” Rábì kan tó jẹ́ Júù tiẹ̀ sọ pé ìtàn náà dà bí ọgbọ́n ẹ̀tàn tí aláìmọ̀kan lò láti ṣàlàyé ibí tí gbogbo orílẹ̀-èdè ti bẹ̀rẹ̀.”

Kí nìdí tí àwọn èèyàn kò fi fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Ilé Gogoro Bábélì? Ní ṣókí, ohun tó fà á kò ju pé ó tako àwọn àbá kan nípa bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé kì í ṣe pé onírúurú èdè kàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni àwọn èdè tó wà lónìí jẹ yọ látinú èdè ìbílẹ̀ kan. Àwọn míì sì sọ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn èdè jẹ yọ fúnra wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ látorí kíkùn hùn-hùn títí tí àwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí pe ọ̀rọ̀ jáde. Irú àwọn àbá bẹ́ẹ̀ àtàwọn èrò míì tó ta kora ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fara mọ́ ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n W. T Fitch sọ nínú ìwé rẹ,The Evolution of Language : “A kò tíì rí ìdáhùn tó ń tẹni lọ́rùn sí ọ̀rọ̀ yìí.”

Kí ni àwọn awalẹ̀pìtàn àti àwọn tó ń ṣe ìwádìí ti ṣàwárí nípa bí àwọn èdè tá à ń sọ ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe gbèrú? Ǹjẹ́ ohun tí wọ́n ṣàwárí tiẹ̀ bá ìkankan mu nínú ohun tí àwọn kan ti sọ? Àbí ó jẹ́rìí sí ohun tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ ní Bábélì? Á dáa ká kọ́kọ́ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ.

IBO NI ÌṢẸ̀LẸ̀ YẸN TI WÁYÉ? ÌGBÀ WO SÌ NI?

Bíbélì sọ pé “ilẹ̀ Ṣínárì” tí wọ́n ń pè ní Bábílónì, ni èdè gbogbo ilẹ̀ ayé ti dà rú, ibẹ̀ sì ni Ọlọ́run ti tú àwọn èèyàn ká. (Jẹ́nẹ́sísì 11:2) Ìgbà wo gan-an ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ayé Pélégì ni “a pín gbogbo èèyàn ilẹ̀ ayé níyà.” Ìwádìí sì fi hàn pé àádọ́ta lé rúgba [250] ọdún kí wọ́n tó bí Ábúráhámù ni wọ́n bí Pélégì. Ìyẹn wá túmọ̀ sí pé, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bábélì wáyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lé igba [4,200] ọdún sẹ́yìn.—Jẹ́nẹ́sísì 10:25; 11:18-26.

Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àwọn èdè tá à ń sọ lónìí jẹ yọ láti inú èdè ìbílẹ̀ kan ṣoṣo tí wọ́n gbà pé gbogbo èèyàn mọ̀ tí wọ́n sì ń sọ láti nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ọdún sẹ́yìn. * Àwọn míì tiẹ̀ sọ pé àwọn èdè tá à ń sọ lónìí jọ ọ̀pọ̀ èdè ìbílẹ̀ tí àwọn èèyàn ti ń sọ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn. Báwo wá ni àwọn onímọ̀ èdè ṣe mọ bí àwọn èdè tí kò sí mọ́ lóde òní ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìwé ìròyìn Economist sọ pé: “Ó dà bíi pé ọ̀rọ̀ yẹn ta kókó, torí pé àwọn onímọ̀ èdè kò dà bí àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tó máa ń fi nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n hú jáde nínú ilẹ̀ mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́. Kódà, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìṣirò tí wọ́n kàn fojú bù ni onímọ̀ èdè kan lò láti gbé àlàyé tiẹ̀ kalẹ̀, tó wá já sí pé kò ṣe é gbára lé.”

Àmọ́ ṣá, àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ mọ́ èdè wà tí àwọn èèyàn hú jáde nínu ilẹ̀. Kí ni àwọn nǹkan yẹn? Kí ni wọ́n sì jẹ́ ká mọ̀ nípa bí èdè ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìwé Gbédègbẹ́yọ̀ náà New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin [4,000] sí márùn ún [5,000] ni ìwé àtijọ́ kan ṣoṣo tí wọ́n lè rí tọ́ka sí ti wà.” Ibo wá ni àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwọn àkọ́sílẹ̀ èdè tí wọ́n hú jáde yìí? Apá ìsàlẹ̀ ilẹ̀ Mesopotámíà ni, níbi tí wọ́n ń pè ní Ṣínárì láyé àtijọ́. * Torí náà, ohun tí wọ́n hú jáde yìí fi hàn pé òótọ́ ni àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí.

TÍ ÈDÈ BÁ YÀTỌ̀, ÌRÒNÚ Á YÀTỌ̀

Bíbélì sọ pé ní Bábélì, Ọlọ́run “da èdè wọn rú níbẹ̀, kí wọ́n má bàa gbọ́ [lóye] èdè ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:7) Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn Bábélì ìgbà yẹn kò fi lè ‘tẹ ìlú ńlá náà dó,’ torí pé ibẹ̀ “ni Jèhófà ti tú wọn ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:8, 9) Torí náà, Bíbélì kò sọ pé látinú èdè ìbílẹ̀ kan ṣoṣo ni gbogbo èdè tí à ń sọ lónìí ti ṣẹ̀ wá. Ohun tó sọ ni pé lójijì ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ onírúurú èdè tuntun, tí wọ́n sì ń fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èdè náà ṣàlàyé èrò wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn, lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti èdè míì.

Wàláà tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, tí wọ́n sì kọ nǹkan sí yìí ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kan ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù

Kí ni ká wá sọ nípa àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ní èdè tiwọn lónìí? Ṣé èdè wọn jọra àbí àwọn ìyàtọ̀ kan gbòógì wà láàárín wọn? Lera Boroditsky tó jẹ́ onímọ̀ nípa bí àwa èèyàn ṣe ń ronú sọ pé: “Bí àwọn onímọ̀ èdè ṣe túbọ̀ ń ṣèwádìí jinlẹ̀ lórí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èdè tó wà láyé, èyí tí wọ́n tíì rí ṣàlàyé nínú wọn kò tó nǹkan, wọ́n rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàtọ̀ téèyàn ò tiẹ̀ retí ló wà láàárín àwọn èdè.” Kò sí irọ́ nínú nínú ọ̀rọ̀ yìí o, torí pé èdè kan pàtó lè ní àwọn èdè àdúgbò tiẹ̀, wọ́n sì lè jọra tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, irú bíi Èkìtì àti Ìjẹ̀ṣà nílẹ̀ Yorùbá. Àmọ́ àwọn èdè yìí yàtọ̀ sí àwọn èdè míì tó jọra tí wọ́n ń sọ ní àwọn àdúgbò míì irú bí Fọn àti Gun tí wọ́n ń sọ ní Cotonou.

Èdè tẹ́nì kan ń sọ máa ń nípa lórí bó ṣe ń ronú àti bó ṣe máa ṣàlàyé nǹkan tó yí i ká, irú bí àwọ̀, ìwọ̀n, apá ibi tí nǹkan wà àti bí wọ́n ṣe máa júwe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Tí àwọn méjì tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá fẹ́ sọ ohun kan náà, bí wọ́n á ṣe sọ ọ́ lè yàtọ̀ síra. Ẹnì kan lè sọ pé: “Kòkòrò kan wà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹ.” Àmọ́ ẹnì kejì ní èdè tiẹ̀ lè sọ pé: “Wo kòkòrò wà ní ọwọ́ rẹ lápá gúúsù ìwọ̀ oòrùn.” Irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí àwọn èèyàn máà lóye ara wọn. Abájọ tí àwọn tó ń kọ́ ilé gogoro Bábélì kò fi lè parí ilé náà.

ṢÉ WỌ́N Ń KÙN NI ÀBÍ WỌ́N Ń SỌ̀RỌ̀ GIDI?

Irú èdè wo ni àwọn èèyàn ń sọ ní ìbẹ̀rẹ̀? Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ tuntun ni Ádámù lò nígbà tó ń sọ àwọn ẹranko àti ẹyẹ lórúkọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:20) Ádámù tún ké ewì láti fi sọ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀. Bí Éfà ṣe ṣàlàyé àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wọn àti ohun tó máa yọrí sí tí wọ́n bá ṣàìgbọràn kò lọ́jú pọ̀ rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 2:23; 3:1-3) Èyí fi hàn pé èdè tí àwọn èèyàn ń sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ kún rẹ́rẹ́ débi pé wọ́n lè fi bá ara wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, kí wọ́n sì sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.

Àmọ́, bí èdè àwọn èèyàn ṣe dà rú ní Bábélì kò jẹ́ kí wọ́n lè parí ohun tí wọ́n fi ọgbọ́n gbèrò láti ṣe. Síbẹ̀, ńṣe ni wọn ń sọ èdè lẹ́nu bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ kí èdè wọn tó dà rú. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí èdè dà rú, àwọn èèyàn ti gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe, wọ́n kó àwọn ọmọ ogun jọ, wọ́n kọ́ àwọn ìlú ńlá, wọ́n sì ṣòwò káàkiri ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 13:12; 14:1-11; 37:25) Ó dájú pé wọn kò ní lè ṣe gbogbo èyí láì jẹ́ pé wọ́n lo èdè tó kún rẹ́rẹ́ àti ìlànà èdè tó rọ̀ mọ́ ọn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èdè tí àwọn èèyàn kọ́kọ́ ń sọ àtàwọn èdè míì tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ní Bábélì kì í ṣe ìró lásán tàbí pé wọ́n ń kùn hùn-hùn, èdè gidi ni wọ́n fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.

Ìwádìí tí wọ́n ṣe lónìí fi hàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ṣàlàyé nípa èdè sọ pé: “Nínú ìwádìí tí a ṣe nípa ìbílẹ̀ àwọn èèyàn, a rí i pé bí ó ti wù kí àwọn èèyàn ìbílẹ̀ náà luko tó, gbogbo wọn ló ní èdè tí wọ́n ń sọ. Èdè wọn sì kún rẹ́rẹ́ débi pé a lè fi wọ́n wé èdè tí àwọn èèyàn ń sọ ní àwọn ilẹ̀ tó ti lajú.” Bákan náà, Steven Pinker tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Harvard sọ nínú ìwé rẹ̀ The Language Instinct pé: “Kò sí èdè kankan tí a lè pè ní èdè àtayébáyé.”

ÀYÍPADÀ TÓ MÁA BÁ ÈDÈ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ

Lẹ́yìn tí a ti ṣàyẹ̀wò ìgbà tí wọ́n rí àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ mọ́ èdè àti ibi tí wọ́n ti rí wọn, ìyàtọ̀ tó wà nínú oríṣiríṣi èdè táwọn èèyàn ń sọ àti bí àwọn èdè àtijọ́ ṣe kún rẹ́rẹ́, èrò wo ló yẹ ká ní? Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ pé ó wáyé ní Bábélì jóòótọ́, ó sì ṣeé gbára lé.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run dìídì da èdè àwọn èèyàn rú ní Bábélì torí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 11:4-7) Àmọ́ ṣá, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun “yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefanáyà 3:9) Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni “èdè mímọ́ gaara” yìí, òtítọ́ yìí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn láti ibi gbogbo kárí ayé wà níṣọ̀kan. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé lọ́jọ́ iwájú, Ọlọ́run á mú kí gbogbo aráyé wà ní ìṣọ̀kan, á fún wá ní èdè kan ṣoṣo, á sì fòpin sí ìdàrúdàpọ̀ to bẹ̀rẹ̀ ní Bábélì.

^ ìpínrọ̀ 8 Èrò àwọn onímọ̀ èdè sábà máa ń ti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n lẹ́yìn pé ara ìnàkí ni àwa èèyàn ti wá. Tí o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí wọ́n sọ yìí, ka Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008, ojú ìwé 14-17. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀ àwọn ilé gogoro tó dà bíi tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ ní ìpele-ìpele, ní àyíká ilẹ̀ Ṣínárì. Ìsàlẹ̀ àwọn ilé náà fẹ̀, òkè wọn sì rí ṣóńṣó. Bíbélì sọ pé bíríkì ni àwọn tó kọ́ ilé gogoro náà lò, kì í ṣe òkúta, wọ́n sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì ṣe erùpẹ̀ àpòrọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 11:3, 4) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The New Encyclopædia Britannica jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé nílẹ̀ Mesopotámíà yẹn, òkúta “kò fi bẹ́ẹ̀ sí tàbí kó má tiẹ̀ sí rárá,” àmọ́ ọ̀dà bítúmẹ́nì pọ̀ gan-an níbẹ̀.