Àkọsílẹ̀ Máàkù 12:1-44

  • Àpèjúwe àwọn tó ń dáko tí wọ́n sì pààyàn (1-12)

  • Ọlọ́run àti Késárì (13-17)

  • Ìbéèrè nípa àjíǹde (18-27)

  • Àṣẹ méjì tó tóbi jù (28-34)

  • Ṣé ọmọ Dáfídì ni Kristi? (35-37a)

  • Ó ní kí wọ́n ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin (37b-40)

  • Opó aláìní fi ẹyọ owó méjì sílẹ̀ (41-44)

12  Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà,+ ó sì ṣe ọgbà yí i ká, ó gbẹ́ ẹkù sí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, ó sì kọ́ ilé gogoro kan;+ ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.+  Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kó gbà lára àwọn èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ wọn.  Àmọ́ wọ́n mú un, wọ́n lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo.  Ó tún rán ẹrú míì sí wọn àmọ́ wọ́n lù ú ní orí, wọ́n sì kàn án lábùkù.+  Ó rán ẹlòmíì, wọ́n sì pa á, ó tún rán ọ̀pọ̀ àwọn míì, wọ́n lu àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì pa àwọn míì.  Ẹnì kan tó ṣẹ́ kù ni ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.+ Òun ló rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’  Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ogún rẹ̀ sì máa di tiwa.’  Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n sì jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà.+  Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa ṣe? Ó máa wá, ó máa pa àwọn tó ń dáko náà, á sì gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì.+ 10  Ṣé ẹ ò ka ìwé mímọ́ yìí rí ni, pé: ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ 11  Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?”+ 12  Ni wọ́n bá fẹ́ mú un,* àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń fi àpèjúwe náà bá wí. Torí náà, wọ́n fi sílẹ̀, wọ́n sì lọ.+ 13  Lẹ́yìn náà, wọ́n rán àwọn kan lára àwọn Farisí àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ bá a, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un.+ 14  Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n sọ fún un pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, o kì í wá ojúure ẹnikẹ́ni, torí kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn lò ń wò, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́. Ṣé ó bófin mu* láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu? 15  Ṣé ká san án àbí ká má san án?” Ó rí i pé alágàbàgebè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? Ẹ mú owó dínárì* kan wá fún mi kí n wò ó.” 16  Wọ́n mú ọ̀kan wá, ó sì sọ fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ti Késárì ni.” 17  Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ Ẹnu sì yà wọ́n sí i. 18  Àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 19  “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé tí arákùnrin ẹnì kan bá kú, tó sì fi ìyàwó sílẹ̀ àmọ́ tí kò bímọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.+ 20  Arákùnrin méje wà. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, àmọ́ nígbà tó kú, kò fi ọmọ kankan sílẹ̀. 21  Ẹnì kejì fẹ́ obìnrin náà, àmọ́ ọkùnrin náà kú láìbímọ, ohun kan náà ló sì ṣẹlẹ̀ sí ẹni kẹta. 22  Àwọn méjèèje ò fi ọmọ kankan sílẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obìnrin náà kú. 23  Nígbà àjíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí àwọn méjèèje ló ti fi ṣe aya.” 24  Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí ìdí tí ẹ fi ṣàṣìṣe nìyẹn, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run?+ 25  Torí tí wọ́n bá jíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+ 26  Àmọ́ ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ 27  Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè. Ẹ mà ṣàṣìṣe o.”+ 28  Ọ̀kan nínú àwọn akọ̀wé òfin tó wá, tó gbọ́ tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀, tó sì mọ̀ pé ó ti dá wọn lóhùn lọ́nà tó dáa, bi í pé: “Èwo ni àkọ́kọ́* nínú gbogbo àṣẹ?”+ 29  Jésù dáhùn pé: “Àkọ́kọ́ ni, ‘Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà* Ọlọ́run wa, Jèhófà* kan ṣoṣo ni, 30  kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+ 31  Ìkejì ni, ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’+ Kò sí àṣẹ míì tó tóbi ju àwọn yìí lọ.” 32  Akọ̀wé òfin náà sọ fún un pé: “Olùkọ́, ohun tí o sọ dáa, ó sì bá òtítọ́ mu, ‘Ọ̀kan ṣoṣo ni Òun, kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan;+ 33  kí èèyàn fi gbogbo ọkàn, gbogbo òye àti gbogbo okun nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀, kó sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ bí ara rẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an ju gbogbo odindi ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ.”+ 34  Jésù rí i pé ìdáhùn rẹ̀ mọ́gbọ́n dání, ó wá sọ fún un pé: “O ò jìnnà sí Ìjọba Ọlọ́run.” Àmọ́ kò sẹ́ni tó láyà láti tún bi í ní ìbéèrè mọ́.+ 35  Bí Jésù ṣe ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó sọ pé: “Kí nìdí tí àwọn akọ̀wé òfin fi sọ pé ọmọ Dáfídì ni Kristi?+ 36  Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́,+ Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.”’+ 37  Dáfídì fúnra rẹ̀ pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe wá jẹ́ ọmọ rẹ̀?”+ Èrò rẹpẹtẹ náà ń gbádùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. 38  Bó ṣe ń kọ́ni, ó sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n fẹ́ máa rìn kiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì fẹ́ kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà,+ 39  wọ́n fẹ́ ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù àti ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́.+ 40  Wọ́n ń jẹ ilé* àwọn opó run, wọ́n sì ń gba àdúrà tó gùn láti ṣe ojú ayé.* Ìdájọ́ tó le* gan-an ni àwọn yìí máa gbà.” 41  Ó wá jókòó síbi tó ti ń rí àwọn àpótí ìṣúra ní ọ̀ọ́kán,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wo bí àwọn èrò ṣe ń fi owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì ń fi ẹyọ owó púpọ̀ síbẹ̀.+ 42  Opó kan tó jẹ́ aláìní wá, ó sì fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an* síbẹ̀.+ 43  Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù tó fi owó sínú àwọn àpótí ìṣúra.+ 44  Torí gbogbo wọn fi síbẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́,* ó fi gbogbo ohun tó ní síbẹ̀, gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “olórí igun.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”
Tàbí “tọ́.”
Tàbí “ló ṣe pàtàkì jù.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “tó dáa jù.”
Tàbí “ohun ìní.”
Tàbí “bojúbojú.”
Tàbí “wúwo.”
Ní Grk., “lẹ́pítónì méjì, tó jẹ́ kúádíránì kan.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “pé ó jẹ́ òtòṣì.”