Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?

Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?

 Ọrẹ àtinúwá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ló pọ̀ jù lára owó tá à ń ná lórí iṣẹ́ wa kárí ayé. a Àpótí ọrẹ máa ń wà láwọn ilé ìpàdé wa, èèyàn tún lè ṣètìlẹyìn ní apá tá a pè ní Ọrẹ lórí ìkànnì wa. Oríṣiríṣi ọ̀nà lẹnì kan lè gbà fi owó ránṣẹ́ níbẹ̀, yálà láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé tàbí fún ìnáwó ìjọ, ó sì lè jẹ́ fún méjèèjì.

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í san ìdámẹ́wàá, wọn ò sì retí pé kéèyàn ya iye kan sọ́tọ̀ láti máa fi ṣètìlẹyìn. (2 Kọ́ríńtì 9:7) A ò kì í gbé igbá ọrẹ tàbí gba owó ìwọlé, bákan náà àwọn òjíṣẹ́ wa kì í gbowó tí wọ́n bá ṣèrìbọmi fún ẹnì kan, tí wọ́n bá bójú tó ètò ìsìnkú, tí wọ́n bá so tọkọtaya pọ̀ tàbí tí wọ́n bá darí àwọn ètò ìsìn míì. A kì í ná ọjà bàsá, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tàbí àjọ̀dún láti fi kówó jọ, a kì í sì í tọrọ owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. A kì í kéde orúkọ àwọn tó bá ṣètìlẹyìn. (Mátíù 6:2-4) A kì í bá àwọn oníṣòwò polówó ọjà lórí ìkànnì wa tàbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa.

 Oṣooṣù làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ka ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe náwó nínú ìjọ. Wọ́n máa ń tọ́jú àkọsílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń náwó, wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò ẹ̀ lóòrèkóòrè kí wọ́n lè rí i pé wọ́n ná owó táwọn èèyàn fi ṣètìlẹyìn bó ṣe yẹ.—2 Kọ́ríńtì 8:20, 21.

Bá A Ṣe Ń Ṣètọrẹ

 •   Àpótí ọrẹ: A máa ń fi owó tàbí sọ̀wédowó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí àwọn ibi míì tá a ti ń ṣèpàdé.

 •   Ọrẹ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì: Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, èèyàn lè fowó ránṣẹ́, èèyàn lè lo káàdì tí wọ́n fi ń rajà tàbí èyí tí wọ́n fi ń gba owó ní báǹkì, èèyàn sì lè lo àwọn ọ̀nà míì láti ṣètìlẹyìn ní abala “Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí ìkànnì wa. b Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa ń ṣètò pé kí wọ́n máa yọ iye kan pàtó nínú owó wọn lóṣooṣù látorí ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì wa.​—1 Kọ́ríńtì 16:2.

 •   Ọrẹ téèyàn ṣètò sílẹ̀: Àwọn ọrẹ kan gba pé kéèyàn ṣètò ẹ̀ sílẹ̀ tàbí kéèyàn fi tó agbẹjọ́rò létí. Ó ṣeé ṣe kírú ètò bẹ́ẹ̀ dín owó orí tẹ́nì kan máa san kù tàbí kẹ́ni náà má tiẹ̀ san án rárá. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé ó máa ṣe àwọn láǹfààní táwọn bá ṣètò láti máa fi ohun ìní àwọn ṣètìlẹyìn nígbà táwọn ṣì wà láàyè tàbí kó di tẹlòmíì táwọn bá kú. O lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè fowó ránṣẹ́ nípasẹ̀:

  •   àkáǹtì owó ní báǹkì

  •   owó ìbánigbófò àti owó ìfẹ̀yìntì

  •   ilẹ̀ àti ilé

  •   ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ètò ẹ̀yáwó

  •   ìwé ìhágún àti ohun ìní téèyàn fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́

 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ọ̀nà míì tó o lè gbà fi owó ṣètìlẹyìn ládùúgbò rẹ, lọ sí abala “Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

a Ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà lè fi owó ránṣẹ́ láti ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn.