Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Obìnrin tó gbọ́n máa ń tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sọ

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìṣẹ́yún

Ìṣẹ́yún

Lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye oyún làwọn èèyàn ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́ dànù—kódà, iye oyún tí wọ́n ń ṣẹ́ pọ̀ ju iye àwọn èèyàn tó ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè kan lọ.

Ṣé ohun tó bá wù ẹ́ lo lè ṣe sí oyún inú rẹ?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Onírúurú nǹkan ló ń mú káwọn obìnrin ṣẹ́yún, lára rẹ̀ ni ìṣòro ọrọ̀ ajé tàbí kí ẹni tó fún wọn lóyún má gbà á. Àwọn míì sì fẹ́ kàwé sí i tàbí kí wọ́n wáṣẹ́ tí wọn ò sì fẹ́ kọ́rọ̀ ọmọ dí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè má fẹ́ dánìkan tọ́mọ. Àmọ́, èrò àwọn míì ni pé kò tọ̀nà rárá kéèyàn ṣẹ́yún, pé ó jẹ́ ìwà ìkà.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ohun mímọ́ ni Ọlọ́run ka ẹ̀mí sí, ní pàtàkì ẹ̀mí àwa èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 9:6; Sáàmù 36:9) Kódà, Ọlọ́run ka ẹ̀mí ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dágbà nínú ikùn ìyá rẹ̀ sí pàtàkì. Torí pé, ńṣe ni Ọlọ́run ṣe ikùn obìnrin bí ibi ààbò fún ọlẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di ọmọ. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi.” Ó wá fi kún un pé: “Ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn.”Sáàmù 139:13, 16.

Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọmọ tó wà nínú oyún tún hàn nínú Òfin tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti bó ṣe dá wa láti ní ẹ̀rí ọkàn. Òfin Ọlọ́run fi hàn pé, pípa ni kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣe aláboyún ni jàǹbá débí ti ọmọ inú rẹ̀ fi kú, ẹ̀mí ara rẹ̀ ló máa fi dí ẹ̀mí ọmọ inú tó pa náà. (Ẹ́kísódù 21:22, 23) Àmọ́ ṣá o, àwọn adájọ́ máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò láti mọ̀ bóyá ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ tàbí kò mọ̀ọ́mọ̀.Númérì 35:22-24, 31.

Ọlọ́run tún fún àwa èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn. Ẹ̀rí ọkàn aláboyún kan máa ṣe é láǹfààní tó bá tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ fún un, tó sì ka ọmọ inú rẹ̀ sí pàtàkì. * Àmọ́ tó bá ṣẹ́yún, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ á máa dàá láàmú, á sì tún máa dáa lẹ́bi. (Róòmù 2:14, 15) Ìwádìí tiẹ̀ fi hàn pé àwọn obìnrin tó ń ṣẹ́yún máa ń ní ìdààmú ọkàn àti ìsoríkọ́.

Tí èèyàn bá wá lóyún láìrò tẹ́lẹ̀, tí kò sì sí owó láti gbọ́ bùkátà ọmọ tuntun ńkọ́? Ẹ gbọ́ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn tó ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀, ó ní: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin; Ìwọ yóò bá aláìní-àléébù, abarapá ọkùnrin [tàbí obìnrin] lò lọ́nà àìlálèébù.” (Sáàmù 18:25) Bíbélì tún sọ pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, Òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.”Sáàmù 37:28.

“Ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.”Róòmù 2:15.

Tó o bá ti wá ṣẹ́yún ńkọ́?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Obìnrin tó ń dá tọ́mọ ni Ruth, ó sọ pé: “Mo ti ni ọmọ mẹ́ta tẹ́lẹ̀, mo sì ronú pé agbára mi ò gbé ọmọ kẹrin. Torí náà, mo ṣẹ́ oyún tí mo ní, àmọ́ lẹ́yìn náà, ó wá ń ṣe mí bíi pé ìwà ìkà gbáà ni mo hù.” * Àmọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run lè dárí jì í fún ohun tó ṣe yìí?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Jésù Kristi sọ ohun tó jẹ́ èrò Ọlọ́run nípa àwọn nǹkan nígbà tó sọ pé: “Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.” (Lúùkù 5:32) Torí náà, tá a bá kábàámọ̀ ìwà burúkú tá a hù, tá a ronú pìwà dà, tá a sì bẹ Ọlọ́run pé kó dárí jì wá, Ọlọ́run á dárí jì wá, kódà kó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an la dá. (Aísáyà 1:18) Ìwé Sáàmù 51:17 sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.”

Yàtọ̀ sí pé ẹni tó ronú pìwà dà náà máa ní ẹ̀rí ọkàn rere, Ọlọ́run máa fún un ní àlááfíà ọkàn tó bá béèrè fún un nínú àdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Fílípì 4:6, 7 sọ pé: “Nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.” * Lẹ́yìn tí Ruth ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run, ó wá ní irú àlàáfíà ọkàn tí ibi yìí sọ. Ó sì wá yé e pé “ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ [Ọlọ́run].”Sáàmù 130:4.

[Ọlọ́run] kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.”Sáàmù 103:10.

^ ìpínrọ̀ 8 Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀mí ìyá tàbí ọmọ inú rẹ̀ wà nínú ewu, àmọ́ ìyẹn kò ní kí wọ́n torí ẹ̀ ṣẹ́yún. Tí ìṣòro bá yọjú nígbà tí aláboyún ń rọbí, tó máa jẹ́ kó ṣòro láti gbóhùn ìyá àtọmọ, ọkọ àtìyàwó ló máa pinnu ẹni tí wọ́n máa dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, yálà ìyá tabí ọmọ. Àmọ́ ṣá o, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà, ìmọ̀ ìṣègun ti dín irú àwọn ìṣòro báyìí kù gan-an.

^ ìpínrọ̀ 12 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

^ ìpínrọ̀ 14 Ìrètí àjíǹde tún lè mú kéèyàn ní àlááfíà ọkàn. Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2009. Àpilẹ̀kọ náà sọ àwọn ìlànà tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ tó kú sínú oyún ní àjínde.