Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Wo Ni Jésù Fi Wo Ọ̀rọ̀ Ìṣèlú?

Ojú Wo Ni Jésù Fi Wo Ọ̀rọ̀ Ìṣèlú?

Ojú Wo Ni Jésù Fi Wo Ọ̀rọ̀ Ìṣèlú?

ÀWỌN tó kọ ìwé Ìhìn Rere ṣàlàyé onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé láwọn ìgbà tó bá àwọn olóṣèlú pàdé. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi nígbà tó wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún, Èṣù sọ pé òun máa sọ ọ́ di alákòóso ayé. Lẹ́yìn ìgbà náà, tí Jésù wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn kan fẹ́ sọ ọ́ di ọba wọn. Nígbà tó tún ṣe, àwọn èèyàn gbìyànjú láti sọ ọ́ di Ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn lórí ọ̀ràn ìṣèlú. Kí ni Jésù ṣe? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Alákòóso ayé. Àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé Èṣù fi ìṣàkóso “gbogbo ìjọba ayé” lọ Jésù. Ẹ wo bí ara ì bá ṣe tu àwọn èèyàn tó ń jìyà tó lábẹ́ ìjọba Jésù ká sọ pé òun ló wà lórí oyè gẹ́gẹ́ bí alákòóso ayé! Olóṣèlú tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ló fi ń fẹ́ ire fún àwọn èèyàn wo ló máa kọ irú àǹfààní bẹ́ẹ̀? Àmọ́ Jésù kọ àǹfààní yìí.—Mátíù 4:8-11.

Ọba. Gbogbo ọ̀nà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó gbé ayé lákòókò Jésù fi ń wá alákòóso tó máa bá wọn yanjú àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé àti ti ìṣèlú. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe wú àwọn èèyàn lórí débi pé wọ́n fẹ́ kí ó dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìṣèlú. Kí lohun tí Jésù ṣe? Jòhánù tó kọ Ìhìn Rere sọ pé: “Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan.” (Jòhánù 6:10-15) Ó ṣe kedere pé Jésù kò fẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú.

Ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn lórí ọ̀ràn ìṣèlú. Kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ mélòó kan kí wọ́n tó pa Jésù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí tí wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa gba òmìnira kúrò lábẹ́ àwọn ará Róòmù, àtàwọn alátìlẹyìn Hẹ́rọ́dù, tí wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ òṣèlú tó gba ti àwọn ará Róòmù, lọ bá Jésù. Wọ́n fẹ́ fipá mú un láti gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan. Wọ́n béèrè bóyá ó tọ́ kí àwọn Júù máa san owó orí fún ìjọba Róòmù.

Máàkù ṣàkọsílẹ̀ bí Jésù ṣe dá wọn lóhùn, ó ní: “‘Èé ṣe tí ẹ fi ń dán mi wò? Ẹ mú owó dínárì kan wá fún mi kí n wò ó.’ Wọ́n mú ọ̀kan wá. Ó sì wí fún wọn pé: ‘Àwòrán àti àkọlé ta ni èyí?’ Wọ́n wí fún un pé: ‘Ti Késárì ni.’ Nígbà náà, Jésù wí pé: ‘Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.’” (Máàkù 12:13-17) Nígbà tí ìwé Church and State—The Story of Two Kingdoms ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Jésù fi dá wọn lóhùn bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ó kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n sọ òun di Mèsáyà olóṣèlú, ó sì fara balẹ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín Késárì àti Ọlọ́run.”

Kristi máa ń mọ̀ ọ́n lára tó bá rí àwọn èèyàn tó wà nínú ìṣòro, àwọn ìṣòro bí ipò òṣì, ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìrẹ́nijẹ. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó dùn ún gan-an nígbà tó rí ipò tó ń ṣeni láàánú tí àwọn èèyàn tó yí i ká wà. (Máàkù 6:33, 34) Síbẹ̀, Jésù kò tìtorí bẹ́ẹ̀ máa polongo bó ṣe máa mú ìwà ìrẹ́nijẹ tó wà láyé kúrò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbìyànjú pé kí ó dá sí àwọn ọ̀ràn tó ń fa àríyànjiyàn láàárín wọn.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn àpẹẹrẹ yìí ṣe fi hàn, ó ṣe kedere pé Jésù kò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Àmọ́, àwọn Kristẹni ńkọ́ lónìí? Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?