Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Tálákà Ni Wá àmọ́ À Ń Fi Ayọ̀ Sin Ọlọ́run

Tálákà Ni Wá àmọ́ À Ń Fi Ayọ̀ Sin Ọlọ́run

Wọ́n bí mi ní oṣù December ọdún 1939 ní abúlé oko kán tí wọ́n ń pè ní Cotiujeni tó wà ní apá àríwá orílẹ̀-èdè tí a wá mọ̀ sí Moldova lónìí. Inú ilé kan tí wọn ò tíì kọ́ tán ni bàbá mi àti bàbá mi àgbà ń gbé. Láàárín ọdún 1930 sí 1934 ni wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, màmá mi náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n rí i pé bàbá mi àgbà mọ Bíbélì ju àlùfáà tó wà ní abúlé wa lọ.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta, àwọn aláṣẹ fipá mú bàbá mi àti àbúrò rẹ̀ pẹ̀lú bàbá mi àgbà lọ sí àgọ́ tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn èèyàn, torí wọ́n kọ̀ láti dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Bàbá mi nìkan ni kò kú síbẹ̀. Àmọ́ nígbà tó fi máa pa dà wálé lọ́dún 1947, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ó ti kán lẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ ò le mọ́, síbẹ̀, ó jẹ́ olóòótọ́, kò sì yí pa dà kúrò nínú ohun tó gbà gbọ́.

ÀWỌN OHUN TÍ OJÚ WA RÍ

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án, ìdílé wa wà lára àwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ẹlẹ́rìí tí àwọn aláṣẹ kó nígbèkùn lọ sí Siberia láti orílẹ̀-èdè Moldova. Ní July 6, 1949, wọ́n kó wá sínú àwọn ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n fi ń kó ẹran ọ̀sìn. A rin nǹkan tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [6,400] kìlómítà láìdúró fún ọjọ́ méjìlá kí á tó gúnlẹ̀ ní ibùdókọ̀ ojú irin Lebyazhe. Àṣé àwọn ọlọ́pàá àdúgbò ibẹ̀ ti ń dúró dè wá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pín wa sí àwùjọ kéékèèké káàkiri àdúgbò yẹn. Inú ọgbà ilé ìwé kékeré kan tí wọn ò lò mọ́ ni wọ́n kó àwùjọ tí mo wà sí. Ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, ọkàn wa sì bàjẹ́. Bí obìnrin àgbàlagbà kan tó wà láàárín wa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lá orin tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nìyẹn. Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yòókù fi gbe orin yẹn. Ọ̀rọ̀ inú orin náà lọ báyìí pé:

“Ọ̀pọ̀ ará ni wọ́n kó nígbèkùn lọ sí ọ̀nà tó jìn.

Wọ́n kó wọn lọ sí àríwá, wọ́n kó wọn lọ sí ìlà oòrùn.

Ọ̀pọ̀ ìpọ́njú ni wọ́n ní torí pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, ibẹ̀ ni wọ́n ti fara da ikú.”

Láìpẹ́, a bẹ̀rẹ̀ sí kóra jọ síbì kan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọọjọ́ Sunday, ibẹ̀ sì tó ìrìn kìlómítà mẹ́tàlá [13] sí ilé wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àárọ̀ kùtùkùtù la máa ń gbéra lásìkò tí yìnyín máa ń bọ́, yìnyín yìí máa ń pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí á mù wá dé ìbàdí. Ojú ọjọ́ máa ń tutù débi pé èèyàn á fẹ́rẹ̀ẹ́ gan. Inú yàrá kékeré kan ni àwa àádọ́ta [50] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ máa ń rún ara wa mọ́. Orin kan tàbí méjì tàbí mẹ́ta ni a máa ń kọ ká tó bẹ̀rẹ̀. Ẹnì kan máa ṣáájú wa nínú àdúrà, lẹ́yìn náà, àá wá jíròrò àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì. Èyí máa ń gbà wá tó nǹkan bíi wákàtí kan. Lẹ́yìn ìyẹn, àá kọrin bí mélòó kan sí i, àwọn míì tún lè béèrè ìbéèrè, wọ́n á sì fi Bíbélì dá wọn lóhùn. Gbogbo èyí mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára gan-an lásìkò yẹn!

ÀWỌN ÌṢÒRO MÍÌ TÍ A NÍ

Ní ibùdókọ̀ ojú irin tó wà ní ìlú Dzhankoy ní nǹkan bí ọdún 1974

Nígbà tó fi máa di ọdún 1960, òmìnira tí ìjọba fún àwa Ẹlẹ́rìí tó wà nígbèkùn túbọ̀ pọ̀ sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí owó lọ́wọ́ wa, mo ṣáà wọ́nà láti lọ sí Moldova, ibẹ̀ ni mo ti pàdé ọmọbìnrin Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Nina. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn òbí rẹ̀ àti àwọn òbí rẹ̀ àgbà. Nígbà tó yá, a ṣe ìgbéyàwó, a sì pa dà sí Siberia, ibẹ̀ la ti wá bí ọmọbìnrin wa Dina lọ́dún 1964 àti ọmọkùnrin wa Viktor lọ́dún 1966. Lẹ́yìn ọdún méjì, a ṣí lọ sí ìlú Dzhankoy ní orílẹ̀-èdè Ukraine, a sì ń gbé nínú ilé kékeré kan níbẹ̀. Ìlú yẹn jìnnà tó ọgọ́jọ [160] kìlómítà sí ìlú Yalta tó wà ní apá ibi tí ilẹ̀ Crimea ti ya wọnú òkun.

Lásìkò yẹn, ìjọba ṣì fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Crimea, àtàwọn tó wà nílẹ̀ ibòmíì lábẹ́ àkóso ìjọba Soviet Union. Ìjọba ò ká wa lọ́wọ́ kò pátápátá, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣàtakò tó pọ̀ sí wa. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ kí ìtara wọn dín kù nìyẹn. Wọ́n ronú pé ojú àwọn ṣáà ti rí màbo nílẹ̀ Siberia, torí náà táwọn bá tiẹ̀ ṣiṣẹ́ kára láti ní ohun ìní díẹ̀, kí àwọn sì tẹ́ ara àwọn lọ́rùn, kò burú.

ÀWỌN NǸKAN AYỌ̀ TÓ ṢẸLẸ̀

Ní March 27, 1991, ìjọba fàyè gba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin láti máa wàásù, ká sì máa péjọ láti jọ́sìn ní gbogbo ilẹ̀ tó wà ní Soviet Union láyé ìgbà yẹn. Lójú ẹsẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò àpéjọ ńlá ọlọ́jọ́ méjì ní àwọn ibi méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ káàkiri ilẹ̀ tó wà lábẹ́ ìjọba Soviet Union. Àpéjọ tó máa bẹ̀rẹ̀ ní August 24 ní ìlú Odessa nílẹ̀ Ukraine ni wọ́n yàn wá sí pé ká lọ. Ó ku oṣù kan kí àpéjọ náà bẹ̀rẹ̀ ni mo ti dé síbi tá a fẹ́ lò, kí n lè bá wọn tún ibẹ̀ ṣe.

A máa ń ṣiṣẹ́ pẹ́ gan-an lójúmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, orí àwọn ìjókòó tó wà ní pápá ìṣeré yẹn la máa ń sùn mọ́jú. Wọ́n pín àwọn obìnrin tó wà láàárín wa sí àwùjọ kéékèèké láti gbá ìdọ̀tí tó wà níbi ìgbọ́kọ̀sí ní àyíká pápá ìṣeré náà. Òbítíbitì pàǹtí tí ó kún inú ọkọ̀ akóyọyọ méjìlá ni wọ́n rù dànù. Iṣẹ́ ribiribi ni àwọn tó ń ṣètò ilé gbígbé ṣe láti wá àwọn ilé tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] èèyàn tí wọ́n retí pé wọ́n máa wá sí àpéjọ náà máa dé sí nílùú yẹn. Àmọ́, ṣàdédé la gbọ́ ìròyìn burúkú kan!

