Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Onígbàgbọ́ Tòótọ́ àti Ọmọ Ìlú Rere​—Béèyàn Ṣe Lè Ṣe Méjèèjì

Onígbàgbọ́ Tòótọ́ àti Ọmọ Ìlú Rere​—Béèyàn Ṣe Lè Ṣe Méjèèjì

Onígbàgbọ́ Tòótọ́ àti Ọmọ Ìlú Rere​—Béèyàn Ṣe Lè Ṣe Méjèèjì

ÀWỌN ohun méjì wo la mọ̀ mọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù? Àkọ́kọ́, ọkàn àwọn èèyàn ni Jésù wá láti yí pa dà, kì í ṣe ètò ìṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun tí Jésù tẹnu mọ́ nínú Ìwàásù Lórí Òkè. Kó tó di pé ó sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dà bí iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀, ó sọ fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn tó ní ojúlówó ayọ̀ ni àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” Ó fi kún un pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, . . . àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, . . . àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” (Mátíù 5:1-11) Jésù mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n jẹ́ kí ìrònú wọn àti ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan bá ìlànà Ọlọ́run mu lórí àwọn ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, àti bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa jọ́sìn Ọlọ́run tọkàntọkàn.

Èkejì, nígbà tí Jésù rí àwọn èèyàn tó ń jìyà, àánú tó ní fún wọn mú kí ó ṣe ohun tó mú kí ara tù wọ́n. Àmọ́, kì í wá ṣe pé ohun tó gbájú mọ́ ni pé kí ó yanjú gbogbo ìṣòro àwọn èèyàn. (Mátíù 20:30-34) Ó wo àwọn aláìsàn sàn, àmọ́ ìyẹn kò mú àìsàn kúrò láyé. (Lúùkù 6:17-19) Ó mú kí ara tu àwọn tí wọ́n ń pọ́n lójú, àmọ́ àìsí ìdájọ́ òdodo ṣì ń mú kí ìyà máa jẹ àwọn èèyàn. Ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, àmọ́ ìyàn ṣì ń han aráyé léèmọ̀.—Máàkù 6:41-44.

À Ń Yí Àwọn Èèyàn Lọ́kàn Pa Dà, A sì Ń Tù Wọ́n Lára

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ohun tí Jésù gbájú mọ́ ni bó ṣe máa yí ọkàn àwọn èèyàn pa dà àti bó ṣe máa tu àwọn èèyàn lára dípò kí ó yí àwọn ètò tó wà nílẹ̀ pa dà tàbí kí ó fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé? Jésù mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu pé òun máa lo Ìjọba Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú láti fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn, tó sì máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. (Lúùkù 4:43; 8:1) Torí náà, nígbà kan tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ pé kí ó dúró díẹ̀ sí i láti wo àwọn aláìsàn sàn, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, sí àwọn ìlú abúlé tí ó wà nítòsí, kí èmi lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú, nítorí fún ète yìí ni mo ṣe jáde lọ.” (Máàkù 1:32-38) Jésù mú kí ara tu ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń jìyà, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló gbájú mọ́.

Àpẹẹrẹ Jésù ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé bí wọ́n ṣe ń wàásù lónìí. Wọ́n máa ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó máa mú kí ara tu àwọn tó ń jìyà. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í wá bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìwà ìrẹ́nijẹ tó kún inú ayé. Wọ́n gbà gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa fòpin sí ohun tó ń fa gbogbo ìjìyà. (Mátíù 6:10) Bíi ti Jésù, ọkàn àwọn èèyàn ni àwọn náà ń gbìyànjú láti yí pa dà kì í ṣe àwọn ètò ìṣèlú. Ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe nìyẹn torí pé olórí ìṣòro tí ẹ̀dá èèyàn ní kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìṣèlú bí kò ṣe àìmọ̀ ìwà hù.

Ọmọ Ìlú Rere

Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ojúṣe àwọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ni pé kí àwọn jẹ́ ọmọ ìlú rere. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń bọlá fún àwọn aláṣẹ ìjọba, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Wọ́n máa ń tipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wọn àtàwọn ìtẹ̀jáde wọn rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa pa òfin ìjọba mọ́. Àmọ́, nígbà tí ìjọba kan ba sọ pé kí wọ́n ṣe ohun tí kò bá òfin Ọlọ́run mu, àwọn Ẹlẹ́rìí kì í pa irú àwọn òfin ìjọba bẹ́ẹ̀ mọ́. Wọ́ máa ń “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29; Róòmù 13:1-7.

Awọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù fún gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ní àdúgbò, kí wọ́n lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Nítorí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn náà, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni wọ́n ti yí lọ́kàn pa dà. Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n ń ràn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tó ń pani lára, irú bíi sìgá mímu, ìmutípara, lílo oògùn olóró, tẹ́tẹ́ títa àti ìṣekúṣe. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti di ọmọlúwàbí àti ọmọ ìlú rere torí pé wọ́n ti mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wọn.—Wo àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” lójú ìwé 18 nínú ìwé ìròyìn yìí.

Ní àfikún, ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń mú kí àwọn tó wà nínú ìdílé túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, kí wọ́n sì túbọ̀ máa gbọ́ ara wọn yé, nígbà tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bá wáyé, yálà láàárín tọkọtaya, òbí sí ọmọ àti láàárín àwọn ọmọ pẹ̀lú. Àwọn nǹkan tó máa ń mú kí okùn ìdílé lágbára nìyẹn. Ó ṣe tán, ilé la ti ń kó ẹ̀ṣọ́ ròde, bí ilé bá tòrò, àdúgbò náà á tòrò.

Ní báyìí tó o ti ka àwọn kókó tá a jíròrò nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, kí lèrò rẹ: Ǹjẹ́ ó bá Bíbélì mu pé kí àwọn èèyàn da ìsìn pọ̀ mọ́ ìṣèlú? Ìdáhùn náà ṣe kedere; kò bá Bíbélì mu. Àmọ́, ṣé ó yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ ọmọ ìlú rere? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ bẹ́ẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe é? Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá pa àṣẹ Jésù mọ́ pé kí wọ́n dà bí iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ nínú ayé.

Àwọn tó ń sapá láti máa fi àwọn ìtọ́ni tó bọ́gbọ́n mu tí Kristi fúnni yìí sílò máa jàǹfààní, wọ́n á tún wúlò fún àwọn ìdílé wọn àti fún àdúgbò tí wọ́n ń gbé. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àdúgbò rẹ máa dùn láti túbọ̀ ṣàlàyé fún ọ nípa ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ lọ́wọ́ ní àdúgbò rẹ. *

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó o bá fẹ́, o tún lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nípa lílo àdírẹ́sì ìkànnì wọn, ìyẹn www.watchtower.org

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Ọkàn àwọn èèyàn ni Jésù ń gbìyànjú láti yí pa dà kì í ṣe àwọn ètò ìṣèlú

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ojúṣe àwọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ni pé kí àwọn jẹ́ ọmọ ìlú rere