Ní August 19, ìyẹn nígbà tó ku ọjọ́ márùn-ún tí a máa bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà, wọ́n mú Mikhail Gorbachev tó jẹ́ ààrẹ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àjùmọ̀ni Soviet nígbà yẹn, níbi tó ti ń gbafẹ́ ní àgbègbè ìlú Yalta, wọ́n sì lọ tì í mọ́lé. Bí ìjọba ṣe wọ́gi lé àṣẹ tí wọ́n fún wa láti ṣe àpéjọ nìyẹn! Àwọn tí a retí pé kó wá sí àpéjọ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn tó ń ṣètò àpéjọ náà, wọ́n ń béèrè pé kí ni kí àwọn ṣe nípa àwọn bọ́ọ̀sì àti ọkọ̀ ojú irin tí àwọn ti háyà sílẹ̀. Àwọn tó ń ṣètò àpéjọ náà gbàdúrà gidigidi lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì sọ fún àwọ́n tó ń pè wọ́n pé kí wọ́n má fòyà, kí wọ́n ṣáà máa bọ̀ ní àpéjọ.

A ò dákẹ́ àdúrà, a ò sì jáwọ́ nínú mímúra ibi púpọ̀ tí a fẹ́ lò sílẹ̀. Àwọn tó ń ṣètò ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ pàdé àwọn tó ń dé láti àwọn apá oríṣiríṣi nílẹ̀ Soviet Union. Wọ́n sì ń mú wọn lọ sí ilé tí wọ́n ti ṣètò kalẹ̀ fún wọn. Ní àràárọ̀, àwọn Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò àpéjọ ńlá yẹn máa ń lọ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìlú nípa àpéjọ náà. Ilẹ̀ ti máa ń ṣú kí wọ́n tó dé, síbẹ̀, wọn ò mú èsì tó dáa bọ̀.

ỌLỌ́RUN DÁHÙN ÀDÚRÀ WA

Ní Thursday, August 22, tó ku ọjọ́ méjì kí àpéjọ náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò àpéjọ yẹn mú ìròyìn ayọ̀ kan wá. Wọ́n sọ pé àwọn aláṣẹ ti fọwọ́ sí i pé ká ṣe àpéjọ náà! Ńṣe ni ayọ̀ kún inú ọkàn wa nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin ìbẹ̀rẹ̀, tí a sì tún gbàdúrà. Lẹ́yìn tí a parí lọ́jọ́ Saturday, a ṣì wà níbẹ̀ di àṣalẹ́ tí à ń sọ̀rọ̀ tí a sì ń kí àwọn tí a ti mọra tipẹ́. Ó wú wa lórí gan-an láti rí àwọn ará wa tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára débi pé wọn ò bọ́hùn nígbà tí ìṣòro tó le koko dé bá wọn.

Àpéjọ ti a ṣe ní Odessa, lọ́dún 1991

Ó ti lé lọ́dún méjìlélógún [22] báyìí tí a ti ṣe àpéjọ ńlá yẹn, ọ̀pọ̀ ìtẹ̀síwájú tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló sì ti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn. Ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti kọ́ káàkiri ilẹ̀ Ukraine, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń wàásù níbẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an. Lọ́dún 1991, a ò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] lọ, àmọ́ ní báyìí a ti lé ní ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000]!

A ṢÌ Ń FI AYỌ̀ SIN ỌLỌ́RUN

Ilé kékeré tí èmi àti ìdílé mi ń gbé ní ìlú Dzhankoy náà la ṣì wà. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì [40,000] èèyàn ló ń gbé ìlú yẹn. Nígbà tá a kó wá láti Siberia sí ìlú yìí lọ́dún 1968, ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn ìdílé tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìjọ ti di mẹ́fà ní ìlú Dzhankoy.

Nínú ìdílé mi, àwa tí a ń sin Jèhófà ti pọ̀ sí i. A ti di ìràn mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èmi àti ìyàwó mi, àwọn ọmọ wa, àwọn ọmọ-ọmọ wa, àtàwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ wa.